Ìdí tí mi ò fi ń kópa nínú eré ṣíṣe mọ́ rèé - Sanyẹri

Oríṣun àwòrán, @sanyeri234)Instagram
O ti to ọjọ mẹta kan ti awọn ololufẹ gbajumọ oṣere tiata nni, Ọlaniyi Afọnja tawọn eeyan mọ si Sanyẹri ti ri i gbẹyin ninu fiimu agbelewo Yoruba.
Eyi ri bẹẹ pẹlu bo ṣe jẹ pe ọpọ ere lo ti jade lori ayelujara bii ẹka You-Tube atawọn mi-in ṣugbọn ti Sanyẹri ko kopa nibẹ gẹgẹ bi iṣe rẹ.
Ọkunrin to maa n kopa adẹrin-in-p’oṣonu ninu sinima Yoruba naa ti waa ṣalaye idi to fi sinmi lẹnu iṣẹ taye ti mọ-ọn, to si tun jẹ ọna ati ri ọwọ mu lọ sẹnu fun un.
Kí ni Sanyẹri wí nípa àìkópa nínú sinimá mọ́

Oríṣun àwòrán, @sanyeri234) Instagram
Lori eto kan ti Kọla Olootu, sọrọsọrọ agba niluu Ibadan ti ba Sanyẹri sọrọ ni gbajumọ oṣere naa ti sọ pe,
‘’Nnkan ko ṣe mi, ki i ṣe pe ohunkohun mu mi ni mi o ṣe kopa ninu fiimu mọ.
‘’Ohun to ṣẹlẹ ni pe ti eeyan ba ti lorukọ tan, ọna ti orukọ naa ko fi ni i dohun igbagbe lo yẹ ko maa wa.
''Iyẹn lo ṣe pataki ju keeyan maa kopa lasan kiri lọ.
‘’Ki i ṣe gbogbo ere ti wọn pe eeyan si lati ṣe leeyan yoo maa sare gba ti yoo si maa ṣe.
‘’ Eeyan gbọdọ tiẹ kọkọ beere iwe itọsọna (script) ti yoo sọ ipa teeyan fẹẹ ko ninu fiimu naa.
‘’Nitori ẹ lo fi jẹ pe emi ki i sare da awọn eeyan lohun lati kopa ninu iṣẹ wọn.
‘’Awọn eeyan le jẹri mi pe mi o ki i gba oko ere kan de omi-in. Bii ki ẹnikan sare pe mi pe ki n waa ba oun kopa abala bii mẹta, ti mo si wa ni lokeṣan kan lọwọ.
‘’Emi o ki n ṣeru ẹ. Mi o ni i ba wọn ya a, nitori mi o mọhun ti wọn ti ya lati ibẹrẹ ki wọn too ni ki n sare waa kopa mẹta.
‘’Ara nnkan tẹ ẹ o fi ri mi lẹnu ọjọ mẹta yii ninu sinima niyẹn’’
Sanyẹri fi kun alaye ẹ pe ọrọ owo ti yoo pari fiimu naa tun jẹ koko kan.
O loun ki i tan eeyan lori iye to ba yẹ ko ya sọtọ lati pari iṣẹ, oun yoo sọ otitọ fun wọn.
Ṣugbọn bo ṣe jẹ pe aye kọ otitọ, ti Ọlọrun ko si fẹ aisododo, afi keeyan ṣọra.
Ọmọ bibi ilu Ọyọ Alaafin naa pari ọrọ rẹ pe bo ṣe wu ko ri ṣaa, otitọ ni yoo leke irọ lọjọ gbogbo.














