Ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ tún kọ ₦60,000 owó oṣù tíjọba fẹ́ san, wọ́n ní ₦494,000 làwọn ó gbà

Oríṣun àwòrán, Others
Ẹgbẹ osisẹ lorilẹede Naijria tun ti kọjalẹ lati gba owo oṣu tuntun ti ijọba apapọ gbe siwaju wọn.
Ijọba apapọ lorilẹede Naijiria fi ẹgbẹrun mẹta kun owo ti wọn gbe siwaju ẹgbẹ osisẹ lọsẹ to kọja, to fi jẹ 60,000 lati 57,000 ninu ipade lọjọ Isẹgun ọjọ kejidinlogun oṣu karun un ọdun 2024.
Bakan naa ni awọn olori ẹgbẹ osisẹ NLC ati TUC naa mu adikun ẹgbẹrun mẹta ba iye owo oṣu ti wọn gbe siwaju ijọba apapọ lọsẹ to kọja to fi jẹ N494,000.
Igba kẹrin ree ti ẹgbẹ oṣisẹ ti kọ owo oṣu to kere julọ ti ijọba gbe wa siwaju wọn.
Akọkọ ni ẹgbẹrun mejidinlaadọta naira ti wọn kọkọ dabaa, ẹlẹẹkeji ni ẹgbẹrun mẹrinlelaadọta naira ti wọn mẹnuba lọjọ Iṣẹgun, nigba ti ẹgbẹrun mẹtadinlọgọta naira jẹ igba kẹta, ko to tun wa kan ẹgbẹrun lọna ọgọta naira ti wọn kọ lati tẹwọgba.
Gẹgẹ bii iroyin to tẹ wa lọwọ ṣe ṣalaye, iye owo ti ijọba apapọ gbe siwaju ẹgbẹ osisẹ ni ko dun mọ wọn ninu, ti wọn tun jẹ ko iye ijọba apapọ pe wọn ko ni ipinnu lati yi erongba wọn pada.
Ẹgbẹ osisẹ ni owo ni awọn fẹ ma gba gẹgẹ bii oṣu to kere ju ni N494,000 to ni din ni ẹgbẹrun mẹta ti wọn bere lọsẹ to kọja.
Ọkan lara ọmọ ẹgbẹ to wa ninu igbimọ to n ba ijọba apapọ jiroro lori owo oṣu sọ fun ileeṣẹ momaworan Channels pe owo oṣu tuntun ti ijọba gbe wa siwaju igbimọ ẹgbẹ oṣisẹ ni ko jẹ tẹwọgba.
Bi ẹ ko ba gbagbe, lati bi oṣu meloo sẹyin ni ẹgbẹ awọn oṣiṣẹ ni Naijiria ti n beere ẹkunwo lori owo oṣu ti wọn n gba.
Ipade ti ẹgbẹ oṣiṣẹ ṣe pẹlu awọn aṣoju ijọba apapọ lọjọ Iṣẹgun, ọsẹ yii fori ṣanpọn nigba ti ijọba apapọ ni ẹgbẹrun mẹrinlalaadọta naira lohun lagbara lati maa san gẹgẹ bi owo oṣu tuntun.
Ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ ṣe àdínkù owó oṣù tí wọ́n ń bèèrè fún sí ₦497,000, ìjọba ní ₦57,000 lòun fẹ́ san

Oríṣun àwòrán, Ahmed Bola Tinubu/X
Titi di asiko ti a pari akojọpọ iroyin yii ni ko tii sẹni to le sọ pato ibi ti ọrọ owo oṣu tuntun ti apapọ ẹgbẹ awọn oṣiṣẹ lorileede Naijiria, NLC ati TUC n beere lọwọ ijọba Naijiria yoo ja si, pẹlu bi awọn mejeeji ko ṣe gba itọ ara wọn da min.
Bi ẹ ko ba gbagbe, lati bi oṣu meloo sẹyin ni ẹgbẹ awọn oṣiṣẹ ni Naijiria ti n beere ẹkunwo lori owo oṣu ti wọn n gba.
