Kí ló dé tí àjọ Ayánilówó Àgbáyé (IMF) ń tojú bọ ọrọ̀ ajé Naijiria?

Oríṣun àwòrán, IMF
Laipẹ yii ni ajọ Ayanilowo Agbaye, International Monetary Fund (IMF), kede pe o ṣe pataki ki ijọba Naijiria ṣe eto iṣuna ti yoo jẹ ki wọn le san owo oṣu oṣiṣẹ to kere ju ti awọn oṣiṣẹ n beere.
IMF sọ pe awọn gba ijọba Naijiria lamọran yii nitori owo oṣu ti wọn n sọrọ rẹ yii ju apapọ owo eto iṣuna ọdun 2024 lọ.
Igba akọkọ kọ niyi ti ajọ ayanilowo agbaye naa yoo gba orilẹ-ede yii nimọran lori bi wọn ṣe ro pe o yẹ ki Naijiria nawo rẹ, tabi dari ẹka ọrọ aje.
Apẹẹrẹ bi wọn ṣe n da si ọrọ Naijiria ni imọran ti wọn gba Naijiria laipẹ yii, pe kijọba yee sanwo iranwọ lori ina, eyi ti ijọba si gba.
Ijọba fowo kun owo ina fawọn eeyan ti nnkan ko tiẹ ṣenuure fun paapaa ni Naijiria.
Bakan naa ni IMF ti ni kijọba Naijiria yee san owo iranwọ ori epo rọbi tipẹ, eyi ti Aarẹ Bọla Tinubu gba to si yọ sọbsidi bo ṣe dori aleefa.
Ọpọ igba ni awọn eeyan Naijiria n kerora lori awọn amọran IMF yii.
Wọn ni ohun to n ni awọn lara ni wọn n sọ funjọba pe ko ṣe.
Eyi lo fa a tawọn eeyan fi n beere pe ki lo da IMF ati Naijiria pọ gan-an?
Ati pe ki lo de ti ajọ naa sọ ara rẹ di Iya Naijiria ati alagbatọ, to ba dibi ọrọ aje orilẹ-ede wa.
Ibeere yii lo jẹ ka tọ Ọjọgbọn Kabiru Isa Dandago, lọ. Onimọ nipa ọrọ aje to n kọ awọn akẹkọọ ni Yunifasiti Bayero, ni Kano ni.
Eyi lawọn idahun to fi si ibeere yii atawọn mi-in.
Kí ni iṣẹ́ IMF lágbàáyé?
Oṣu keje ọdun 1944 ni wọn da ajọ IMF silẹ lasiko ipade ajọ Iṣọkan awọn orilẹ-ede ni UK. ‘Bretton Woods Conference’ ni wọn pe ipade naa.
Olu ileeṣẹ IMF yii wa ni Washington, USA. Aadọwa orilẹ-ede (190) ni awọn ọmọ ẹgbẹ rẹ.
Nipa ojuṣe IMF, Ọjọgbọn Kabiru Isa Dandago ṣalaye pe,
" Ojuṣe IMF ni lati gba awọn orilẹ-ede nimọran nipa ọrọ aje wọn ki wọn si ya wọn lowo nibi to ba yẹ fun idagbasoke awọn ẹka to nilo iranwọ.
‘’Awọn olowo aye ti wọn lagbara wa ni ikawọ IMF.
‘’Owo naa wa fun iranlọwọ awọn orilẹ-ede to ṣẹṣẹ n gunke agba.
‘’Wọn le ya wọn lati maa san an diẹdiẹ, tabi ki wọn gbe e gba ọna iranwọ ta a n pe ni grant.’’
Àjọṣepọ̀ Naijiria àti IMF
Gẹgẹ bi Ọjọgbọn Dandago ṣe ṣalaye, Naijiria naa wa lara awọn ọmọ ẹgbẹ IMF, o si lẹtọọ lati beere iranwọ lọwọ ajọ naa boya lọna ẹyawo abi iranwọ.
O ni Naijiria wa lara awọn orilẹ-ede ti wọn maa n sanwo to yẹ lati jẹ ọmọ ẹgbẹ, fun idi eyi, bi orilẹ-ede yii ba ni iṣoro kan, o le tọ IMF lọ fun ẹyawo.
