Wo àwọn ìlú méjì tí wọ́n ti fẹ́ràn tàbí kóríra Ìbejì ní Nàìjíríà

Oríṣun àwòrán, AFP
Nigba ti a de ilu kan lorilẹede Naijiria ti won n pe ara wọn ni olu ilu awọn ibeji lati se iwadii bibi pupọ ibeji se n waye ni ilu kekere ti Igbo-Ora, iroyin to ki wa kabọ ni iroyin pe obinrin kan sese bi ibeji ni ile iwosan agbegbe naa.
Iya wọn jẹ ibeji - ikeji rẹ lokunrin wa ni wọọdu ti o n ya awọn fọto awọn ọmọ tuntun.
Ninu wọọdu naa ni a ti ri iya agba awọn ọmọ naa, ti oun jẹ ibeji fun rarẹ, ati iya-nla wọn, ti oun naa tun bi ibeji meji.
"Bayii ni a ṣe n ṣe ni ibi bayii . A ma bi awọn ibeji. O jẹ ki ohun to ṣe pataki si ilu wa"
iya agba awọn ibeji sọ fun BBC.
"O jẹ ohun iwuri fun wa ati pe a nifẹ wọn. A nifẹ awọn ibeji wa Wọn mu aṣeyọri wa fun wa, "iya sọrọ.
"Ibanujẹ ma de ba awọn eeyan ti wọn ko ba bi ibeji."
Lootọ ni pe Igbo-Ora, ni guusu iwọ-oorun orilẹ-ede Naijiria, dabi ẹni pe o ni iye awọn ibeji ti o pọ ju - ti ẹ ba rin ni ilu naa o rọrun lati rii awọn ibeji, ti wọn wo aṣọ kana lati se anko.
Iwọn ibimọ ni agbaye fun awọn ibeji jẹ iwọn mejila ninu fun ọmọ ẹgbẹrun ka, ṣugbọn ni Igbo-Ora o jẹ nipa ida iwọn marindinlaadọta ninu ẹgbẹrun kan.

