Àwọn ajínigbé pa dẹrẹba, ṣe èrò mẹ́rin lése, jí èèyàn mẹ́ta gbé lọ́nà Ibadan sí Ijebu-Ode

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Nnkan bii aago mẹfa irọlẹ ọjọ Aiku, ọjọ kejila oṣu karun-un ọdun 2024 yii ni awọn agbebọn da awọn arinrinjo lọna l’Abule Longẹ, loju ọna Ibadan si Ijẹbu-Ode.
Wọn pa dẹrẹba kan wọn si ji ọkunrin mẹta gbe lọ.
Itosi ile-ẹkọ Cocoa Research Institute of Nigerian (CRIN) to wa n’Idi Ayunre, n’Ibadan, ipinlẹ Ọyọ ni wọn ti dena de ọkọ mẹta ti i ṣe Toyota Corolla, Toyota Sienna ati Mazda 6.
Báwo lo ṣe ṣẹlẹ̀ gan-an?
Ẹka iroyin ayelujara Tribune fidi iṣẹlẹ yii mulẹ, pe ibọn ni awọn agbebọn naa kọkọ bẹrẹ si i da bolẹ bi wọn ṣe ri awọn ọkọ to n bọ.
Awakọ to n wa Mazda ti nọmba idanimọ ẹ jẹ Lagos AKD 08 JB, ni ibọn naa kọkọ ba, ẹsẹkẹsẹ lo si ku.
Wọn tun yinbọn fun awọn obinrin meji ati ọkunrin meji mi-in ti wọn wa ninu ọkọ Sienna. Eyi lo fi jẹ eeyan mẹrin lo fara pa.
Ọgangan aya ni wọn ti yinbọn fun ọkan ninu awọn obinrin meji naa bi a ṣe gbọ, nigba ti wọn yin ibọn si ikeji lapa.
Lẹyin eyi ni wọn ko ọkunrin mẹta wọgbo lọ ninu awọn ti wọn wa ninu ọkọ ayọkẹlẹ Corolla.
Nigba ti wọn n fidi orukọ awakọ to doloogbe naa mulẹ, Abiọdun Emmanuel Omotoye ni wọn pe e.
Awọn mẹta ti wọn gbe sa lọ si ni Gbenga, Ṣẹgun ati Emma.
Ibi kan ti wọn pe ni Olunde ni awọn ọkunrin mẹta ti wọn ji gbe yii ti n bọ ti wọn fi ko sọwọ awọn ajinigbe agbebọn.
Ko din ni miliọnu lọna marundinlogoji naira, (35m) ti awọn ajinigbe naa n beere bayii bii owo itusilẹ lati ọwọ awọn ẹbi wọn.
Lẹ́yìn ìkọlù náà ni àwọn ará abúlé pe ọlọ́pàá
Ere buruku ni awọn agbebọn naa ba wọgbo lọ lẹyin ikọlu ọhun bi a ṣe gbọ.
Ati pe ero wọn ni pe awọn ti wọn yinbọn fun naa ti dagbere faye ni wọn ṣe fi wọn silẹ ti wọn wa ọkọ wọn wọgbọ lọ.
Ileewosan ti wọn kọkọ gbe awọn eeyan ti ibọn ba naa lọ ko tilẹ gba wọn, wọn dari wọn sibo mi-in ni.
Lẹyin ti gbogbo rogbodiyan naa rọlẹ tan ni awọn ara abule too le pe ọlọpaa.
Awọn ti teṣan Idi Ayunre lo waa yọju si wọn pẹlu ikọ Operation Burst.
Nibẹ ni wọn ti ri oku awakọ Mazda to wa lori aga nibẹ, ti ẹjẹ si n jade lara rẹ gidi.
SP Adewale Osifeso, Alukoro ọlọpaa nipinlẹ Oyo, fidi iṣẹlẹ yii mulẹ.
Bẹẹ lo ni iwadii n lọ lọwọ.














