Mahatma Deby borí ìdìbò gẹ́gẹ́ bí ààrẹ tuntun lórílẹ̀èdè Chad

Deby

Oríṣun àwòrán, AFP

Olori ijọba ologun lorilẹede Chad, Ọgagun Mahamat Deby ti jawe olubori ninu eto idibo aarẹ to waye lorilẹede naa.

Eto idibo aarẹ yii to waye ni akọkọ eto idibo ti yoo waye lorilẹede naa lati nnkan bii ọdun mẹta ti awọn ologun ti gba ijọba nibẹ.

Ninu awọn esi ibo akọkọ ti ajọ eleto idibo lorilẹede naa fi sita, Deby ti ko ida mọkanlelọgọta (61%) ibo ti wọn ti ka, olotu ijọba nibẹ to tun jẹ ọkan gboogi ninu awọn oludije alatako, Succes Masra lo n ṣe ipo keji pẹlu ida mejidinlogun abọ ibo (18.5%).

Ko tii pe wakati kan si idibo naa ti Succes Masra ti kede ara rẹ gẹgẹ bi olubori ibo naa, pẹlu ẹsun wi pe awọn eeyan kan ti ko darukọ n gbero lati da idibo naa ru.

Ṣaaju idibo ọhun, awọn onwoye ṣalaye pe wọn kan gbe idibo naa kalẹ lati fi ontẹ lu ijoko Deby ni ipo agbara ni.

Ireti wa pe Igbimọ ofin lorilẹede naa yoo kede apapọ esi ibo naa laipẹ ọjọ.