Ṣé lóòtọ́ọ́ ni ìjàmbá ọkọ̀ ṣẹlẹ̀ sí Tijani Babangida agbábọ́ọ̀lù Náíjíríà tẹ́lẹ̀ rí?

Aworan Tijani Babangida

Oríṣun àwòrán, Tijani Babangida/Instagram

Iroyin to tẹ wa lọwọ lo sọ pe ori ko agbabọọlu Super Eagles Naijiria tẹlẹri, Tijani Babangida yọ ninu ijamba ọkọ ti eeyan kan ti dero ọrun.

Ijamba ọkọ yii ni a gbọ pe o ṣẹlẹ ni Ọjọbọ lasiko ti Babangida n rinrin ajo lopopona Kaduna si Zaria.

Iroyin kan fidi rẹ mulẹ pe Babangida wa ninu ọkọ pẹlu iyawo rẹ ati aburo rẹ pẹlu.

Garba lawal to jẹ akẹgbẹ Babangida ninu ikọ agbabọọlu Super Eagles fidi iṣẹlẹ ọhun mulẹ fun BBC pe lootọọ ni iṣẹlẹ naa waye.

''Otitọ ni pe ijamba ọkọ ṣẹlẹ si Tijani Babangida ati ẹbi rẹ.

Babangida ati iaywo rẹ n gba itọju nile iwosan, amọ, o ṣeni laanu pe aburo rẹ, Ibrahim Babangida ku ninu iṣẹlẹ naa,'' Lawal lo sọ bẹẹ fun BBC.

Emmanuel Babayaro ti oun naa jẹ akẹgbẹ Tijani sọ pe ''a jẹki a maa gbadura fun aarẹ wa Tijani Babangida ti ijamba ọkọ ṣẹlẹ si lopona Kaduna si Zaria.''

Babangida wa lara awọn agbabọọlu Naijiria to gba ami ẹyẹ goolu ni idije 'Olympics' Atlanta '96 lorilẹede Amẹrika.

Ọpọ awọn ololufẹ ere bọọlu ọmọ Naijiria ni wọn maa n ṣe ireti goolu meji ti Babangida gba sawọn South Africa ni idije Afcon ti Naijiria gbalejo rẹ pẹlu Ghana lọdun 2000.

Babangida ni aarẹ ẹgbẹ agbabọọlu PFAN lọwọ yii.