Oríṣun àwòrán, AFP
Ninu asa Yoruba, eyi to gbinlẹ ni guusu-iwo oorun orilẹ-ede yii, ibukun ni awon ibeji je, ti oruko won si ti wa lati ọrun.
Lai wo boya o jẹ akọ tabi abo, ibeji to kọkọ jade ni a n pe ni Taiwo, itumo re ni “Eni o kọkọ tọ aye wo”, aburo ni a n pe ni Kehinde, itumo re ni “Eni ti o wa leyin”
Lọjọ kejì, ní ile ẹkọ giga Igbo-Ora a rí pe awọn orukọ wọnyi lo pọ ju nigba ti wọn n pe awọn akẹkọọ.
Nigba ti a ba beere lọwọ awọn akẹkọọ ile-ẹkọ lo le 1,500 ni apejọ owurọ lati na ọwọ wọn soke ti wọn ba jẹ ibeji, tabi ni ibeji kan ninu ẹbi wọn , o fẹrẹ jẹ apa ti gbogbo akẹkọọ naa lo wa loke.
Kilode ti ibeji fi pọ ni agbegbe naa?
Gẹgẹ bí ìtan atẹnudẹnu ṣe sọ, ọmọ arẹmọ Ọba Oyo kan ti wọn le kuro ni ilu ni wọn sọ fun pe ko se awọn etutu fun awọn Oosa ni ọna meji, to si ko orire ba ilu naa.
Ọpọlọpọ awọn eeyan lagbegbe fi igbagbọ wọn sinu ọbẹ jíjẹ ti a npe ni "ilasa", ti a ṣe lati awọn ewe ila.
Ewe ila yii ni wọn ma n se pẹlu ẹgusi, iru, iyọ ati orisirisi.
Idi ti o wa lẹyin ibimọ ibeji pupọ ni Igbo-Ora jẹ koko-ọrọ ti ikẹkọ ni Naijiria.
Diẹ ninu awọn ibeji ti wọn bi ni Igbo-Ora ni o jọra - nigbati ẹyin kan ba gbo yoo pin.
Awọn oniwadi n ṣe iwadii boya awọn kẹmika adayeba ni ounjẹ agbegbe naa , bii ilasa tabi boya paapaa iṣu, le jẹ ki awọn obinrin ṣe ni lọpọlọpọ ẹyin
Ọjọgbọn Akinola Kehinde Akinlabi to jẹ Oga agba fun ile ẹkọ giga ìmọ ẹrọ ati eto ọgbin ní ìpínlẹ Oyo to wa ni Igbo-Ora ọrọ pọ nidi ohun to n ṣókunfa ìbeji.
Ọmọwe naa ti oun naa jẹ ibeji - ati baba awọn ibeji, sọ pe ẹnikan ti a bi ni ibeji ni awọn ẹya wọnyi kii yoo nira lati wa iyawo tabi ọkọ.
"Awọn ibeji ni a bọwọ fun gẹgẹ awọn oriṣa ti o mu orire ati aabo wa. Awọn eniyan fun awọn ibeji ati awọn idile wọn ní awọn ẹbun, owo ati awọn anfani iranlọwọ. Gbogbo eyi lo gba eniyan niyanju lati fẹ awọn ti o wa lati idile ibeji, "o sọ fun BBC.
Olori ibile ilu naa, ti a mọ si oba, n duro de awọn esi abajade ti awọn iwadii imọ-jinlẹ.
Jimoh Olajide ni ireti pe ni orilẹ-ede ti o ni ifẹ lati ṣeto igbawọle Guinness World Records, Igbo-Ora yoo ni idanimọ ni laipẹ fun ohun pataki re - pe ko fẹ si ile kan ni ilu naa ti ko ni ibeji.
“Iriran mi fun ilu yii ni lati rii pe a gba ami ẹyẹ agbaye fun bibi ibeji pupọ julọ ni gbogbo agbaye,” Oba Ọlajide, ti o jẹ baba ti awọn ibeji sọ fun BBC.
"Awọn nkan ti yoo tẹle yoo jẹ eto irin-ajo afẹ,awọn ile itura."

Pẹlu eyi ni lokan, ilu naa ṣe ifilọlẹ ajọdun ibeji kariaye lododun ni ọdun diẹ sẹyin.
Ọjọgbọn Akinlabi nireti pe gbigba jumọ ọrọ ibeji yoo tun idoko-owo wọle fun agbegbe Igbo Ora lati koju awọn nkan bii awọn kudiẹkudiẹ eto ilera.
Pelu bi esin Islam ati Kristiẹniti ṣe gbinlẹ ni agbegbe naa, awọn ẹlẹsin ibilẹ si n bọ awọn ere ibeji ni agbegbe.
Kehinde Adeleke, olutọsọna wa ati ikeji rẹ, mu wa lọ ibi ti wọn se etutu, níbi ti wọn ti pese epo ati ẹwa fun Oosa ibeji.
Arabinrin Adeleke ti o ni ọmọ meji sugbọn ti ko ti bí ibeji sọ pe “Gẹgẹ bii ibeji, mo mọ pe mo ni ibukun"
“Inu mi yoo bajẹ ti n ko ba bi ibeji - awọn ibeji ni mo nilo,” o ba wa sọrọ larin ilu ati orin ni ibi ayẹyẹ naa
Iru awọn ìwa yii si awọn ibeji lọ jẹ ìbanujẹ pata pata fun awọn ọmọ ẹgb kan ni agbo Bassa-Komo nitosi olu-ìlu Abuja. Ibeji l fun wọn jẹ orisun iberu.
Ní aarin ọdun 1990s, olusọ aguntan miṣannari Naijiria, Olusola Stevens gbọ pe awọn ara abule yii ni igbagbọ pe nnkan buruku ni ibeji, ti wọn si n ku lojiji.
Iru awọn igbagbọ yii ko jẹ tuntun ni Naijiria - paapaa ni guusu ila-oorun orilẹ-ede naa nibiti awọn agbegbe oriṣiriṣi ti pa awọn ibeji nigbakan, botilẹjẹpe iru awọn iṣe bẹẹ ti pari ni pipẹ sẹyin.
Olusọ agutan Stevens, ti o wa ni Gwagwalada, pinnu lati ṣe iwadi.
"A bẹrẹ lati lọ lati agbegbe si agbegbe ti a beere: 'Nibo ni awọn ibeji wa?' Idahun wọn ni pe awọn oriṣa ti pa wọn, iya wọn ko ni fun wọn ni ọmu, ti wọn yoo si ku fun ara wọn "o sọ.

