'Ojoojúmọ́ ni wọ́n ń ja àwọn èèyàn lólè tàbí pa wọn, mò ń gbàdúrà lọ́sàn-án àti lóru fún ààbò'
- Author, Ayanda Charlie & Tamasin Ford
- Role, BBC Africa Eye, Johannesburg & London
Báwọn ènìyàn orílẹ̀ èdè South Africa ṣe ń múra fún ètò ìdìbò gbogbogbò tí yóò wáyé nínú oṣù yìí, ìrònú tó gba ọkàn wọn kò sẹ̀yìn àwọn ìwà ìpáǹle tó ń wáyé ní orílẹ̀ èdè náà, tí ọ̀pọ̀ àwọn olóṣèlú sì ń ṣe ìlérí láti fòpin sí ìwà náà.
Bí ìwà ìpànìyàn ṣe ń lékún ní orílẹ̀ èdè náà láti bíi ogún ọdún báyìí, BBC Africa Eye bá àwọn ìlú tí wọ́n ń jà fúnra wọn sọ̀rọ̀.
N ṣe ni ariwo fèrè gbalẹ̀ bí àwọn èèyàn tí wọ́n wọ aṣọ olómi ọsàn ṣe bẹ̀rẹ̀ sí ní sáré.
“Ọlúwa o,” ni igbe tí èèyàn kan ké nígbà tí wọ́n yìnbọn fún ọlọ́pàá kan, tó sì ṣubú lulẹ̀.
Alẹ́ ọjọ́ Ẹtì ni iṣẹlẹ naa waye ní Diepsloot, ìlú kan lẹ́bàá Johannesburg.
Abel Rapelego tó jẹ́ ẹni ọdún mọ́kànlélógójì, tó jẹ́ aṣáájú ikọ̀ kan ti wọ́n fa ara wọn kalẹ̀ láti máa ṣọ́ àdúgbò náà, tí ilẹ̀ bá ṣú salaye isẹlẹ yii fún BBC.
“Nǹkan tó máa ń ṣẹlẹ̀ dáadáa níbi ni, “
Fèrè tó ń dún lára ọkọ̀ àwọn ọlọ́pàá mú kí àwọn èrò tó ń péjọ túká.
Rapelego sọ fún àwọn ènìyàn rẹ̀ pé kí wọ́n túká. “Ẹ jẹ́ ka fún àwọn agbófinró láàyè láti ṣe iṣẹ́ wọn.”
Wọ́n gbé ọlọ́pàá náà, Tom Mashele, ẹni ọdún méjìdínlógójì, lọ sí ilé ìwòsàn fún ìtọ́jú àmọ́ ó jáde láyé lẹ́yìn ọ̀sẹ̀ díẹ̀ tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà wáyé.
Wọ́n kò nawọ́ gán ẹnikẹ́ni fún ikú rẹ̀.

Àwọn èèyàn dúdú South Africa ni wọ́n ń pa, táwọn tó dìde ìrànwọ́ yìí sì ń fi ẹ̀mí ara wéwu

Orílẹ̀ èdè South Africa jẹ́ ọ̀kan lára àwọn orílẹ̀ èdè tí ìṣẹ̀lẹ̀ ìpànìyàn ti wọ́pọ̀ ní àgbáyé gẹ́gẹ́ bí ẹ̀ka tó ń rí sí lílo egbògi olóró àti ìwà ipa àjọ ìṣọ̀kan àgbáyé ṣe fìdí rẹ̀ múlẹ̀.
Ènìyàn tó lé ní 27,000 ni wọ́n ṣekúpa ní ọdún tó kọjá nìkan, èyí tó túmọ̀ sí pé èèyàn 45 nínú 100,000 èèyàn ni wọ́n pa.
Èyí jìnà púpọ̀ tí a bá fi wé Amẹ́ríkà níbi ti wọ́n ti pa èèyàn mẹ́fà nínú èèyàn 100,000.
Fún ìdí èyí, Rapelego ní ọ̀nà tí àwọn le fi dá ààbò bo àwọn ẹbí àwọn ni kí àwọn kan dìde láti máa sọ́ ìlú fúnra wọn.
Kódà o ni bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ń fi ẹ̀mí àwọn wéwu ni nítorí ọwọ́ àwọn ọ̀daràn ni ìlú Diepsloot wà.
Àwọn ikọ̀ náà ń ṣiṣẹ́ pẹ̀lú àwọn ọlọ́pàá to wa fun aarin ilu municipal.
Àwọn tí wọ́n ń ṣe iṣẹ́ yìí kò gbowó, bẹ́ẹ̀ ni wọn kìí gbé ìbọn nítorí òfin kò fàyè rẹ̀ gbà wọ́n àmọ́ wọ́n ní sjambok, tí a lè fi wé kòbókò.
“A máa ń dá àwọn èèyàn dúró láti ṣàyẹ̀wò wọn, ẹni ta bá fura sí pé ọ̀daràn ni tàbí tí kò bá dáwa lóhùn ni a máa ń fi sjambok nà. Rapelego sọ.