Ipade ti ẹgbẹ oṣiṣẹ ṣe pẹlu awọn aṣoju ijọba apapọ lọjọ Iṣẹgun, ọsẹ yii fori ṣanpọn nigba ti ijọba apapọ ni ẹgbẹrun mẹrinlalaadọta naira lohun lagbara lati maa san gẹgẹ bi owo oṣu tuntun.
Bakan naa ninu ipade ti wọn tun ṣe lana l’Ọjọru, bi ẹni to lọ fi asiko ṣofo ni ipade ọhun tun ja si, nigba ti ijọba tun sọ pe oun yoo fi ẹgbẹrun mẹta naira kun owo ti wọn fẹẹ maa san tẹlẹ.
Ẹgbẹrun mẹtadinlọgọta naira ni ijọba apapọ tun sọ pe oun ni agbara lati san gẹgẹ bi owo oṣu tuntun fun awọn oṣiṣẹ orileede yii.
Eyii ni yoo si jẹ igba kẹta laarin ọsẹ meji ti ijọba apapọ ti n dabaa lori owo oṣu tuntun naa.
Akọkọ ni ẹgbẹrun mejidinlaadọta naira ti wọn kọkọ dabaa, ẹlẹẹkeji ni ẹgbẹrun mẹrinlelaadọta naira ti wọn mẹnuba lọjọ Iṣẹgun, nigba ti ẹgbẹrun mẹtadinlọgọta naira yii jẹ igba kẹta.
Bakan naa, apapọ ẹgbẹ awọn oṣiṣẹ ti NLC ati TUC ti wa sọ pe awọn naa ti ri idi pataki ti awọn yoo fi ja owo ti wọn n beere tẹlẹ wa silẹ.
Apapọ ẹgbẹ oṣiṣẹ ti wa sọ pe ẹgbẹrun mẹtadinlaadọrun (N497,000) naira ni awọn fẹ bayii ki ijọba san fun wọn gẹgẹ bi owo oṣu to kere julọ.
Wọn ni awọn ti boju aanu wo ijọba apapọ, idi ree ti wọn fi sọ pe ki ijọba gbagbe nipa N615,000 naira ti wọn n beere fun tẹlẹ.
Ọkan lara awọn alẹnulọrọ ninu igbimọ idunadura ti ijọba apapọ gbe kalẹ lori owo oṣu tuntun nigba to n ba awọn akọroyin sọrọ ṣalaye pe ẹgbẹrun mẹtadinlọgọta naira naa ni ijọba fẹnuko si.
Ni bayii, ko tii si ẹni to le sọ pato ibi ti ọrọ ọhun yoo pada ja si pẹlu bo ṣe n ku bi ọjọ mẹsan ki ọjọ kọkanlelọgbọn, oṣu karun-un ti ẹgbẹ awọn oṣiṣẹ fun ijọba apapọ lati fi mu ọrọ idunadura lori owo oṣu tuntun yii wa si opin pe.
Kí lohun tó ti ṣẹlẹ̀ ṣáájú?
Ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ láwọn o gba N54,000 owó oṣù tó kéré jùlọ t'íjọba fẹ́ san, ìpàdé wọn tún foríṣánpọ́n
Ireti ti awọn ọmọ orileede Naijiria lati gbọ esi ayọ nipa ipade ti ijọba apapọ ba ẹgbẹ awọn oṣiṣẹ ilẹ yii ṣe lori ọrọ owo oṣu lo pada ja si ofo.
Ohun ti a gbọ ni pe niṣe ni ẹgbẹ awọn oṣiṣẹ tutọ soke, ti wọn si fi oju gba a, pẹlu bi wọn ṣe sọ pe ijọba apapọ ko tii ṣetan lati jo si orin ti wọn n kọ lori afikun owo oṣu wọn.
Ijọba apapọ Naijiria, apapọ ẹgbẹ awọn oṣiṣẹ ti a mọ si Organised Labour, ati akojọpọ awọn ileeṣẹ aladani, iyẹn Organized Private Sector (OPS), ni wọn jokoo papọ lati ṣe ipade lori ọrọ owo oṣu oṣiṣẹ tuntun lọjọ Iṣẹgun, ana.
