Wo ọ̀nà tí Deji Akure kò gbọdọ̀ gbà ju ẹ̀ẹ̀kan lọ láàfin rẹ̀ tí yóò fi jáde láyé

Àkọlé fídíò, Wo ọ̀nà tí Deji Akure kò gbọdọ̀ gbà ju ẹ̀ẹ̀kan lọ tí yóò fi jáde láyé
Wo ọ̀nà tí Deji Akure kò gbọdọ̀ gbà ju ẹ̀ẹ̀kan lọ láàfin rẹ̀ tí yóò fi jáde láyé

Yoruba bọ, wọn ni idalu ni iṣelu, eyi lo difa fun ọna kan ti Deji ti ilu Akure ko gbọdọ gba ju ẹẹkan lọ titi ti yoo fi jade laye.

Oloye Sele ti ilẹ Akure, Taiwo Fagite sọ fun BBC pe aafin Adimula Deji ti Ilu Akure jẹ ọkan ninu awọn aafin to ti pẹ julọ nilẹ Yoruba, ti o ṣo tun ṣe pataki bakan naa.

Oloye Fatige ni ọna owurọ ni wọn n pe ọna yii eyi ti Deji maa n gba ni ẹẹkan laye iyẹn lọjọ ti wọn ba ti fi wọn jẹ ọba.

Lara awọn nnkan iṣẹnbaye mii to wa laafin Deji Akure ni ere Aṣọdẹboyede to jẹ ọba akọkọ ni Akure.

Orukọ baba rẹ ni ‘’Ẹkun’’ ti i ṣe ọmọ Oduduwa.

Ibomiran ninu aafin Deji ni wọn n pe ni ‘’UA LILA’’ to jẹ ibi ti Deji Akure ti maa n pade awọn eeyan Akure.

Aafin Deji Akure ti le ni ẹgbẹrin ọdun bayii gẹgẹ bi akọsilẹ ṣe sọ.

Oloye Sele ni ''a n gbiyanju lati daabo bo aafin yii tori o ti wa lati nkan bi ọdun 826 sẹyin, ohun ta n ṣe ni pe ka ro o, ko le duro daadaa, ko ma lọ di wi pe ko maa lọ dẹgbẹ si apa kan kan tori ile yẹpẹ ni.

‘’UA Ibura’’ ṣi tun jẹ ibomiran to ṣe pataki ninu aafin yii tori ẹnikan kan ko gbọdọ parọ nibẹ.

Nibẹ lawọn eeyan to ba ni edeaiyede ti maa n bura tabi awọn to ba fẹ jẹ oye.

Nibẹ ni wọn ti maa n bura wi pe awọn yoo ṣe olootọ si Deji Akure, awọn ko dẹ ni ditẹ.

Oloye Fatige tun sọ nipa kẹkẹ kan awọn lọba lọba to wa laafin Deji, eyi ti kabiesi maa n gun ti wọn ba fẹ lọ ṣe ayẹyẹ ni ita aafin.

Kẹkẹ yii ni a gbọ pe o ti le ni ọgọrun ọdun to ti wa ninu aafin Deji ni Akure.