Ọjọgbọn Dandago sọ pe ofin wa nipa owo ti IMF n ya awọn orilẹ-ede, ilu ti ko ba ti kogo awọn ofin naa ja ko ni i gba ẹyawo kankan.
" Ẹtọọ Naijiria ni lati beere ẹyawo lọwọ IMF, ẹtọọ IMF ni lati kọ Naijiria lọna ti yoo gba sanwo naa pada deede lai si wahala kankan.
‘’Iyẹn lo fi jẹ pe ti wọn ba ya wa lowo, tabi ki wọn too ya wa rara, wọn yoo gba wa nimọran lori ohun ti a le ṣe ti a ko fi ni i maa yawo,"
"Bi orilẹ-ede ba gba lati yawo naa ti wọn o si ri i san, IMF maa fun wọn nimọran lorii bi wọn ṣe le san an.
" Ti ajọ IMF ba ya Naijiria lowo lati ṣe ọna, papakọ ofurufu abi afara, ti Naijiria ko waa ri owo naa san pada, IMF yoo ṣe awọn ofin kan fun wọn lori ọna ti wọn le gba ri gbese naa san.
‘’IMF le ni ki wọn din oṣiṣẹ ku ni ida ogoji, eyi ti yoo jẹ ki wọn le sanwo awọn oṣiṣẹ to ba ṣẹku, yoo si jẹ ki gbese dinku lọrun wọn.’’
Onimọ nipa ọrọ aje naa ṣalaye pe Naijiria n gba amọran IMF ki wọn le maa ri owo ya lọwọ rẹ lọ ni.
O ni ki i ṣe pe ajọ naa n toju bọ ọrọ Naijiria, imọran ti yoo jẹ ki Naijiria le san gbese rẹ ni wọn n fun un.
‘’Naijiria ko le maa gbowo lọwọ IMF ki wọn waa reti pe ajọ naa yoo dakẹ, nigba ti Naijiria ko ba ti i san gbese to jẹ’’.
Bẹẹ ni Ọjọgbọn Dandago wi.
Àwọn aráàlú tó ń fapájánú kọ́ ni IMF ń fún nímọ̀ràn, ìjọba ni wọ́n ń bá wí
Nipa ti awọn ọmọ Naijiria ti wọn n fapajanu lori imọran IMF, Ọjọgbọn Dandago sọ pe awọn kọ ni IMF n fun nimọran.
O ni ijọba ati awọn olori wọn ni.
‘’Wọn o ni nnkan kan lati ṣe pẹlu awọn mẹkunnu, boya wọn n kerora pe ko tẹ wọn lọrun, ko kan IMF.
‘’Awọn mẹkunnu naa yoo yan awọn aṣoju wọn ti wọn le ba sọrọ ti yoo gbe ohun wọn debi ti wọn fẹ ni.
‘’Alajọsọ ni ijọba ati IMF, ajọsẹpọ wọn gun rege gidi.’’
Ọnà àbáyọ fún àwọn ìjọba ilẹ̀ Adúláwọ̀
Bi awọn orilẹ-ede Afrika ti Naijiria jẹ ọkan lara wọn ba fẹẹ bọ lọwọ yiyawo lọwọ IMF, wọn gbọdọ maa gbamọran latọwọ awọn akọṣẹmọṣẹ ni Naijiria.
Ọjọgbọn Dandago sọ pe, ‘’Amọran awa ọmọ Naijiria ta a mọ ibi ti nnkan ti n ṣe wa yoo ṣe wa lanfaani.
‘’Amọran awọn IMF ati Banki Agbaye (World Bank), ko le mu ilọsiwaju ba wa, afi ifasẹyin."
O ni okunkun ti ko toju ẹni ṣu yoo ṣoro lati rin ilẹ ibẹ. Iṣoro ti IMF ko mọ ipilẹ rẹ ko le lojuutu lati ọwọ wọn bo ṣe sọ.
" Irori ọdọ tiwọn ni wọn n gbe wa sibi, wọn o mọ iṣoro tiwa.
Bi wọn ba le gba imọran awarawa ta a wa nibi, awa ti nnkan ko dẹrun fun, yoo mu idagbasoke wa fun wa bo ṣe yẹ’’
Bẹẹ ni Ọjọgbọn Dandago pari alaye naa.