Lara ohun ti ijọba apapọ sọ ni pe awọn ko ni le san ju ẹgbẹrun mẹrinlelaadọta owo naira (N54,000) lọ, dipo ẹgbẹrun mejidinlaadọta ti wọn mẹnuba tẹlẹ.
Bo tilẹ jẹ pe ibanujẹ lo jẹ fun ẹgbẹ awọn oṣiṣẹ pẹlu bi wọn ṣe ni ko si eyikeyi ninu awọn gomina Naijiria to yọju sibi ipade ọhun, ati pe lara awọn aṣoju gomina to yọju sibẹ ni awọn ko ni aṣẹ lati sọrọ, bi ko ṣe pe ki awọn woye ohun to n lọ lati jabọ fun awọn ọga wọn.
Ṣugbọn ṣa, agogo mẹrin irọlẹ oni, Ọjọru ni ipade naa yoo tun tẹsiwaju, eyi ti ko si tii le sọ ibi ti ipade ọhun yoo tun yọri si.
Gẹgẹ bi ohun ti a gbọ, wọn ni ẹgbẹrun mẹrinlelaadọta ni ijọba apapọ loun yoo bẹrẹ sii san fun awọn oṣiṣẹ, eyi ti wọn sọ pe ijọba ko mu ọrọ naa ni ọkunkundun.
Ẹgbẹ oṣiṣẹ sọ pe owo naa kere si ẹgbẹrun mẹtadinlọgọrin (N77,000) naira ti awọn n gba tẹlẹ, fun idi eyi, wọn ni ko le ṣee ṣe nitori pe apadasi buruku ni yoo jẹ fun awọn.
A gbọ pe lara ṣaaju ki ipade naa to foriṣanpọn, ẹgbẹ awọn oṣiṣẹ ti ṣeleri pe bi awọn gomina ko ba si nibi ipade ti yoo waye lonii, Ọjọru, awọn ko nii ba ẹnikẹni jokoo ipade.
Nigba to n fidi ohun to ṣẹlẹ nibi ipade naa mulẹ, ọkan lara awọn ọmọ igbimọ to n ri sọrọ owo oṣu apapọ, Ọjọbọn Theophilus Ndubuaku kọminu lori bi awọn gomina mẹfa ti wọn ṣoju ẹkun mẹfẹẹfa orileede yii ko ṣe yọju.
Ọjọgbọn Ndubuaku sọ pe bi awọn gomina yii ba kọ tun kọ lati yọju sibi ipade naa lonii, o ṣee ṣe ki nnkan ma tun lọ bo ṣe yẹ ko lọ.
Bẹẹ lo fidi rẹ mulẹ pe otitọ ni pe ẹgbẹ oṣiṣẹ ti fẹnuko lori ọjọ kọkanlelọgbọn, oṣu karun-un fun ijọba pari gbogbo eto lori ọrọ owo oṣu tuntun.
Ninu ọrọ rẹ, o sọ pe “O gba wa ni ọpọlọpọ asiko ki a to le sọ ohun to wa lọkan wa gẹgẹ bi ijọba. Igba to ya ni minisita to n ri sọrọ awọn oṣiṣẹ sọ pe ijọba yoo san ẹgbẹrun mẹrinlelaadọta naira gẹgẹ bi owo oṣu tuntun.
“A tiẹ tun ṣi sọ fun wọn pe eyi ko tunmọ si nnkankan. Wọn ko tii bẹrẹ idunadura bayii, nitori pe owo to kere julọ ti awọn oṣiṣẹ ijọba apapọ n gba, ẹgbẹrun mẹtadinlọgọrin naira ni. Gẹgẹ bi oju ti wọn fi wo o, wọn ro pe a ko tii bẹrẹ idunadura lori owo oṣu tuntun.
“Ohun ti a n dunadura le lori ni adinku owo oṣu, nitori pe bi a ba kuro nibẹ, ti a sọ fun wọn pe ẹgbẹrun mẹrinlelaadọta naira ni a fẹnuko si, ohun to tunmọ si ni pe ka lọ sọ fun gbogbo awọn to ti n gba ẹgbẹrun mẹtadinlọgọrin naira pe adinku ti de ba owo oṣu ti wọn n gba tẹlẹ.
