Kí ni Portable kọ sínú orin tó gbé jáde lẹ́yìn tó kúrò ní àhámọ́ ọlọ́pàá?

Portable

Oríṣun àwòrán, @portablebaeby

Gbajúmọ̀ olórin tàkasúfèé nnì, Habib Okikiola tí ọ̀pọ̀ mọ̀ sí Portable ti gbé orin kan jáde lẹ́yìn tó kúrò ní àhámọ́ ọlọ́pàá.

Lẹ́yìn wákàtí díẹ̀ tí Portable gba ìtúsílẹ̀ kúrò ní àhámọ́ ọlọ́pàá ló gbé orin náà síta.

Portable, lórí ìkànnì Instagram rẹ̀, lọ́jọ́bọ̀, ọjọ́ Kẹrìndínlógún, oṣù Karùn-ún, ọdún 2024 fi orin tó pé àkọ́lé rẹ̀ ní “Spiderman” síta láti fi sọ̀rọ̀ ohun tó gbe dé àhámọ́ ọlọ́pàá.

Ẹ ó rántí pé lọ́jọ́ Ìṣẹ́gun ni ìròyìn gbòde pé Portable tún kọ sí gbaga ọlọ́pàá lẹ́yìn tí wọ́n mu fẹ́sùn pé ó jẹ gbèsè.

Nínú fọ́nrán kan tó gba orí ayélejára ló ṣàfihàn bí Portable ṣe fo géètì ilé bọ́ sí òdì kejì láti bọ́ lọ́wọ́ àwọn ọlọ́pàá tó fẹ́ fòfin gbe é.

Àmọ́ ọwọ́ àwọn ọlọ́pàá padà tẹ̀ ẹ́, tí wọ́n sì fi tipátipá gbe sínú ọkọ̀ ọlọ́pàá.

Portable sun àhámọ́ àwọn ọlọ́pàá ní ọjọ́ Ìṣẹ́gun mọ́jú ọjọ́rú kí àwọn ọlọ́pàá tó gba béèlì rẹ̀, tó sì padà sí ilé rẹ̀.

Ní ọjọ́bọ̀ ni Portable wá fi orin síta láti ṣàlàyé ohun tó gbe dé àhámọ́ àwọn ọlọ́pàá náà.

Ìròyìn tó gbòde pé Portable kọ̀ láti san gbèsè mílíọ̀nù mẹ́rìnlá náírà owó ọkọ̀ G-Wagon SUV tó rà ní mílíọ̀nù mẹ́tàdínlọ́gbọ̀n náírà.

Nínú orin náà ni Portable ẹni tó bá fẹ́ pẹ́ láyé ló máa ń jẹ gbèsè àti pé ikú tí òun rí níwájú ló mú òun fo ẹnu ọ̀nà àbáwọlé láti sá mọ́ àwọn ọlọ́pàá lọ́wọ́.

“Ọlọ́run ló síwájú ohun gbogbo, mi ò ní kú ní kékeré, mo ma darúgbó, èmi máa fèrìgì jobì, mo ma lówó wọ 90.

“Ẹ pèmí ní aláǹtakùn, èmi a ríkú sá... èmi a ríkú yẹrí...

“Ohun a ní là ń nání, mo ríkú mo bẹ́, mo jápa, ikú ló kápá mi o, Ọlọ́run ló ṣẹ̀dá mi o.

“Wọ́n ní mo jẹ gbèsè, tó bá fẹ́ pẹ́ láyé jẹ gbèsè, jẹ wọ́n ní gbèsè, kí wọ́n jẹ ẹ́ ní gbèsè, o ma pẹ́ láyé.”

“Olówó ló máa ń jẹ gbèsè mọ́tò, mi k]o gbowó lápó, mọ́tò ni mo rà mi ò jalè...”

Ìgbà àkọ́kọ́ kọ̀ nìyí tí Portable ń ní ìfaǹfà pẹ̀lú àwọn ọlọ́pàá.

Aworan orin ti Portable gbe jade

Oríṣun àwòrán, @portablebaeby

Kì í ṣe iṣẹ́ Ọlọ́pàá ni láti bá ẹnikẹni sin gbèsè, bí wọn ṣe gbé Portable lòdì sófin - Amòfin

Aworan Portable Omo Olalomi

Oríṣun àwòrán, Instagram/Portable Omolalomi_1

Gbajumọ Amofin to fi ilu Abuja ṣe ibugbe, Pelumi Olajengbesi, ti bu ẹnu atẹ lu bawọn ọlọpaa ṣe gbe Habeeb Okikiola, Portable olorin Zazu lorii gbese mọto G-Wagon ti olorin naa jẹ.

Ọjọru ọsẹ yii ni Olajengbesi sọrọ naa loju opo Facebook rẹ.

O ni bi wọn ṣe gbe Portable ati ọna ti wọn fẹ fi gba gbese to jẹ lodi pata si ofin iṣẹ wọn ati ti orilẹ-ede Naijiria.

Gẹgẹ bi Amofin Olajengbesi ṣe wi, o ni, ‘’ o ṣe pataki lati mọ pe gbese jijẹ ki i ṣe iwa ọdaran, ijọba Naijiria paapaa jẹ gbese.

‘’ Ọna ti wọn gba mu Portable yii n tọka si ipo aidaa ti iṣẹ ọlọpaa wa lorilẹ-ede Naijiria ni.

Aworan Amofin Pelumi Olajengbesi

Oríṣun àwòrán, Pelumi Olajengbesi @Facebook

Àkọlé àwòrán, Amofin Pelumi Olajengbesi

‘’Gbèsè jíjẹ kì í ṣe ìwà ọ̀daràn, ọlọ́pàá kò sì láṣẹ láti bá onígbèsè gbowó pẹ̀lú ipá’’

‘’Ọpọ igba ni ile-ẹjọ ti sọ pe kawọn ọlọpaa jawọ ninu ọrọ to ba jẹ mọ gbese jijẹ laarin araalu. Afi ti ẹsun jibiti ba wa nibẹ nikan ni wọn le da si i.

‘’Abala kejilelọgbọn, ipin keji (Section 32) (2) ofin ọlọpaa ilẹ wa ti wọn ṣe ni 2020, ṣalaye pe ọlọpaa ko gbọdọ mu eeyan lori ẹsun to jẹ mọ adehun.’’

Amofin Olajengbesi tẹsiwaju pe Portable le ya onijangbọn loootọ, ṣugbọn bi wọn ṣe gbe e ju satimọle lori ọrọ gbese ko yẹ.

O ni iwa tawọn ọlọpaa Naijiria n hu yii n fi wọn wọlẹ lawujọ ọlọpaa agbaye ni.

Bo tilẹ jẹ pe Were olorin ti pada ri eto beeli rẹ ṣe, sibẹ, o lo awọn asiko kan lọdọ awọn ọlọpaa lori ọrọ naa.

Ẹ o ranti pe asanku owo G-Wagon ti Portable ra, eyi ti i ṣe miliọnu mẹtala naira lo di wahala.

To fi dohun tawọn ọlọpaa waa fagidi gbe e ju si mọto nigba tolorin naa fẹẹ fọgbọn sa mọ wọn lọwọ lọjọ Iṣẹgun ọsẹ yii.

Atẹjade ti Olajengbesi fisita

Oríṣun àwòrán, Pelumi Olajengbesi/Facebook