Wo kókó àṣeyọrí ìjọba Ààrẹ Bola Tinubu láàrin ọdún kan tó dé ipò ààrẹ

Oríṣun àwòrán, X/official BAT
Bi Ọjọru ọjọ kọkandinlọgbọn oṣu Karun-un ọdun 2024 ṣe jẹ ayajọ ọdun kan ti Aarẹ Bola Tinubu di aarẹ orilẹede Naijiria, ẹgbẹ oṣelu APC ti ki awọn ọmọ Naijiria ku orire, o si tun kan sara si wọn fún ifọwọsowọpọ ati atilẹyin ti wọn ṣe fun ẹgbẹ oṣelu naa ati ijọba to wa lode.
Bẹẹ ba gbagbe, Ọjọru ana yii kan naa lo pe ọdun kan ti Aarẹ Tinubu kede pe oun ti yọ owo iranwọ epo bẹntiroolu.
Igbesẹ yii ko dun mọ ọpọ araalu ninu, ti wọn si bu ẹnu atẹ lu igbesẹ ọhun pe ohun lo sokunfa idi ti ọwọngogo fi gbode lorilẹede Naijira.
Ninu atẹjade ti Felix Morka, akọwe iroyin ẹgbẹ oṣelu naa fi lede fawọn akọroyin, APC kan sara si Aarẹ fun bi o ṣe gbaju mọ ohun to ṣe ileri fawọn araalu.
Morka tẹsiwaju pe pẹlu bi Aarẹ se ni ọpọlọpọ ila kọja, o si se ọkan akin lati gbe awọn igbesẹ ti yoo ṣe ilu ni anfani pupọ.
O tẹsiwaju pe awọn igbesẹ Aarẹ yii lo mu inira dani sugbọn igbagbọ wa pe adun ni yoo gbẹyin ewuro laipẹ.
O wa ka awọn aṣeyọri ti ijọba Tinubu ati ẹgbẹ oṣelu APC ti ṣe laarin ọdun kan .
Idagbasoke ọrọ Aje
Akọwe iroyin APC ijọba Tinubu ṣe agbekalẹ awọn ilana ati igbesẹ lati tako kudiẹkudiẹ to n koba ọrọ aje, eyi to si n ti ṣe anfani nla fun idagbasoke ọrọ aje.
“Bi aarẹ se kede pe owo iranwọ epo bẹntiroolu ti dopin ninu ọrọ to kọkọ sọ sita gẹgẹ bii Aarẹ, jẹ igbesẹ nla lati gbe ina woju gbogbo iṣoro to n koju eto aje Naijiria.
“Ijọba yii siṣẹ takuntakun lati mu awọn olokowo wọle lati oke okun lati wa da okowo silẹ, eyi to n ṣe anfani nla fun idagbasoke ọrọ aje to si tun pa owo sapo ijọba laarin ọdun kan.
“Sisowo lorilẹede Naijria ti gbooro si lati bilọnu kan naira lọdun 2023 si biliọnu mejidinlaadọrun naira ni ọdun 2024, ti ida owo ti wọ apo ijọba si ti gboro si ju ti tẹlẹ lọ.
Atunṣe oju ọna reluwe ati opopona ọkọ
Ọgbẹni Morka ni yatọ si ọrọ ajẹ, Aarẹ Tinubu tun ṣe ifilọlẹ awọn opopona ti yoo ṣe ọpọlọpọ anfani fun idagbasoke ọrọ aje kaakiri orilẹede Naijiria.
“Laipẹ yii ni iṣẹ bẹrẹ lori opopona Eko si Calabar, eyi ti yoo pese iṣẹ fun ọpọlọpọ ọdọ, ti irinajo igbafẹ yoo si gboro si, ka ma gbagbe pe yoo se anfani nla fun eto aje naa pẹlu.
“Lẹyin ọpọlọpọ ọdun to ti wa ni pipati, ijọba Tinubu ti bẹrẹ iṣẹ pada lori opopona Sokoto si Badagry.
”Ijọba tun pese ohun irinsẹ loju reluwe kaakiri Naijiria bi ti reluwe ti ilu Abuja,-Port Harcour-Maiduguri, Ibadan -Abuja- Kaduna, Kano-Katsina-Maradi ti iṣẹ ṣi tun ti bẹrẹ lori ọpọlọpọ oju ọna morosẹ kaakiri orilẹede Naijiria.
Ẹyawo fun awọn akẹkọọ
APC ni iṣejọba to wa lode bayii ko kọ iyan awọn ọdọ ati akẹkọọ kere lo fi pese eto ẹyawo fun awọn akẹkọọ lati le ni anfani lati tẹiswaju nini eto ẹkọ wọn.
“Ipese ẹyawo fun awọn akẹkọọ, ijiroro nipa owo oṣu tuntun fun awọn sisẹ, pinpin owo kaakiri fun awọn mẹkunnu, sise afihan ọkọ ayọkẹlẹ to n lo afẹfẹ gaasi ati awọn nnkan mii ti fihan pe Aarẹ Tinubu ni erongba to da fun awọn araalu.”
Akọwe iroyin APC tun sọ pe ijọba apapọ labẹ iṣejọba Aarẹ Tinubu n ri pe abo ounjẹ wa bo ti lẹ jẹ wi pe pupọ awọn igbesẹ yii lo wa pẹlu inira fun mẹkunnu sugbọn Ọgbẹni Marko ni Aarẹ ati ẹgbẹ oṣelu APC n sisẹ lati ri pe ara dẹ araalu.
Ni ipari, APC ni awọn kan sara si awọn ọmọ Naijiria fun bi wọn ṣe n ṣe suuru fun Aarẹ Tinubu, ti wọn si n ti i lẹyin pẹlu.
“O da wa loju pe ọjọ rere n bọ, o ṣi ti sumọ.
“Aarẹ Tinubu ko ni yi ohun pada, ti yoo si ma wa gbogbo ọna ti Naijiria yoo fi gbooro si ni gbogbo ẹka ijọba pata.”
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post