“A sọ fun wọn pe ko si oṣiṣẹ to maa gba owo to kere si iye to n gba tẹlẹ. Ṣe ka sọ pe adinku ti de ba bi owo nnkan ṣe lọ soke ni tabi ka sọ pe owo ti awọn eeyan fi n ra ounjẹ ti lọ silẹ?”
₦48,000 owó oṣù tó kéré jùlọ tíjọba fẹ́ san fún òṣìṣẹ́ tàbùkù wá - Ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ fọnmú
Ẹgbẹ osisẹ lorilẹede Naijiria NLC ati TUC ni wọn ti koroju si aba ijọba apapọ, ti wọn si binu jade lasiko ipade wọn to waye lọjọru.
Ohun to fa ibinu naa wa nipa iye ti owo oṣu osisẹ to kere ju lọ yoo jẹ.
Ẹgbẹrun mejidinlaadọta Naira ni iye owo oṣu to kere ju ti ijọba apapọ gbe kalẹ fun awọn ẹgbẹ osisẹ pe oun lagbara lati san.
Amọ awọn osisẹ koro oju si igbesẹ naa, ti wọn si ṣapejuwe rẹ gẹgẹ bii iwọsi, ti wọn si binu jade.
Aarẹ NLC, Joe Ajaero ṣalaye pe ijọba apapọ ko ti ṣetan lati duna dura nipa iye owo oṣu to kere ju yoo jẹ.
O fikun pe ijọba apapọ ko ni oye to kun to lati ba ẹgbẹ oṣisẹ sọrọ.
Ajaero wa jẹ ko di mimọ pe, ẹgbẹ osisẹ ko ni yi ohun rẹ pada, ti ijọba apapọ si ni di ipari oṣu ti a wa yii lati gbe igbesẹ to yẹ.
Ki lo ti saaju laarin ijọba apapọ ati ẹgbẹ osisẹ?
Ẹgbẹ oṣiṣẹ ni Naijiria fun ijọba apapọ ni gbedeke ọjọ kọkanlelọgbọn oṣu Karun un yii lati fẹnuko lori N615,000 t'awọn oṣiṣẹ n beere fun.
Awọn adari ẹgbẹ oṣiṣẹ sọrọ yii nibi ayajọ ọjọ awọn oṣiṣẹ lọjọ kinni oṣu Karun un ọdun 2024.
Lasiko ti ayẹyẹ ayajọ ọjọ oṣiṣẹ n lọ lọwọ niluu Abuja ni ẹgbẹ oṣiṣẹ sọ koko mejidinlogun ti awọn n fẹ ki ijọba ṣe, eyi ti N615,000 gẹgẹ bi owo oṣu oṣiṣẹ to kere julọ jẹ ọkan gboogi lara wọn.
Aarẹ ẹgbẹ oṣiṣẹ NLC, Joe Ajaero ati Festus Osifo ti ẹgbẹ TUC fi aidunnu wọn han lori bi igbe aye awọn oṣiṣẹ ko ṣe rọrun ni bii ọdun kan sẹyin.
Wọn ni N30,000 owo oṣu oṣiṣẹ to kere julọ ti ijọba n san tẹlẹ ti dopin lati ọjọ kejidinlogun oṣu Kẹrin to kọja labẹ ofin.
Wọn ni o ti yẹ ki ijọba ti bẹrẹ si ni san owo oṣu tuntun fawọn oṣiṣẹ bayii.
Awọn adari ẹgbẹ oṣiṣẹ naa ni awọn ko ni gba owo to din ni N615,000 gẹgẹ bi owo oṣu oṣiṣẹ to kere julọ.
"N615,000 ni owo to le to fun awọn oṣiṣẹ lati gbe iye aye to gbadun pẹlu bi nnkan ṣe wọn gogo bayii.
A ti jiroro lori bi nnkan ṣe ri ni Naijiria, a ṣi ti ri pe N615,000 lo le to oṣiṣẹ ti ipo rẹ kere julọ na loṣu kan.
Awọn adari ẹgbẹ oṣiṣẹ ni arumọjẹ lasan ni afikun 25% ati 35% ti ijọba apapọ kede, wọn ni owo osu to kere julọ tawon n beere fun lo ṣe koko.















