Wo àwọn t'órin orílẹ̀ èdè pọn dandan fún láti máa kọ

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Lẹ́yìn tí ààrẹ buwọ́lu òfin kíkọ orin orílẹ̀ èdè ayé àtijọ́, ó ti pọn dandan fún gbogbo èèyàn láti máa kọ orin náà ní gbogbo ayẹyẹ tí ètò tó jọ mọ́ ọ̀rọ̀ ìlú bá ti ń wáyé.
Bí àwọn ọ̀dọ́ Nàìjíríà kan ṣe ń dunnú pé àwọn ti parí ilé ẹ̀kọ́ girama níbi tó ti pọn dandan fún àwọn láti máa kọ orin náà ni àwọn mìíràn ń kọminú pé báwo ni àwọn ṣe fẹ́ tètè mọ orin yìí.
Lóòótọ́, ó ṣeéṣe kí kíkọ́ orin yìí ní kíákíá má kàn ọ́ nígbà tí o kò bá sí nínú àwọn tó ń ṣe àmúlò rẹ̀ ní gbogbo ìgbà tàbí àwọn tí yóò ṣàmúlò rẹ̀ láìpẹ́ ọjọ́.
Àwọn ibi tí wọ́n ti máa ṣàmúlò orin orílẹ̀ èdè
Orin orílẹ̀ èdè jẹ́ èyí tó máa ń ṣàfihàn ìṣe, àṣà àti àmì ìdánimọ̀ tó sì jẹ́ pé gbogbo orílẹ̀ èdè káàkiri àgbáyé ló ní orin tirẹ̀.
Kíkọ orin orílẹ̀ èdè níbi ayẹyẹ tó jẹ́ ti ètò ìlú àti pé ọ̀pọ̀ ayẹyẹ tó jẹ́ ti ìjọba ló sábà máa ń bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú kíkọ orin orílẹ̀ èdè.
Yàtọ̀ sí àwọn ayẹyẹ, ojoojúmọ́ ni àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ilé ẹ̀kọ́ àti alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ àti girama máa ń kọ orin yìí ní orí ìlà.
Bákan náà orin orílẹ̀ èdè máa ń jẹ́ kíkọ nígbà tí wọ́n bá fẹ́ bẹ̀rẹ̀ ìdíjé eré ìdárayà pàápàá jùlọ bọ́ọ̀lù àfẹsẹ̀gbá.
Èyí túmọ̀ sí pé orin orílẹ̀ èdè tuntun yìí ni àwọn ọmọ Nàìjíríà tí yóò kópa níbi olympics tó ń bọ̀ láìpẹ́ yìí ní Paris, orílẹ̀ èdè France.
Àwọn tí orin orílẹ̀ èdè pọn dandan fún
- Àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ilé ẹ̀kọ́ girama àti alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀
- Àwọn ẹ̀ṣọ́ ààbò
- Àwọn àgùnbánirọ̀
- Àwọn elére ìdárayà
'Èmi ò ní báwọn kọ orin ìyìn Nàìjíríà àtijọ́ tí Tinubu fòntẹ̀ lù,' mínísítà tẹ́lẹ̀ rí yarí

Oríṣun àwòrán, Ahmed Bola Tinubu/X
Minisita tẹlẹ ri, Oby Ezekwesili ti sọ pe oun ko ni báwọn kọ orin ìyìn ilẹ Naijira ti Aarẹ Bola Tinubu ṣẹṣẹ buwọlu.
Ezekwesili sọ eyi loju opo ayelujara rẹ ni lonii Ojọru, ọjọ kọkandinlọgbọn oṣu karun un ọdun 2024.
Gẹgẹ bii o ṣe sọ, ko si ẹnikẹni to fi ẹtọ rẹ dun lati yago fun oun to gbagbọ pe ko ba ofin, ti ko si erongba rere fun awọn ọmọ orilẹede Naijiria.
“Ẹ jẹ eku ile gbọ ko sọ fun ti oko pe emi, Oby Ezekwesili yoo ma kọrin iyin orilẹede ti tẹlẹ nigba kugba ti wọn ba pe mi pe ki kọrin iyin orilẹede Naijiria.
Lonii ni Aarẹ Tinubu buwọlu kikọ orin iyin asiko ijọba amunisin fun ilẹ Naijiria.
Aba yii ni aba orin iyin ọdun 2024 ti yoo pese anfani fun awọn ọmọ Naijiria lati maa kọ orin orilẹede “Naijiria, a kan sara si ẹ.”
Aarẹ ile igbimọ aṣofin agba lorilẹede Naijiria, Godswill Akpabio lo sọ eyi lasiko ijoko awọn ọmọ ile igbimọ aṣofin mejeeji.
Ààrẹ Tinubu buwọ́lu kíkọ orin ìyìn àsìkò ìjọba amúnisìn fún ilẹ̀ Naijiria

