Ilé ẹjọ́ da ẹjọ́ Nnamdi Kanu nù, da padà sí àhámọ́ DSS

Nnamdi Kanu

Oríṣun àwòrán, others

Ile ẹjọ giga to wa niluu Abuja ti da ẹjọ ti olori ẹgbẹ IPOB, Nnamdi Kanu pe tako bo ṣe wa ni ahamọ ajọ ọtẹlẹmuytẹ DSS nu.

Ṣaaju ni Kanu ti kọkọ bẹ ile ẹjọ ọhun pe ko mu oun kuro ni ahamọ DSS lọ si ọgba ẹwọn tabi ko fi oun si ahamọ inu ile.

Adajọ to n gbọ ẹjọ naa, Binta Nyako sọ irufẹ ẹjọ bẹẹ ti wa siwaju oun ri ti oun si da ẹjọ naa nu ni nitori ko lẹsẹ nilẹ.

Nyako ni oun ri daju pẹlu ẹri pe Kanu salọ lasiko ti wọn kọkọ fun ni beeli akọkọ ti awọn to si fa kalẹ fun beeli naa si sọ pe awọn ko mọ ibi to wa.

O fi kun pe ohun kan ṣoṣo to ku fun Kanu bayii ni ko gba ile ẹjọ kotẹmilọrun lọ lati pe ẹjọ nibẹ.

Ẹwẹ, Kanu ti sọ pe oun ko le jẹjọ niwaju ile ẹjọ kankan ni Naijiria.

Gẹgẹ bii ohun to sọ, ti wọn ba ṣedajọ ẹwọn fun oun, o n tumọ si pe ile ẹjọ ru ofin orilẹede Naijiria ati ofin awọn orilẹede mii lagbaye.

Lónìí ni Kanu yóò mọ̀ bó yá yóò kúrò ní àhámọ́ àjọ DSS

Aworan Nnamdi Kanu

Oríṣun àwòrán, Other

Oni, ọjọ Aje, ogunjọ, oṣu karun-un ni olori ajijangbara ilẹ Biafra, IPOB, Nnamdi Kanu yoo tun foju ba ile-ẹjọ lati gbọ erongba ile-ẹjọ lori lori ẹbẹ rẹ lati gbe e kuro ni ahamọ ọlọpaa ọtẹlẹmuyẹ, DSS.

Lọjọ kẹtadinlogun, oṣu kẹrin, ọdun yii ni onidajọ Binta Nyako sun igbẹjọ ọhun siwaju di oni, lẹyin to ti gbọ ọrọ lati ẹnu awọn agbẹjọro.

Agbẹjọro Kanu, Aloy Ejimakor nigba to n sọrọ sọ pe niṣe ni ajọ DSS n tẹ ẹtọ onibara ohun loju mọlẹ, pẹlu bi wọn ṣe n fojoojumọ fi si ahamọ wọn.

Bẹẹ lo ni awọn bii Sambo Dasuki to ti figba kan ri jẹ oludamọran pataki fun aarẹ lori ọrọ eto aabo ati olori ikọ musulumi kan, Sheik Ibraheem El-Zakzaky ti jẹ anfaani yii ri, ko si sohun to sọ pe ki Kanu naa ma lẹtọ si iru anfaani ominira bẹẹ.

O ni ki ile-ẹjọ paṣẹ pe ki ajọ DSS fi Kanu silẹ lati gba ominira ara rẹ.

Ṣugbọn nigba to n tako ipẹjọ naa, agbẹjọro DSS, Adegboyega Awolomo sọ pe ipẹjọ ti ko lẹsẹ nilẹ ni, ati pe ki ile-ẹjọ wọgi le.

Onidajọ Nyako ti wa sọ pe ogunjọ, oṣu karun, ọdun 2024 tii ṣe oni ni igbẹjọ ọhun yoo waye lati gbọ erongba ile-ẹjọ lori rẹ.