Binance tún lúlẹ̀ ní Nàìjíríà, ile ẹjọ́ ní kò sí àyè béèlì fún òṣìṣẹ́ rẹ̀ tó ń jẹ́jọ́ EFCC

Oríṣun àwòrán, Binance/Nairametrics
Ile ẹjọ giga apapọ kan nilu Abuja, olu ilu Naijiria ti kọ lati gba oniduro fun ọgaagba ileeṣẹ isuna ori ayelujara ni, Binance, Ọgbẹni Tigran Gambaryan, ẹni to ti wa ni ọgba ẹwọn Kuje lati nnkan bii ogoji ọjọ.
Onidajọ Emeka Nwite to n gbọ ẹjọ naa jẹ hoo si awijare ikọ olupẹjọ to ni bi wọn ba gba oniduro ọgaagba ileeṣẹ Binance naa, afaimọ ko maa na papa bora.
Ọgbẹni Tigran Gambaryan, akẹgbẹ rẹ Nadeem Anjarwalla to ti na papa bora bayii ati ileeṣẹ iṣuna Binance Holdings n jẹ ẹjọ ti ajọ to n gbogun ti iwa ijẹkujẹ lorilẹede Naijiria, EFCC n fi kan wọn pe wọn n lọwọ ninu iwa gbigba ọna ẹburu ko owo kuro lorilẹede Naijiria, ti owo ti a n sọrọ rẹ yii si n le ni bii miliọnu marundinlogoji dọla ($35.4m).

Oríṣun àwòrán, binance
Bakan naa ni ileeṣẹ agbowo ori ni Naijiria, FIRS pẹlu n fi ẹsun mẹrin to nii ṣe pẹlu kikuna lati san owo ori kan wọn.
Gbogbo ẹsun yii ni wọn ni awọn ko jẹbi rẹ.
Igbẹjọ lori kiko owo kuro lorilẹede Naijiria lọna ti ko bofinmu bẹrẹ lọjọ Ẹti nibi ti ẹlẹri kan lati ileeṣẹ idokoowo Naijiria, SEC ti jẹri.
Bi ẹ ko ba ni gbagbe, ni ọsẹ to kọja ni alaṣẹ ati oludari ileeṣe Binance, Richard Teng pariwo sita pe awọn oṣiṣẹ ijọba Naijiria kan beere fun aadọjọ miliọnu dọla ($150m) owo ori ayelujara (digital currency) gẹgẹ bi owo riba lọwọ Gambaryan lati pa ina ẹjọ naa mọlẹ.
Awọn alasẹ ijọba ni Naijiria ti fi eyín ọwọ da ẹsun naa nu ti wọn si tọka sii gẹgẹbi ọrọ ibanilorujẹ lasanlasan.















