Èèyàn 1,097 làwọn agbébọn ṣekúpa lóṣù kẹrin ní Nàìjíríà – Àbọ̀ ìwádìí

Eeyan kan gbe ibọn dani

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Abọ iwadii kan ti jade to sọ pe iye awọn eeyan ti wọn ṣekupa lorilẹede Naijiria laarin oṣu kẹrin nikan pọ ju iye awọn ti wọn ṣeku pa loṣu kẹta ọdun 2024 pẹlu ida mẹrinlelọgbọn.

Eyi jẹyọ ninu abajade iwadii oloṣooṣu nipa ọrọabo eyi ti ajọ kan ti orukọ rẹ n jẹ Beacon Consulting fi sita eyi to sọ wi pe loṣu kẹrin ọdun 2024 ẹgbẹrun eeyan o le mẹtadinlaadọfa (1,097) ni awọn oniṣẹ ibi ṣekupa. Gẹgẹbi atẹjade naa ṣe sọ, eyi tun gbẹnusoke ju ti oṣu kẹta nibi ti eeyan ẹgbẹrin o le mẹrindinlogun (816) ti kagbako iku gbigbona lorilẹede Naijiria.

Ipinlẹ Borno ni o ko iye to pọju pẹlu ọọdunrun o le mẹtadinlaadọrin (367) eeyan ti awọn oniṣẹibi ẹda ṣekupa loṣu kẹrin ti iwadii naa n gbe yẹwo. Zamfara lo pẹlu pẹlu iku eeyan mẹtalelaadọfa(113) ti ipinlẹ Kano si wa ni ipo kẹta pẹlu iku eeyan mẹrinlelọgọfa.

Ikọlu awọn agbebọn Boko Haram ni lemọlemọ ni ipinlẹ Borno lo mu ki ipinlẹ naa o wa ni iwaju loriatẹ awọn ipinlẹ ti awọn agbebọn ti ṣekupa eeyan lorilẹede Naijiria loṣu kẹrin.bakan naa ni awọn agbebọn Boko Haram wnyi a tun maa gbin ado oloro si inu ilẹ lawọn oju popo gbogbo ni ipinlẹ naa eleyi to n pa kun iye ẹmi to n ṣofo nibẹ.

Aworan abọ iwadii naa

Oríṣun àwòrán, Beacon Consulting

‘O le ni ọọdunrun eyan to ko sọwọ awọn ajinigbe pawo loṣu kẹrin’

Ni ti ijinigbe pawo loṣu kẹrin kan naa, ipinlẹ Zamfara lo wa niwaju, pẹlu eeyan mejilelọgọfa tawọn agbebọn ti jigbe nibẹ, ipinlẹ Borno lo tẹle wọn nibi ti ogoji eeyan ti bọ sọwọ awọn ajinigbe

Ipinlẹ Delta lo wa ni ipo kẹta atẹ awọn ajinigbe fun oṣu kẹrin. Eeyan mọkandinlọgbọn lawọn ajinigbepawo ji gbe nibẹ loṣu kẹrin ọdun 2024 gẹgẹbi iwadii naa ṣe sọ.

Ipinlẹ Zamfara kun awọn ipinlẹ ti gulegule ijinigbepawo ti gogo si julọ lorilẹede Naijiria.

Awọn ibọn meji ati ọta wọn

Oríṣun àwòrán, @KDSG_MISHA

Awọn agbebọn wọnyii a maa kọlu awọn ileto, nibi ti wọn a ti maa ji dukia ati eniyan lati gba owo itusilẹ.

Bi o tilẹ jẹ wipe ijọba orilẹede Naijiria ni awọn n sa gbogbo ipa awọn lati dẹkun wahala ọrọ abo to mẹhẹ lorilẹede Naijiria, sibẹ ipenija yii ṣi n rinlẹ bi ọwara ojo eyi to si n ja si ọpọ ipadanu ẹmi kaakiri, paapaajulọ lawọn ileto lẹkun iwọ oorun ariwa orilẹede Naijiria.

Abajade iwadi yii fihan pe ọọdunrun o le mọkanla eeyan lo kagbako awọn ajinigbe lorilẹede Naijiria loṣu kẹrin nikan, ti ojilelọọdunrun ati meji miran si tun farapa.

Amọṣa o, abọ iwadii naa fi kun un pe ọwọja ikọlu awọn agbebọn atawọn ajinigbe pawo lawọn ileto kaakiri ti walẹ.