Ẹ̀kúnwó N615,000 t'ẹ́gbẹ́ òṣìṣẹ́ ń bèèrè pọ̀jù, N48,000 tí ìjọba fẹ́ san kéré - onímọ̀ nípa ọrọ̀ ajé

Gbajugbaja onimọ nipa eto ọrọ aje lorileede Naijiria, Ọgbẹni Bisi Iyaniwura ti sọ pe kii ṣe aisko yii lo yẹ ki ẹgbẹ awọn oṣiṣẹ lorileede Naijiria maa beere fun afikun lori owo oṣu.
Onimọ nipa eto ọrọ-aje naa sọ pe apada si buruku ni N48,000 ti ijọba n fi lọ awọn oṣiṣẹ, tori wọn ti n san N65,000 fun wọn lati ọdun to kọja pẹlu owo iranwọ ti wọn n gba.
Bakan naa ni N615,000 ti ẹgbẹ oṣiṣẹ n beere pọju pẹlu bi ọrọ-ajẹ Naijiria ṣe dẹnulọlẹ lasiko yii.
O ni niṣe lo yẹ ki ijọba da inakuna to n na duro ki o si ṣe afikun owo oṣu to jọju fawọn oṣiṣẹ.
Iyaniwura to tun jẹ ogbontarigi agbẹjọro ni dipo ki ẹgbẹ awọn oṣiṣẹ maa pariwo lori afikun owo oṣu, bi irọrun yoo ṣe ba gbogbo araalu lo yẹ ki wọn ja fun.
Lasiko to n ba BBC Yoruba sọrọ, Iyaniwura ṣalaye pe eto ọrọ aje Naijiria ti dẹnukọlẹ, to si yẹ ki ẹgbẹ oṣiṣẹ wa ọna lati jokoo ipade pẹlu ijọba apapọ lori bi ọwọngogo yoo ṣe di ohun igbagbe, ti araalu yoo si bẹrẹ sii gbadun.
Ninu ọrọ rẹ, o ṣalaye pe “bi a ba maa wo daadaa, akoba nla ni yoo ṣe, anfaani diẹ lo kan maa wa nibẹ.
Lara akoba to maa ṣe ni pe, ẹ jẹ ka beere lọwọ ara wa, ṣe orileede wa ni owo to to bẹẹ lati maa san loṣooṣu fun awọn oṣiṣẹ.
Nigba to n sọrọ, Iyaniwura sọ pe ohun to yẹ ki oṣiṣẹ maa ja fun ni bi igbe aye irọrun yoo ṣe ba gbogbo ọmọ ati olugbe Naijiria, ki ọwọngogo di ohun igbagbe.
“Ẹlẹẹkeji ni pe awọn oṣiṣẹ ti wọn n ja yii, wọn ti gbagbe awọn ileeṣẹ kerejekereje ti wọn ko lowo lọwọ. Nibo ni wọn ti fẹ ki wọn ri owo naa san?
“Ẹni to jẹ pe gbogbo owo to fi ṣi ṣọọbu ko to miliọnu marun-un naira, nibo ni ko ti ri ẹgbẹrun lọna ogunlelẹgbẹtadinmarun-un (N615,000) naira, ohun ti wọn n sọ ni pe ki wọn kogba wọle?
“Ti emi ba maa ba ẹgbẹ awọn oṣiṣẹ sọrọ, maa sọ fun wọn pe kii ṣe ọrọ owo oṣu lo yẹ ki wọn ja fun, bi ko ṣe igbe aye irọrun fun gbogbo araalu.
“Ki olowo ati mẹkunnu ri ina ọba lo, ko ma si nnkan to n jẹ Band A ati B.
Ki owo naira lagbara sii.
“Ẹ jẹ ka tun beere lọwọ ara wa pe ijọba ipinlẹ meloo lo n san ẹgbẹrun lọna ọgbọn naira latigba ti ofin naa ti wa nita. A ni to ṣi n san ẹgbẹrun mejidinlogun ni ẹkun Guusu-Iwọ-Oorun Naijiria yii.
“Ṣe awọn ti ko tii ri ẹgbẹrun lọna ọgbọn naira san lẹ wa sọ pe ki wọn wa san ẹgbẹrun lọna ogunlelẹgbẹtadinmarun-un naira, nibo lẹ ti fẹ ki wọn ri owo san.
Wọn ko nii ṣiṣẹ idagbasoke ilu mọ nigba ti wọn ba ti fi gbogbo owo san owo oṣu oṣiṣẹ.
