NLC, TUC, fàáké kọrí, wọ́n ni ìyanṣẹ́lódì n tẹ̀síwájú lẹ́yìn tí ìjọba kéde iye tó le san

Agbarijọpọ ẹgbẹ awọn oṣiṣẹ ni Naijiria, ti sọ pe iyanṣẹlodi alainigbedeke ọjọ ti yoo pari ṣi n tẹsiwaju.

Ẹgbẹ NLC fi ikede naa sita loju opo X wọn.

Wọn ni awọn ko ni i fi opin si iyanṣẹlodi titi di igba ti awọn ba gbọ lati ọdọ awọn ẹka gbogbo, nibi ipade ti yoo waye ni ọjọ Iṣẹgun, ọjọ kẹrin, oṣu Kẹfa.

Wọn sọ eyi lẹyin ipade ti wọn ṣe pẹlu awọn aṣoju ijọba ni irọlẹ ọjọ Aje.

Nibi ipade naa, ijọba apapọ ni oun ti gba lati san ju ẹgbẹrun lọna ọgọta Naira ti oun n gbero tẹlẹ.

Awọn ẹgbẹ oṣiṣẹ
Skip X post
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of X post

Ìjọba àti ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ fẹnukò lórí owó oṣù tuntun
Àwọn ọmọ ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ìjọba apapọ ati ẹgbẹ oṣiṣẹ ti fẹnuko lori awọn adehun tuntun to nii ṣe nipa owo oṣu tuntun fun awọn osisẹ.

Adehun tuntun naa waye nibi ipade ti awọn aṣoju ijọba, ati ẹgbẹ oṣiṣẹ ṣe niluu Abuja lọjọ Aje.

Ọjọ Aje, ọjọ kẹta, oṣu Kẹfa, ni agbarijọ pọ NLC, TUC, NUJ, ati awọn ẹgbẹ mii bẹrẹ iyanṣẹlodi alainigbedeke.

Awọn akọroyin BBC to lọ kaakiri awọn ipinlẹ bii Ogun, Osun, Oyo, Ekiti, Kwara ati Ondo jabọ pe titi pa ni awọn ileeṣẹ ijọba, to fi mọ awọn banki wa.

Ṣaaju ni ijiroro laarin ijọba ati ẹgbẹ oṣiṣẹ ko so eso rere. Ijiroro to kẹhin waye lọjọ Aiku to kọja, pẹlu awọn olori ile aṣofin.

Igba mẹrin ni ijọba ti daba owo oṣu to le san - akọkọ ni ẹgbẹrun mejidinlaadọta Naira ti wọn kọkọ dabaa, ẹlẹẹkeji ni ẹgbẹrun mẹrinlelaadọta Naira ti wọn mẹnuba lọjọ Iṣẹgun, nigba ti ẹgbẹrun mẹtadinlọgọta naira jẹ igba kẹta, ko to tun wa kan ẹgbẹrun lọna ọgọta naira ti wọn kọ lati tẹwọgba.

Nipa ipade ti wọn ṣe lọjọ Aje, ileeṣẹ agbohunsafẹfẹ to jẹ ti ijọba apapọ, NTA, sọ pe Aarẹ Bola Tinubu, ti buwọlu owo oṣù to ju ẹgbẹrun lọna ọgọta Naira.

Nitori owo oṣu tuntun ti aarẹ buwọlu, ọjoojumọ ni igbimọ ti ijọba gbe kalẹ yoo ma a ṣe ipade fun ọsẹ kan gbako, lati fẹnukò lori owo oṣu ti ijọba ati awọn osisẹ yoo faramọ́.

Ninu adehun ti wọn, awọn olori ẹgbẹ oṣiṣẹ gba lati ṣe ipade pẹlu awọn ẹka wọn ni kiakia, lati gbe erongba ijọba wo.

Bakan naa lo tun jẹyọ nibi ipade naa pe, oṣiṣẹ kankan ko ni fojuwina ijiya tabi idunkooko mọ, ninu wọn kopa ninu iyanṣẹlodi.