N kò ní ọmọ kankan níta - Ooni fèsì padà fùn ọ̀dọ́mọkùnrin tó pe ara rẹ̀ ní ọmọ Ooni

Oríṣun àwòrán, Others
Ooni ti ile ife, Oba Enitan Adeyeye Ogunwusi ti jẹ ko di mimọ pe oun ko ni ajọsepọ baba si ọmọ pẹlu ọdọmọkunrin kan to pe ara rẹ ni ọmọ oun.
Ninu atẹjade tí agbẹnusọ Ooni, Moses Olafare fi lede, Ooni ni ọdọkunrin naa ti wu wa ibanilorukọ jẹ, to si kesi awọn agbofinro lati se iṣẹ wọn.
Olafare ni Ọba Ogunwusi, gẹgẹ bii baba to mọ aṣa, to tun jẹ Arole Oodua mọ gbogbo awọn ọmọ rẹ, ti ko si fi igba kankan ma ṣe ojuṣe rẹ gẹgẹ bii baba fun wọn.
O ni ọdọmọkunrin to n pe ara rẹ ni ọmọ Ọba yii lo jẹ ajoji si Aafin ati si gbogbo ilu Ile Ife, ti ko si ẹnikẹni to mọ ọ ri.
Olafare ni “Ko ki n se ọmọ Ọba Ogunwusi gẹgẹ bii o ṣe sọ, ko si fi ibi kankan tan mọ idile Ogunwusi ati idile Giesi niluu Ile Ife.
"Wọn pe akiyesi wa si fọnran kan níbi ti ọdọmọkunrin naa ti sọ pe oun jẹ ọmọ fun Baba wa, Arole Oodua Olofin Adimula, Ooni Adeyeye Enitan Ogunwusi, Ojaja II, ti fọnran naa si ti gba gbogbo ori ayelujara.
"Ni gbogbo ọna ni a fi bu ẹnu atẹ lu iwa itiju yii.
"Gbogbo awọn ọmọ Ooni ni a mọ ni Aafin ati ni gbogbo Ile Ife, akọbi ọmọ fun Ooni, Ọmọọba Adeola Ogunwusi wa niluu Canada, Ọmọọba Adewamiwa Ogunwusi ti oun naa wa niluu Dublin.
"Ọmọọba Adesewa n se daada, Ọmọọba Tadenikawo Ogunwusi wa pẹlu Iya rẹ ni alaafia, ti awọn ibeji tuntun naa, Ọmọọba Adebisi Kehinde ati Ọmọọba Taiwo Adeayo yoo wọle si Aafin laipẹ ni ilana ti asa ile ife.”
"Oṣu meji ni mo fun Ooni lati tẹwọgba mi "
Ṣaaju ni ọdọmọkunrin naa ti ko darukọ ara rẹ ninu fọnran to gbe jade ti ni o da oun loju pe Ooni ni baba to bi oun lọmọ.
O ni Ooni fi oun pamọ pẹlu iya oun pẹlu aṣẹ pe oun ko gbọdọ fara oun han síta.
O tẹsiwaju pe didakẹ Ooni si oun gẹgẹ bii Ọmọọba lo jẹ ki oun jade lati se fọnran.
Ọkunrin "Ni igbakugba ti mo ba fẹ wa si Aafin, wọn maa sọ fun mi pe ko tii to asiko.
“Asiko ti to bayii. Iya mi le ma sọrọ ṣugbọn emi yoo sọ otitọ ọrọ. Kabiyesi ni Baba mi.
"Lootọ iya o jẹ mi; ile wa, ọkọ ayọkẹlẹ wa, owo n bẹ ṣugbọn gbogbo eyi ni ko wu mi mọ.
"Mo fẹ ki wọn mọ mi gẹgẹ bii Ọmọọba Ọba Adeyeye Ogunwusi, Ojaja II."
Bakan naa ni o fun Ọba ni oṣu meji pere lati ransẹ pe oun wa si Aafin tabi ko tu awọn asiri kan nipa Ọba alaye naa fun gbogbo araye.















