"A máa fún ọ ní N50m, gbé ọ pamọ loke okun, tó o bá fún wa ní ojúlówó ìròyìn nípa ohun tó pa Mohbad "

Oríṣun àwòrán, Mohbad/instagram
Ẹgbẹ kan ti wọn n pe African Television and Foundation for Justice ti kede sita pe awọn ṣetan lati gbe aadọta milọnu naira kalẹ fun ẹnikẹni to ba le pese ojulowo iroyin nipa ohun to ṣekupa Ilerioluwa Aloba, ti ọpọ mọ si Mohbad.
Saaju ni ọnimọ nipa ayẹwo oku farahan ni ile ẹjọ pe awọn ti ṣe ayẹwo ohun to sokunfa iku Mohbad sugbọn awọn ko le tọka si nnkan pato to ṣekupa Mohbad.
Iroyin yii ni ko dun mọ ọpọ awọn ọmọ orilẹede Naijiria ninu nitori o ti to oṣu meje ti pupọ ninu wọn ti n duro de esi ayẹwo naa.
Ninu ọrọ to sọ lẹyin ijoko ileẹjọ to n sewadi iku Mohbad, ọga agba fun ileeṣẹ naa, Larry Omodia kan sara si igbiyanju ileeṣẹ ọlọpaa lati ṣe iwadii iṣẹlẹ naa.
O ni o ṣe koko ki ọrọ lori iku Mohbad tẹnubọlẹ, bo ti lẹ jẹ pe o jẹ iṣẹlẹ to n dun ni pupọ lọkan.
“Lati le ṣe iranlọwọ fun ileeṣẹ ọlọpaa, Ileeṣẹ African Television n kede sita pẹlu ajọṣepọ awọn akẹgbẹ wa pe a o gbe aadọta milọnu kalẹ fun ẹnikẹni to ba le pese iroyin to le ṣe iranlọwọ nipa ohun to ṣekupa Mohbad.
“Ti o ba mọ nnkan nipa iku Mohbad, kesi wa, a n fi da yin loju pe a gbe aadọta miliọnu kalẹ fun ẹni naa, ti a yoo si tun gbe lọ si oke okun fun abo.”

Baba Mohbad bú s'ẹ́kún lẹ́yìn tí àyẹ̀wò kùnà láti sọ ikú tó pa ọmọ rẹ̀
Wayi o, Joseph Aloba to jẹ Baba Mohbad ni fọnran kan lori ayelujara Tiktok ti ṣafihan bi o ṣe n tomi loju lẹyin ti dokita kede fun ile ẹjọ pe iwadii ko le sọ ohun pato to ṣekupa Mohbad.
Baba Mohbad, ẹni to ti n duro de esi ayẹwo fun oṣu meje bayii ni ọrọ to jade lati ẹnu dokita ko dun mọ ninu.
Ọpọ awọn eeyan lori ayelujara lo ti ranṣẹ ibanikẹdun si Baba Mohbad lori ọrọ iku Mohbad.
Nibi igbẹjọ to waye nile ẹjọ lọjọru, ọjọ Kẹẹdogun, oṣu Karun-un, ọdun 2024 ni dokita to ṣe ayẹwo oku naa ti wa sọ ohun ti esi ayẹwo naa wi.
Ninu fidio kan to gba ori ayelujara to ṣafihan ibi tí agbẹjọro Waha Shittu ti n ba awọn akọroyin sọrọ lẹyìn igbẹjọ naa ni awọn to ṣe ayẹwo oku naa ni oku Mohbad ti jẹra pupọ ki awọn to ṣe ayẹwo oku rẹ nitori naa awọn ko le fidi ohun to ṣekupa a mulẹ.
“Ko rọrun fun wa lati mọ ohun to ṣekupa Mohbad nitori oku rẹ ti jẹra pupọ ki a to ṣe ayẹwo lati mọ ohun to pa a.
“Ní kukuru a o le sọ pe nnkan bayii lo pa Mohbad.”















