Àwọn ọmọ ìta wọ̀já ìjà l‘Osogbo, ẹ̀mí alágbe kan bá ìṣẹ̀lẹ̀ náà lọ

Awọn eeyan to duro

Aṣita ibọn awọn janduku ti sọ ọkunrin alagbe kan di ero ọrun ojiji bayii, laduugbo Gbaemu,Oṣogbo, nipinlẹ Ọṣun.

Ọjọ Iṣẹgun, ọjọ kẹrinla oṣu karun-un ọdun 2024 yii ni iṣẹlẹ naa waye.

Awọn olugbe adugbo naa ṣalaye fawọn akọrin pe awọn janduku lati agbegbe Asoje ati Ẹgbatẹdo, niluu Oṣogbo ni wọn doju ija kọ ara wọn.

Wọn ni baba olowo kan lo ra ilé si Gbaemu, awọn igun ọmọ-ita kan si fẹẹ gba owo lọwọ rẹ bi iṣe wọn.

Wọn fi kun un pe ija agba ti wa nilẹ tẹlẹ laarin awọn ọmọ-ita naa, ko too dohun ti wọn gbe ibọn wọlu, ti wọn si pa alagbe ti ọrọ o kan.

‘’Ọjọ́ Àìkú ni àwọn ọmọ-ìta náà ti kọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀ sí í fa wàhálà’’

Awọn obinrin ọlọja kan ti wọn mọ nipa iṣẹlẹ yii ṣe ṣalaye, wọn ni ọjọ Aiku ni wahala ti n rugbo bọ.

Wọn ni awọn ọmọ-ita lati Asoje taku sibi ile tuntun ti baba olowo naa ṣẹṣẹ ra, wọn n ṣọ ọ gẹgẹ bi iṣẹ to gbe fun wọn.

‘’Ọjọ Sannde yẹn ni wọn kọkọ doju ija kọ ọmọ-ita kan to wa sibẹ lati Egbatedo. Iyẹn fẹẹ waa gbowo ni.

‘’Awọn janduku Asoje yẹn to ọgbọn (30), wọn ko gbogbo nnkan ija lọwọ, wọn si ri i daju pe ẹjẹ bo ọmọ-ita to wa lati Egbatedo lati waa gbowo lọwọ ẹni to ra ile naa.

‘’Janduku Ẹgbatẹdo yẹn naa pada wa pẹlu awọn eeyan rẹ lati ba wọn ja,ṣugbọn ko ba wọn mọ. Gbogbo wọn ti lọ.

‘’Gbogbo adugbo ni wọn bẹrẹ si i da laamu latigba yẹn, ọkan wa o balẹ lati ọjọ Aiku yẹn.’’

Bẹẹ ni awọn ontaja ti wọn ko darukọ wọn naa ṣalaye.

Wọn tẹsiwaju pe ija naa lo wọ ọjọ Iṣẹgun, ti wọn yinbọn to ṣe kongẹ ọkan ninu awọn alagbe agbegbe naa.

Kí ni iléeṣẹ́ ọlọ́pàá Osun wí?

Alukoro ọlọpaa ipinlẹ Osun, Yemisi Opatola, fidi iṣẹlẹ yii mulẹ.

O ni ẹka ọlọpaa to n gbogun ti ẹgbẹ okunkun ṣi wa lawọn adugbo naa ti wọn n ṣọ ibẹ titi dasiko yii.

Opatola sọ pe awọn n ṣiṣẹ lori iṣẹlẹ naa, gbogbo awọn janduku to kopa ninu ẹ lawọn yoo mu patapata.