Orúkọ ń ro ni! Oríògbadé FC padà mófo, Man City já ife ẹ̀yẹ EPL gbà mọ́ wọn lọ́wọ́

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Gbogbo akitiyan ẹgbẹ agbabọọlu Arsenal lati gba ife ẹ̀yẹ idije Premier League fun igba akọkọ ni nnkan bi ogun ọdun ni saa bọọlu 2023/2024 yii, pabo lo jasi.
Erongba Arsenal at'awọn ololufẹ wọn saaju ọjọ Aiku ti i ṣe ọjọ asekagba idije EPL fun saa bọọlu yii ni wi pe ki West Ham lu Man City mọle nigba ti Arsenal yoo si lu Everton lati le gbade Premier League.
Amọ, ọrọ bẹyin yọ nigba ti ere bọọlu naa bẹrẹ lọsan ọjọ ìsinmi.
Phil Foden lo kọkọ gba goolu s'awọn West Ham ni papa iṣere Etihad fun Man City, eyi to kọkọ da omi tutu sọkan awọn ololufẹ Arsenal.
Laipẹ ni Foden tun gbayo keji wọle ti Man City si bẹrẹ si ni lewaju pẹlu ami ayo meji sodo.
Mohamed Kudus gba goolu kan wọle City lojiji eyi to jẹ ki ọpọ bẹrẹ si ni ro pe o ṣeeṣe ki West Ham gba ayo mii wọle ki wọn si ta ọmi pẹlu City eyi ti yoo fun Arsenal lanfaani lati gbade EPL.
Amọ, ẹpa ko boro mọ nigba ti Rodri gbayo kẹta wọlé fun Man City lo ba di 3-1 eyi ti ere bọọlu naa pari si.
Ni kẹkẹ ba pa mọ atioro awọn ololufẹ Arsenal lẹnu ni papa iṣere Emirates.
Tomiyasu sọ ere bọọlu ọhun di ọmi 1-1 lẹyin to dayo kan pada sile Everton.
Lẹyin o rẹyin, Kai Harvert gbayo keji wọle fun Arsenal eyi ti wọn fi bori.
Arsenal bori ni tootọ, amọ, Man City lo gbade EPL, tori wọn fi pọinti meji siwaju wọn.
Ki a to wi ki a to fọ ninu ere bọọlu to n lọ ni Emirates, Everton ti gba goolu wọlé Arsenal lai ro tẹlẹ.
Wo ọ̀nà tí Arsenal fi lè gba ife Premier League mọ́ Man City lọ́wọ́ lónìí

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Lonii ọjọ kọkandinlogun oṣu Karun un ọdun 2024 yii ni idije Premier League ti saa yii yoo wa sopin.
Oni yii naa la o mọ ẹgbẹ agbabọọlu ti yoo gb'ade EPL laarin Manchester City ati Arsenal ti wọn wa ni ipo kinni ati ipo keji.
Ni bayii, Man City lo wa loke tábìlì EPL pẹlu ami ayo 88, nigba ti Arsenal wa ni ipo keji pẹlu ami ayo 86.
Man City le maa fi ami ayo meji lewaju Arsenal ni tootọọ, ṣugbọn Arsenal ti ni goolu mokanlelọgọta nilẹ, nigba ti Man City ni ọgọta.
Ẹgbẹ agbabọọlu West Ham ni Man City yoo koju ninu Ifesewonse wọn to kẹyin ni papa ìṣeré Ehihad, nigba ti Arsenal yoo koju Everton ni Emirates.
Bawo ni Arsenal ṣe le gba ife Premier League mọ Man City lọwọ?
BBC Yoruba ti ṣalaye ọna ti Arsenal fi le gba liigi EPL mọ Man City lọwọ, bi bẹẹ kọọ, Man City ni yoo tun gbade ọhun fun ọdun kẹrin lera wọn.
Bi Arsenal ba gbo ewuro soju Everton ti Man City naa ba lu West Ham, Man City ni yoo tun gbade EPL saa bọọlu yii.
Ami ayo meji ni City yoo fi la wọn mọlẹ tawọn mejeeji ba jọ jawe olubori ninu Ifesewonse to kẹyin lonii ọjọ Aiku.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Amọ, ti Man City ba ta ọmi pẹlu West Ham ti Arsenal si lu Everton, Arsenal ni yoo gba ife Premier League tori goolu wọn pọ ju ti Man City lọ, bo tilẹ jẹ pe ami ayo kan naa l'awọn mejeeji yoo jọ ni.
Ti Man City ba jawe olubori ninu ifẹsẹwọnsẹ ti Arsenal ba le ta ọmi tabi fidirẹmi ninu ifẹsẹwọnsẹ wọn pẹlu Everton, Man City ni yoo gba liigi EPL mọ wọn lọwọ.
Ọna kan to daju fun Arsenal lati gba ife Premier League lonii ni ki West Ham lu Man City ki Arsenal si fiya jẹ Everton.
Ipade dori papa laago mẹrin ọsan oni.