Àwọn ẹgbẹ́ tí wọ́n kó ara wọn jọ yìí kò ní àṣẹ látọ̀dọ̀ ìjọba láti máà ṣe àyẹ̀wò àwọn ènìyàn síbẹ̀ wọ́n máa ń lọ káàkiri àdúgbò láti fọ̀rọ̀ wá àwọn ènìyàn tó bá pẹ́ níta lẹ́nu wò.
Bí wọ́n ṣe ń kọjá lára ṣọ́ọ̀bù kan ni ẹni tó ni ilé ìtajà náà ní àwọn kan ṣẹ̀ṣẹ̀ wá ja òun lólè ni, wọ́n sáré tẹ̀lé ọkùnrin kan tó ń sálọ láti wá owó àti fóònù ẹni tí wọ́n jà lólè.
Wọ́n fi sjambok lùú àma kò sí ẹ̀rí pé ó jalè láti hù ìwà tí kò tọ́ kankan, wọ́n jù ú sílẹ̀ kó máa bá tirẹ̀ lọ.
Nígbà tí a bí Rapelego pé ṣé ó ní àṣẹ láti hu ìwà tí wọ́n hùu yìí, ó ní àwọn ni àwọn ni Diepsloot àti pé tí àwọn kò bá ṣe àmójútó Diepsloot kò sí ẹni tó máa bá àwọn mójúto.
Ìwádìí fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé àwọn èèyàn dúdú South Africa ni àwọn tí wọ́n ń ṣekúpa àti pé àwọn tó dìde ìrànwọ́ yìí náà ń fi ẹ̀mí ara wéwu.
Ní ọdún méjì sẹ́yìn, wọ́n yìnbọn pa Alpha Rikhotso, ẹni ọdún mọ́kànlélógún lásìkò tó ń ṣọ́ àwọn èèyàn ìlú rẹ̀.
Bàbá rẹ̀, David Rikotso ní bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé òun ti gbà fún Ọlọ́run síbẹ̀ ikú rẹ̀ ṣì dá ọgbẹ́ sí òun lọ́kàn.
“Ó ń gbìyànjú láti dá ààbò bo ara rẹ̀, ẹ̀mí mi àti gbogbo àwọn èèyàn tó kù. Ó ń gbógun toko ìwà ọ̀daràn.”

"Ojoojúmọ́ ni wọ́n ń ja àwọn èèyàn lólè tàbí pa wọn, mò ń gbàdúrà lọ́sàn-án àti lóru fún ààbò ikọ̀ tó ń ṣọ́ ìlú torí kò sí òfin kankan ní ibí yìí”
Ọmọ rẹ̀ ló kọ́kọ́ jáde nígbà tí wọ́n fọn fèrè pé ìwà ọ̀daràn kan ti ń wáyé, ó gbìyànjú láti mú …ọ̀daràn náà àmọ́ wọ́n yìnbọn fun lápá.
Kò ye ọ̀gbẹ́ ìbọn náà. Wọn kò rí ẹnikẹ́ni mú fún ikú rẹ̀ gẹ́gẹ́ bíi ti ọlọ́pàá náà.
“Ojoojúmọ́ ni wọ́n ń ja àwọn èèyàn lólè.
Ojoojúmọ́ ni àwọn èèyàn ń kú. Mo máa ń gbàdúrà lọ́sàn-án àti lóru pé kí ààbò máa wà lórí àwọn ikọ̀ tó ń ṣọ́ ìlú yìí. Kò sí òfin kankan ní ibí yìí,”
Rikhotso sọ BBC Africa Eye.
Ipa tí àwọn ìwà ọ̀daràn yìí ń ní lórí ètò ọrọ̀ ajé kò kéré rárá.
Ilé ìfowópamọ́ àgbáyé ní iye tó ń lọ sí ìwà ipá tó ń wáyé ní South Africa tó $40bn (£32bn) ní ọdún kan – èyí tó tó ìdá mẹ́wàá owó tí wọ́n ń pa lọ́dún.
Bákan náà ni ìwà ẹlẹ́yàmẹ̀yà, tí ọ̀pọ̀ mọ̀ sí apartheid, tí wọ́n ti kásẹ̀ rẹ̀ nílẹ̀ láti ọgbọ̀n ọdún sẹ́yìn wà lára àwọn nǹkan tó ń fa ìwà ipá.
Ní nǹkan bíi ọgọ́ta kìlómítà sí ìwọ̀ oòrùn àríwá Diepsloot ni àwọn ikọ̀ tó fara wọn kalẹ̀ fún iṣẹ́ ìlú míì wà. Àwọn àgbẹ̀ ẹgbẹ́ tí wọ́n ń pè ní Afriforum ló dá ikọ̀ náà sílẹ̀.
Wọ́n ní àwọn ẹ̀yà Afrikana funfun ni àwọn wà fún, àti pé wọ́n ní ọmọ ẹgbẹ́ tó lé ní 300,000 káàkiri orílẹ̀ èdè wọn.
