Chelsea fọwọ́ òsì júwe ilé fún akọ́nimọ̀ọ́gbá Pochettino lẹ́yìn oṣù mẹ́wàá

Mauricio Pochettino

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ẹgbẹ agbabọọlu Chelsea ti kede pe awọn ti pinya pẹlu akonimọọgba wọn, Mauricio Pochettino lẹyin oṣu mẹjọ pere lẹnu iṣẹ

Ọjọ kinni oṣu Keje ọdun 2023 ni Pochettino bẹrẹ iṣẹ olukọni Chelsea ti o ṣi ṣiṣẹ naa fun saa bọọlu kan pere.

Ni akoko rẹ, Chelsea wọ ipele aṣekagba idije Carabao Cup ninu eyi ti Liverpool ti lu wọn gba ife naa.

Bakan naa ni wọn tun wọ ipele to kangun si asekagba ninu idije FA Cup.

Pochettino ni akonimọọgba kẹta ti Chelsea ti le lọ bayii lati ọdun 2022 ti Todd Boely ti ra ẹgbẹ agbabọọlu naa.

Ninu ọrọ ti wọn fi lede loju opo ayelujara wọn, Chelsea dupẹ lọwọ Pochettino fun akoko rẹ ni Chelsea.

Wọn awọn ko tii fẹ sọ ju bayẹn lọ lori ọrọ naa.