Misọnari tun ri pe nigba mii àwọn ọmọ ọwọ ni wọn ma ń fún wọn ni agbo tí ko ni jẹ kí wọn sanra mu.
Ko ṣe kedere ohun to sokunfa idi ti wọn n pe iru awọn ọmọde bẹẹ ni awọn ọmọ buburu, ṣugbọn o le jẹ pe ni igba atijọ wọn ti sopọ mọ aini ati ewu.
Olusọ agutan Stevens ati ẹgbẹ rẹ bẹrẹ gbigba awọn ọmọde wọnyi silẹ ati pe wọn ṣeto Ile-itọju orphanage Vine Heritage Home, eyiti o tọju lọwọlọwọ awọn ọmọde igba níye.
Lati yi ìwa yii pada, wọn bẹrẹ nípa pípese awọn abule yii pẹlu eto ìlera ati awọn kanga lati rí omi mímọ mu.

Oríṣun àwòrán, Peter McJob BBC
Ile-itọju ọmọ alainibaba tun n ṣiṣẹ pẹlu Action Aid lori eto Iranlọwọ ti wọn ṣe nipasẹ European Union, ti ijọba tun ti ṣe ipilẹṣẹ akiyesi nla kan fun idanilẹkọọ.
Nitori bẹẹ, ọpọlọpọ lati agbegbe Bassa-Komo ni wọn ti n tọju awọn ibeji wọn, ṣugbọn ti awọn obi ba wa ni ero ọkan búburú, wọn yoo fi awọn ọmọ naa le awọn ọmọ alainibaba lọwọ - ti wọn si lọ ṣabẹwo si wọn nibẹ.
Ni kukuru, nnkan bí ọmọ mẹtadinlọgbọn [27] ló gba ẹbẹ awọn obí wọn lati pada síle, kí wọn le maa bawọn wọn gbe, bó tilẹ jẹ pe ìpinnu naa kò rọrun fun awọn ọmọ naa.

Oríṣun àwòrán, Peter McJob/BBC
Olufemi Stevens ti oruko re n je "Wonder Boy" so wipe "Nigba akoko ti mo ri baba mi nigba ti mo pe omo odun mejidinlogun, inu mi bajẹ pe o fi mi sile".
O dagba ni ile alainibaba lẹyin ti iya rẹ ti ku ni akoko to n bimọ, ṣugbọn inu rẹ dun pe o ni igboya lati lọ si ile: "Nigbati wọn ri mi, wọn mọ pe awọn ọmọ wọnyi kii ṣe ọmọ buburu.
"Ati nigbati mo pada, ẹnu ya mi lati ri awọn ibeji kan pẹlu iya wọn. Eto mi ni lati pada lọ ṣeto ile-ẹkọ fun wọn - ẹkọ ni kọkọrọ"
Olusoagutan Stevens mọ pe awọn ibeji kii yoo ni itẹwọgba bi wọn ṣe wa ni Igbo-Ora, ṣugbọn o nireti pe ni ọjọ kan awọn iṣẹ rẹ ko ni nilo.