Pẹ̀lú lílo ọkọ̀ ńlá, ẹ̀rọ àlùpùpù àti ìmọ̀ ẹ̀rọ drones ni wọ́n fi máa ń wo àwọn ilé tí kò sí èèyàn níbẹ̀ àtàwọn oko wọn ní alaalẹ́. Wọ́n ní àwọn fi máa ń wá bóyá èèyàn kan jí ẹrù kó sí ibi kan tàbí láti fi ṣàwàrí ẹni tí ìrìn rẹ̀ kò bá mọ́ lọ́wọ́ alẹ́.
Ọ̀pọ̀ nínú wọn bíi Dewald van Wyngaardt ló ní ìbọn lọ́wọ́.
“Èèyàn kò lè lọ kojú ìjà ìbọn pẹ̀lú ọ̀bẹ. Mi ò ní kọ̀ láti dá ààbò bo ìdílé mi. Tí mo bá máa kojú ẹni tó lè ṣemí léṣe, mi ò ní sẹ̀ ẹ́ rọ̀ fun.”

Ìkọlù sáwọn àgbẹ̀ tó jẹ́ aláwọ̀ funfun ló ti di nǹkan tí gbogbo àgbáyé ń sọ
Àwọn àgbẹ̀ náà máa ń gba iṣẹ́ náà fún ara ní alaalẹ́, nígbà mìíràn ẹ̀mẹerin sí ẹ̀ẹmàrùn-ún ní àárín ọ̀sẹ̀ ni wọ́n máa fi ń ṣe é.
Johan de Klerk, tó jẹ́ adarí Afriforum àti farmwatch ní láti ọdún karùn-ún sẹ́yìn ni òun ti ń ṣọdẹ yìí.
“A máa ń ri dájú pé a tìlẹ̀kùn mọ́ àwọn àgùntàn wa ní alaalẹ́ láti ri dájú pé a mọ́ ohun tí à ń ṣe iṣẹ́ fún lọ́jọ́ kejì. Ó máa ṣòro láti tẹ̀síwájú báyìí nítorí a ò lè máa ṣiṣẹ́ lọ́sàn-án, ká tún máa ṣeṣẹ́ ọlọ́dẹ lóru.
Ìkọlù sáwọn àgbẹ̀ tó jẹ́ aláwọ̀ funfun ló ti di nǹkan tí gbogbo àgbáyé ń sọ.
Ní ọdún 2018, Donald Trump fi ọ̀rọ̀ kan sórí Twitter rẹ̀ pé ìjọba South Africa ń fi ipá gba ilẹ̀ lọ́wọ́ àwọn àgbẹ̀ aláwọ̀ funfun àmọ́ ọ̀rọ̀ náà kìí ṣe òótọ́. Bákan náà lọ ní wọ́n ń pa àwọn àgbẹ̀.
Ní oṣù Keje ọdún tó kọjá, Elon Musk náà kọ ọ̀rọ̀ tó fara pẹ pé ẹgbẹ́ òṣèlú Economic Freedom Fighters ń pè fún pípa àwọn èèyàn aláwọ̀ funfun South Africa.
Kò sí ẹ̀rí pé àwọn àgbẹ̀ wà nínú ewu ju àwọn èèyàn yòókù lọ.
Àwọn ẹ̀yà aláwọ̀ funfun South Africa kò ju ìdá méje àwọn èèyàn orílẹ̀ èdè náà bẹ́ẹ̀ ni wọn kò tó ìdá méjì àwọn tí wọ́n ń pa náà síbẹ̀ ẹ̀rù gba ọkàn wọn.
“Inú ìdè ni à ń gbé tí kò sì bá ojú mu. Kò yẹ kó rí báyìí. Tí nǹkankan bá le yípadà ní orílẹ̀ èdè yìí, kí ìwà ọ̀daràn di ohun ìgbàgbé pátápátá.” De Klerk sọ.
Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá gbà pé ìwà ọ̀daràn pọ̀ ní àwọn agbègbà kan àmọ́ agbẹnusọ iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ní àwọn tún ti gbé àwọn ètò kan tó lágbára dìde láti fi kojú àwọn ìwà ọ̀daràn yìí.
Ó ní èyí kún gbígba ọlọ́pàá tó lé ní 30,000 láàárín ọdún mẹ́ta tí ìsúná iléeṣẹ́ ọlọ́pàá sì ti lékún dáadáa láàárín ogún ọdún sẹ́yìn.
Nígbà tó ń sọ̀rọ̀ lórí bí àwọn ikọ̀ tó fara wọn kalẹ̀ kan tó bá BBC Africa Eye ṣe ń ṣètò wọn, agbẹnusọ ọlọ́pàá náà ní àwọn kò ní fi ààyè gba ìwà tó bá lòdì sí òfin àti pé ẹni tó bá ṣe ìdájọ́ lọ́wọ́ ara wọn ni wọ́n máa fojú winá òfin.
Ẹ̀wẹ̀, èyí le má kà á àwọn èèyàn ọ̀hún lọ́wọ́ kò tí ìwà ọ̀daràn náà bà ṣì ń pọ̀ si, àwọn èèyàn káàkiri South Africa ń ṣe gbogbo ohun tó wà ní ìkáwọ́ wọn láti fi dá ààbò bo ìlú àti agbègbè wọn.
