“Kii ṣe afikun lo yẹ ki wọn maa ja fun, bi ko ṣe ki wọn ja fun pe iwọnba ti wọn n gba naa, ko ba wọn de ile, ki owo ile si wa silẹ.
“Ijọba Eko loun fẹẹ da eto kan silẹ wi pe ki awọn onile maa gba owo loṣooṣu, ṣe ijọba lo kọ ile fun wọn ni.
Lati gba iwe ile kikọ l’Eko lasiko yii, obitibiti miliọnu owo naira ni. Gbogbo owo iwe ti a n gba lọwọ ijọba, ojoojumọ lo n lọ soke.
“Ijọba n fi owo kun owo nnkan, ẹ wa sọ pe ki owo oṣu naa ma lọ soke. Afikun lori owo ina, iwe ọkọ, iwe ile kikọ ati bẹẹbẹẹlọ, o di dandan ki awọn eeyan naa beere ẹtọ ti wọn lọwọ ijọba, ṣugbọn kii ṣe nipa afikun rẹpẹtẹ, bi ko ṣe igbe aye irọrun.
“Ifọkanbalẹ araalu ni ki wọn ja fun. Eto ọrọ aje wa ko le gba ẹgbẹrun lọna ọgọrun naira, ka ma too sọ aduru owo ti wọn n beere yii.
“Ẹ ba ijọba jokoo lati sọrọ bi owo epo yoo ṣe lọ silẹ. Ki wọn ṣiṣẹ lori ile ifọpo, ka si yee ra epo loke okun. Ohun to yẹ ki wọn ja fun ni pe awọn naa fẹ gbe igbe aye bi eeyan.”
A ṣì dúró lórí N615,000 gẹ́gẹ́ bí owó oṣù tó kéré jùlọ - Ẹgbẹ́ Òṣìṣẹ́

Oríṣun àwòrán, getty images
Igbimọ onígun mẹta to n dunadura lori owo osu tó kéré jùlọ fáwọn òṣìṣẹ́ lorilẹede Nàìjíríà, tun tí fẹnu ko lati joko ṣe ipade pẹlu ìjọba àpapọ̀ lónìí ọjọ́ ìṣẹ́gun.
Etim Okon tíì ṣe igbakeji ààrẹ ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ TUC ló fìdí ọ̀rọ̀ náà múlẹ̀ lásìkò ifọrọwerọ pẹlu awọn akọroyin NAN nilu Abuja.
Níbi ìpàdé to wáyé ṣáájú ni ìjọba apapọ ti kede pe ẹgbẹ̀rún mejidinlaadọta Naira ni òun lagbara lati san bíi owó oṣù tó kéré jùlọ fáwọn òṣìṣẹ́.
Èyí sì lo mú káwọn aṣojú ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ náà bínú jáde níbi ìpàdé náà pẹlu alaye pé owó náà tàbùkù àwọn òṣìṣẹ́, tí wọn kò sì fi ẹnu ijiroro wọn ko síbi kan.
Àmọ́ Okon tí wá kéde pé ìjọba àpapọ̀ tí tọrọ aforiji lórí ìkéde rẹ náà, tí àwọn sí ti fẹnu kò láti ṣe ìpàdé miran ni ọjọ́ ìṣẹ́gun, tí ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ yóò sì péjú síbi ìpàdé náà.
"A ti béèrè N615,000 bíi owó oṣù tó kéré jùlọ fún òṣìṣẹ́ lọdọ ìjọba níbi ìpàdé tó kọjá naa, ká tó bínú jáde, ìjọba kò sì tíì tako ìbéèrè wá.
A kàn tako N48,000 owó oṣù tó kéré jùlọ tíjọba gbé kalẹ̀ nítorí wọn kò ṣàlàyé fún wa bí wọn ṣe ṣírò owó naa tó fi kú sí ìyè yìí.
Wọn kò bá wà ro owó ọkọ, ilegbe, oúnjẹ, owona atigbadegba, ìwọ iná, ìlera, eto ẹ̀kọ́ àti bẹẹ bẹẹ lọ."
Ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ wá rọ ìjọba láti kéde owó oṣù tó kéré jùlọ fún òṣìṣẹ́ to fẹ́ san pelu alaye bo se ṣírò owó naa, tó fi kú sí ìyè ọhun.


























