Ìlú kan rèé tí wọ́n ti máa ń rí àwọn èèyàn tó bọ́ lọ́wọ́ ìkọlù ààrá mọ́lẹ̀ láàyè

Àwọn tórí kóyọ tí wọ́n rì mọ́lẹ̀ fún wákàtí méjì

Oríṣun àwòrán, Abas Muktar

Báyìí là ń ṣe nílé wa, èèwọ̀ ni ní ilẹ̀ ibòmíràn.

Ní orílẹ̀ èdè Ethiopia, èèyàn méjìlá ni wọ́n rì mọ́lẹ̀ láàyè títí dé ibi ọrùn wọn.

Èyí kò ṣẹ̀yìn bí àwọn èèyàn náà ṣe móríbọ́ lọ́wọ́ ikú nígbà tí àrá san wọn ṣùgbọ́n tí wọn kò kú.

Wákàtí méjì gbáko ni wọ́n fi sin àwọn èèyàn náà sínú ilẹ̀ ní ìbámu pẹ̀lú àṣà orílẹ̀ èdè náà lẹ́yìn tí àrá bá ṣọṣẹ́.

Ní ọjọ́ Àìkú ni ìṣẹ̀lẹ̀ náà wáyé ní agbègbè Melka Bello, ìlú kan tó wà ní kìlómítà 450 sí Addis Ababa tó jẹ́ olú ìlú orílẹ̀ èdè Ethiopia.

Lára àwọn èèyàn tó móríbọ́ lọ́wọ́ ikú, Nesro Abdi sọ fún BBC pé kìí ṣe pé òjò ńlá ló rọ̀ àmọ́ àrá san pa àgùtàn kan tó wà lẹ́nu ọ̀nà ilé tí gbogbo àwọn wà.

"Ààrá sísán ni wọ́n rí bí àmúwá Ọlọ́run, tí wọ́n sì máa ń ṣàjọyọ̀ rẹ̀ tó bá wáyé láti má fi ṣẹ Ọlọ́run"

Ó ní gbogbo àwọn ṣubú lulẹ̀ lẹ́yìn tí àrá náà sán tí àwọn sì bẹ̀rẹ̀ sí ní gbọ̀n.

Ó ṣàlàyé pé àwọn ará àdúgbò tó gbọ́ igbe àwọn ló sáré láti ran àwọn lọ́wọ́.

“Wọ́n sáré da mílìkì sí wa lára, wọ́n gbọ́ ilẹ̀, wọ́n sin wá sínú rẹ̀ dé ibi ọrùn wa,” Nesro sọ.

Ní agbègbè Oromia ní Ethiopia, ìgbàgbọ́ wọn ni pé wọ́n gbọ́dọ̀ sin èèyàn tó bá móríbọ́ lọ́wọ́ ìkọlù àrá sínú ilẹ̀ fún ìgbà díẹ̀, kí wọ́n sì fún wọn ní mílìkì mu tàbí kí wọ́n dà á sí wọn lára kí ìlera wọn lè bọ̀ sípò padà.

Àrá sísán ni wọ́n rí bí àmúwá Ọlọ́run, tí wọ́n sì máa ń ṣàjọyọ̀ rẹ̀ tó bá wáyé láti má fi ṣẹ Ọlọ́run.

Nesro ní òun kò lè gbé ẹsẹ̀ òun nígbà tí àrá náà sán, àwọn èèyàn ló gbé òun tí wọ́n sì sin òun àmọ́ àláfíà òun bọ̀ sípò nígbà tí wọ́n fi máa gbé òun jáde kúrò nínú ilẹ̀.

“Gbogbo àwọn yòókù ni ìlera wọn náà ti pé báyìí, mò ń rìn dáadáa báyìí.”

Oníwàdìí nípa ìmọ̀ àyíká ní ilé ẹ̀kọ́ gíga fásitì Haramaya, Haftu Birhane ní ìwà ríri èèyàn mọ́lẹ̀ yìí kò ṣè é fídì rẹ̀ múlẹ̀ pẹ̀lú ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì.

Ó ní ilé ìwòsàn ló yẹ kí wọ́n gbé àwọn ẹnikẹ́ni tó bá móríbọ́ lọ́wọ́ ìkọlù àrá lọ lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà bá wáyé.