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Aarẹ orilẹede Naijiria ti buwọlu aba to n pe fun pe pipada si orin iyin orilẹede Naijiria tl ti wn lo lasiko iṣejba amunisin.
Aba yii ni aba orin iyin ọdun 2024 ti yoo pese anfani fun awọn ọmọ Naijiria lati maa kọ orin orilẹede “Naijiria, a kan sara si ẹ.”
Aarẹ ile igbimọ aṣofin agba lorilẹede Naijiria, Godswill Akpabio lo sọ eyi lasiko ijoko awọn ọmọ ile igbimọ aṣofin mejeeji.
Aarẹ fi ontẹ orin iyin atijọ naa gẹgẹ bii orin iyin tuntun
Lillian Jean Williams, ọmọ orilẹede Gẹẹsi lo ṣe akọsilẹ orin naa ti Frances Berda si kọ ọ sita.
Orin yii ni wọn ṣapejuwe gẹgẹ bii eyi ti o kopa nla ninu idagbasoke orilẹede Naijiria .
Olori ọmọ ile, Opeyemi Bamidele sọ lori ipa orin iyin naa.
O ni, “ orin yii mu ajọsepọ wa laarin awọn ọmọ Naijiria wa. Awọn to wa lasiko naa mọ ipa to ko ninu itan orilẹede Naijiria.”
Ki lo de ti Aarẹ ko fi ba awọn araalu sọrọ fun ayajọ ijọba awarawa?
Aarẹ Bola Tinubu ko ni báwọn ọmọ orilẹede Naijiria sọrọ lonii ọjọ kọkandinlọgbọn oṣu Karun un ọdun 2024 ti i ṣe ayajọ ọdun kan to de ipo aarẹ.
Amọ, Tinubu yoo ba apapọ ile ìgbimọ aṣofin agba l'Abuja sọrọ lori ayajọ ọdun kẹẹdọgbọn ti Naijiria ti pada si ijoba awaarawa.
Oludamọran pataki si aarẹ lori ọrọ iroyin ati ọgbọn inu, Bayo Onanuga lo fi ọrọ yii lede loju opo X rẹ.
Onanuga ṣalaye pe ọrọ ti aarẹ Tinubu yoo bawọn ọmọ ile aṣofin agba sọ ni ṣe pẹlu awọn aṣeyọri rẹ ni ọdun kan sẹyin.
Bakan naa ni Ọgbẹni Onanuga sọ pe Tinubu yoo tun ba ile aṣofin sọrọ lori irin-ajo ijọba awarawa Naijiria lati ọdun 1999 ti alagbada ti gbajọba lọwọ awọn ologun.
Onanuga fikun ọrọ rẹ pe awọn abẹnugan lagbo oṣelu mii bi aarẹ ile igbimọ aṣofin agba tẹlẹ, David Mark ati Femi Gbajabiamila toun naa jẹ abẹnugan ile aṣoju-ṣofin l'Abuja tẹlẹ ri yoo sọrọ nibi eto ọhun.
"Olori orilẹede ijọba ologun ni Naijiria tẹlẹ ri, Ajagunfẹyinti Abdulsalami Abubakar to gbe ijọba fun alagbada lodun 1999 yoo sọrọ nibi eto ọhun.
Aarẹ Tinubu yoo tun lo anfaani eto naa lati ṣi ile ikawe ile igbimọ aṣofin agba ti awọn aṣofin fi orukọ rẹ sọ," Onanuga ṣalaye.
O fẹẹ jẹ wi pe igba akọkọ ree ti aarẹ Naijiria ko ni báwọn araalu sọrọ ni ayajọ ọjọ ti Naijiria pada si ijọba awarawa lati ọdun 1999.















