'Irọ́ ni mo pa pé Ọọni Ile-Ife ni bàbá mi àmọ́ ìdí tí mo fi parọ́ rèé'

Oríṣun àwòrán, Screenshot
Ọrọ ti pada bẹyin yọ fun gendekunrin kan to sọ pe Ọọni Ile-Ifẹ, Ọba Adeyẹye Ẹnitan Ogunwusi, Ọjaja keji ni baba to bi oun lọmọ, ati pe oun fun kabiyesi ni gbedeke oṣu meji lati tẹwọ gba oun gẹgẹ bi ọmọ.
Ọdọmọkunrin naa to kọ lati darukọ ara rẹ ninu fọnran to tun ṣẹṣẹ gbe jade laipẹ yii lo ti n rawọ ẹbẹ si Ọọni pe irọ to jinna si otitọ loun n pa, ati pe ọna lati fi oju kan an loun n wa.
Ninu fọnran to ti n bẹbẹ ọhun lo ti sọ pe ala toun la lọdun diẹ sẹyin wi pe kabiyesi fun oun ni ilẹkẹ, toun si gbiyanju lati ri kabiyesi, ṣugbọn to ja si pabo lo jẹ koun sọ pe kabiyesi ni baba oun.
“Mo ki gbogbo ọmọ Naijiria, mo si fẹẹ fi asiko yii sọrọ nipa fọnran ti mo ṣe fun baba mi, Kabiyesi, Ọọni Ile-Ifẹ, Ọjaja keji, ọba wa. Bi mo ṣe pe baba mi ni baba to bi mi, mi o ro pe boya mo ṣi sọ.
“Nitori pe bi ẹ ba wo o, baba wa Ọọni Ile-Ifẹ ni olori ilẹ Oodua. Mi o tii ri bi ẹni ọhun ṣe le dagba to, awọn naa ni baba wa to bi wa nilẹ Yoruba.
“Ṣugbọn o ni idi ti mo fi ṣe fọnran naa jade, ni ọdun 2022, mo la ala kan nipa kabiyesi. Mo wa ni ẹgbẹ wọn, a si jọ n sọrọ loju ala yẹn. Mi o tiẹ wa mọ pe ala ni mo n la.
“Kabiyesi fun mi ni ilẹkẹ kan to wa lọwọ mi. Ṣugbọn ibi ti kabiyesi ti fa mi dide, ti a ti n lọ, ibẹ ni mo ti taji.
“Igba ti mo taji, ala yẹn ru mi loju. Nnkan to wa sọ si mi lọkan ni pe kabiyesi ni baba ilẹ Oodua, awọn ni baba wa, ti a ba si la ala ri wọn, mi o ro pe iyẹn buru.
“Mi o la ala ri ọba ri, ṣugbọn mo maa n la ala ri awọn gomina. Igba to di ọjọ keji ti mo la ala yẹn, mo wa ronu ohun ti mo le ṣe, nitori pe awọn ala ti mo maa n la maa n ni itumọ si mi.
“Ọjọ kẹta ni mo gbera lọ si Ile-Ifẹ boya mo le ri kabiyesi. Mo gbiyanju ki n ri kabiyesi, ṣugbọn lati aarọ ti mo ti debẹ, mi o ri kabiyesi titi di alẹ ti mo fi kuro nibẹ pada sile.
“Ṣugbọn igba ti mo de ile ni mo ronu pe ala ti mo la yii ni itumọ, nitori pe ti ko ba ni itumọ, mi o nii ri kabiyesi wi pe wọn fun mi ni ilẹkẹ loju ala.
“Igba to ya, mo wọnu yara igbohunsilẹ (studio) lati ṣe orin jade fun kabiyesi nitori pe olorin ni mi, wi pe boya ti mo fi orin naa jade sori ayelujara, boya kabiyesi maa wa mi. Mo sa gbogbo ipa boya orin naa yoo jẹ ki n ri kabiyesi, ṣugbọn pabo lo ja si.
“Igba to to asiko kan, mo ba ọga mi kan sọrọ lati Canada wi pe boya wọn ni ẹni to sunmọ kabiyesi. Ọga mi naa fun mi ni ẹnikan, ti a si jọ sọrọ Facebook ati Whatsapp.
“Ẹni lo sọ pe ki n kọ lẹta lati lọ si aafin, ki n si fin orin ti mo ṣe sinu ẹ, wi pe ti kabiyesi ba rii, wọn maa ranṣẹ pe mi. Mo daamu titi lati ṣugbọn pabo ni gbogbo igbiyanju mi ja si.
“Ti mo ba ri ibi kan ti wọn ti darukọ Kabiyesi Ẹnitan Ogunwusi sibẹ, maa sọrọ sibẹ, maa tun fi orin naa ranṣẹ, titi ti ọdun naa fi lọ. Igba to ya ni mo sọ ireti nu pe bi Ọlọrun ba kọ riri wa, emi ati kabiyesi maa rira.
“Ṣugbọn idi ti mo fi n sọrọ yii ni pe mi o wa lati wa ba orukọ kabiyesi jẹ nitori pe awọn ni baba wa nilẹ Oodua.
“Ni nnkan bi oṣu kan sẹyin, mo wa la ala miran pe mo ri kabiyesi. Ala yẹn lo wa jẹ ki n tun ronu pe ki ni idi ti mo tun fi la ala ri kabiyesi, ti mo tun wa lẹgbẹ wọn, ti a si jọ n sọrọ.
“Ala yẹn ko ye mi, iyẹn lo tun jẹ ki n ṣe fọnran ti mo ṣe jade wi pe kabiyesi ni baba mi, ati pe mi o jẹbi, mi o si parọ lati sọ pe kabiyesi ni baba mi, nitori pe awọn lo bi mi, awọn si ni baba wa nilẹ Oodua.
“Ṣugbọn mo wa fi asiko yii bẹ baba mi kabiyesi, ki ade pẹ lori, ki bata pẹ leṣe, ki ẹsin ọba jẹ oko pẹ. Baba mi, ẹ ma binu si mi, mi o ṣe fọnran lati fi ba orukọ jẹ, ṣugbọn mo ṣe e lati le rii yin, ki n le sọ bi mo ṣe n la ala, nitori pe ko ye mi.
“Bi mo ṣe pe yin ni baba mi, ẹyin naa lẹ ṣi bi mi, nitori pe ọmọ ilẹ Oodua ni mi. Ẹ ma binu, ẹyin ọmọ Naijiria, ẹ ma gbe fọnran mi, nitori pe mi o ṣe e lati fi ba orukọ Ọọni jẹ.”















