Wọ́n ṣàwárí ọkùnrin kan lábẹ́ ilé àwókù lẹ́yìn ọjọ́ márùn-ún

Aworan ile awoku

Wọ́n ṣàwárí ọkùnrin kan lẹ́yìn ọjọ́ márùn-ún tó ti wà lábẹ́ ilé àwókù.

Ori tun ti ko ọkan lara awọn oṣiṣẹ to ha sabẹ ile to da wo niluu George to wa lorileede South Afrika yọ lọwọ iku, lẹyin ọjọ bii marun-un to ti wa labẹ awoku ile naa.

A gbọ pe awọn to n doola ẹmi awọn to wa labẹ awoku ile naa ni wọn gbọ ohun pe eeyan kan wa nibẹ, ti wọn si ṣe iranwọ lati fun un ni omi mu.

Alan Winde to jẹ oṣiṣẹ Western Cape Premier sọ pe iyanu nla ni bi wọn ṣe doola ẹmi arakunrin naa, ati pe ireti awọn lo wa si imuṣẹ.

Ọjọ Aje to kọja yii ni wọn sọ pe apakan lara ile naa da wo, nibi ti awọn ti ko din ni mẹrinla ti jade laye, ti wọn ko si tii ri awọn mọkandinlogoji.

Awọn mọkanlelọgọrin ni iroyin fi to wa leti pe wọn n ṣiṣẹ lọwọ ninu ile ọhun nigba to wo lulẹ.

Mẹtala ninu awọn ti ori ko yọ lọwọ iku ni wọn ko lọ gba itọju lọsibitu.

Ileeṣẹ iroyin ilẹ South Afrika ti News24 to gbe iroyin ọhun lo fidi rẹ mulẹ pe Gabriel Gambe, ẹni ọdun mẹtalelọgbọn to yan iṣẹ awọn to n lẹ ilẹ (tiler) ni ọkunrin ti wọn ṣẹṣẹ ṣawari rẹ labẹ awoku ile naa leyin ọjọ bii marun-un.

Loju ẹsẹ ti wọn ti rii ni wọn ti gbe e wọnu mọto itọju iṣẹlẹ pajawiri, eyi ti wọn fi gbe e lọ si ọsibitu.

Nigba to n sọrọ, Ọgbẹni Winde fi idunnu rẹ han lori bi wọn ṣe ri ẹmi Gambe doola, to si loun ko le ṣai dupẹ lọwọ ikọ to n doola ẹmi awọn eeyan.

“A ko sọ ireti nu, ati pe lonii, mi o le ṣapejuwe bi inu mi ṣe dun to, to si mu ọkan mi balẹ. Mo dupẹ lọwọ gbogbo ikọ yii, ẹyin ni akikanju to ṣẹgun.”

Colin Deiner, toun jẹ alakoso ileeṣẹ to n ri sọrọ iṣẹlẹ pajawiri ninu ọrọ tiẹ naa sọpe Ọgbẹni Gambe ti sọ fun awọn pe ọkunrin naa ni ẹsẹ to wuwo, ko si le gbe e daadaa.

O ni eyi lo jẹ ki awọn wa ọna ti wọn fi ri ọkunrin ọhun gbe jade lai jẹ pe o fi ara pa pupọ

O ni akọṣẹmọṣẹ oniṣegun meji ọtọọtọ lo wa lati ṣe iranwọ ati itọju.