Èsì àyẹ̀wó òkú Mohbad jáde, dókítà jẹ́rìí nílé ẹjọ́

Mohbad

Oríṣun àwòrán, INSTAGRAM

Àwọn onímọ̀ nípa àyẹ̀wò òkú tí wọ́n ń ṣàyẹ̀wò òkú gbajúmọ̀ olórin tàkasúfèé nnì, Ilerioluwa Aloba tí ọ̀pọ̀ mọ̀ sí Mohbad ní èsì àyẹ̀wò náà ti jáde.

Níbi ìgbẹ́jọ́ tó wáyé nílé ẹjọ́ lọ́jọ́rú, ọjọ́ Kẹẹ̀dógún, oṣù Karùn-ún, ọdún 2024 ni dókítà tó ṣe àyẹ̀wò òkú náà ti wá sọ ohun tí èsì àyẹ̀wò náà wí.

Nínú fídíò kan tó gba orí ayélujára tó ṣàfihàn ibi tí agbẹjọ́rò Waha Shittu ti ń bá àwọn akọ̀ròyìn sọ̀rọ̀ lẹ́yìn ìgbẹ́jọ́ náà ní àwọn tó ṣe àyẹ̀wò òkú náà ní òkú Mohbad ti jẹrà púpọ̀ kí àwọn tó ṣe àyẹ̀wò òk;u rẹ̀ nítorí náà àwọn kò lè fìdí ohun tó ṣekúpa á múlẹ̀.

“Kò rọrùn fún wa láti mọ ohun tó ṣekúpa Mohbad nítorí òkú rẹ̀ ti jẹrà púpọ̀ kí a tó ṣe àyẹ̀wò láti mọ ohun tó pa á.

“Ní kúkurú a ò lè sọ pé nǹkan báyìí ló pa Mohbad.”

Agbẹjọ́rò náà ní dókítà ọ̀hún sọ pé àwọn kò lè sọ ní pàtó pé nǹkan báyìí ló pa Mohbad àmọ́ ó ní ó ṣeéṣe kó jẹ́ pé àwọn ogun tó lò kó tó jáde láyé wà lára ohun tó ṣokùnfà ikú rẹ̀.

Shittu ní dókítà náà tún fi kún ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé òun kò mọ̀ bóyá àwọn oògun náà ló fa ikú rẹ̀ nítorí ìwádìí àwọn kò fìdí rẹ̀ múlẹ̀.

Àwọn ẹ̀rí míì tún jẹyọ nílé ẹjọ́

Àgbà agbẹjọ́rò náà tẹ̀síwájú pé àwọn ọ̀rọ̀ míì tún jẹyọ ní ilé ẹjọ́ lásìkò tí ìgbẹ́jọ́ náà wáyé pàápàá lórí ìjà tó wáyé láàárín Mohbad àti ìyàwò rẹ̀ kó tó jáde láyé.

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Bákan náà ni wọ́n gbé àwọn ìjà tó wáyé láàárín Sam Larry àtàwọn míì pẹ̀lú Mohbad síwájú ilé ẹjọ́ nígbà tí ẹlẹ́rìí kan ń sọ̀rọ̀.

“Ohun tó ṣe patàkì jùlọ lásìkò yìí ni èsì àyẹ̀wò òkú Mohbad tí dókítà gbé wá sílé ẹjọ́ tí a sì ti mú ọjọ́ láti fi fọ̀rọ̀ wá dókítà lẹ́nu wò.”

Ó ní ó dìgbà tí àwọn bá bèèrè àwọn ìbéèrè tí àwọn ní fún dókítà náà, tó sì fún àwọn ní èsì tí àwọn ń fẹ́ ni àwọn tó máa mọ ìgbésẹ̀ tó kàn.

Ó rọ àwọn ọmọ Nàìjíríà láti ṣe sùúrù pẹ̀lú èsì tí dókítà náà sọ nítorí àwọn kò ì tíì rí ìwé èsì àyẹ̀wò náà gbà láti mọ ohun tó dá lé lórí gangan.

“Ilé ẹjọ́ ti ní ka kọ̀wé láti fi bèèrè fún ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ohun tó wà nínú èsì àyẹ̀wò náà, èmi gan kò ì tíì ri, nígbà tí gbogbo wa bá ri ni a máa mọ ohun tó kàn.”

Ó fi kún ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé tí àwọn bá ti rí ìwé náà ni àwọn máa mọ ìdí tí èsì àyẹ̀wò rẹ̀ ṣe ní àwọn kò lè mọ ohun tó ṣokùnfà ikú rẹ̀.

Ó ní gbogbo àwọn agbẹjọ́rò tó wà nílé ẹjọ́ náà ló ń ṣiṣẹ́ láti ri pé àwọn wagbò ìṣẹ̀lẹ̀ lórí ìkú Mohbad dé ìsàlẹ̀ kòkò, tí àwọn k]o sì ní kọ àárẹ̀ ọkàn títí ìgbẹ́jọ́ náà ma fi parí.

“Tí a kò bá wa rí nǹkan tí à ń fẹ́, a ò ní sinmi.”

Ẹ ó rántí pé ní ọjọ́ Kejìlá, oṣù Kẹsàn-án, ọdún 2023 ni Mohbad jáde láyé tí ikú rẹ̀ sì fa awuyewuye lórí ayélujára.

Ní ọjọ́ kejì tí Mohbad kú ni bàbá rẹ̀ Joseph Aloba ní kí wọ́n lọ sín ṣùgbọ́n iléeṣẹ́ ọlọ́pàá pàṣẹ pé kí wọ́n lọ hú òkú rẹ̀ nígbà tí àwọn èèyàn bẹ̀rẹ̀ sí ní sọ pé ejò lọ́wọ́ nínú, pé ikú rẹ̀ kò gbọdọ̀ lọ lásán láì ṣe wí pé wọ́n ṣe ìwádìí náà bó ṣe yẹ.

Bákan náà ni iléeṣẹ́ ọlọ̀pàá fòfin gbé àwọn afurasí mélòó kan lórí ikú náà, tí ìwádìí sì ń tẹ̀sìwájú.