Ilé aṣòfin àgbà l'Abuja buwọ́lu ìdájọ́ ikú fáwọn tó ń gbé oògùn olóró

Oríṣun àwòrán, NDLEA/X
Ile aṣofin l’Abuja ti buwọlu idajọ iku fawọn to n fi oogun oloro ṣe kata kara.
Ni Ọjọbọ ọjọ kẹsan an oṣu Karun un ọdun 2024 yii ni aba idajọ iku fawọn to n gbe oogun oloro naa de ipele kẹta.
Aba ọhun ti wọn pe orukọ rẹ ni atunṣe ofin 2024 NDLEA ni igbimọ kan nile aṣofin agba jiroro lori rẹ l’Ọjọbọ.
Nigba ti wọn n ṣe agbeyẹwo ofin ajọ NDLEA to n gbogun ti oogun oloro ni Naijiria, Sẹnẹtọ Peter Nwebonyi lo daba wi pe ki ile aṣofin fi idajọ iku rọpo ẹwọn gbere to jẹ ijiya fawọn ti wọn ba gbamu fun kata kara oogun oloro.
Nigba tawọn aṣofin bẹrẹ si ni dibo lori ọrọ naa, o kọkọ dabi ẹni pe awọn to tako idajọ iku ti wọn n jiroro le lori lo pọju.
Amọ, igbakeji aarẹ ile aṣofin agba naa dibo wi pe idajọ iku lo yẹ awọn to n fi oogun oloro ṣe kata kara, iyẹn lo jẹ ki wọn gba aba ọhun wọle.
Ẹwẹ, Sẹnẹtọ Adams Oshiomole fi aidunnu rẹ han lori bi ile ṣe tete gba aba idajọ iku naa wọle.
Amọ, igbakeji aarẹ ile aṣofin agba sọ pe ile ko le yi igbesẹ rẹ pada tori Oshiomole pẹ ko to tako aba naa eyi to lodin si ofin ile.
Ibuwọlu awọn sẹnẹtọ tumọ si pe ẹnikẹni to ba n gbe eegbogi olori bii ‘’cocaine, LSD, heroin,’’ atawọn oogun oloro mii tabi ti o ba n ṣe e to fi mọ awọn to ba n gbin in le gba idajọ iku ti aba naa ba do ofin tan.
Idajọ iku fawọn to n gbe oogun oloro ti maa n fa awuyewuye laarin awọn amofin atawọn ajafẹtọọ ọmọniyan.
Awọn kan gbagbọ pe idajọ iku dara tori o maa jẹki ẹnikẹni to ba fẹ hu iru iwa bẹẹ kọwọ ọmọ rẹ bọ aṣọ.
Amọ, awọn to tako idajọ iku maa n sọ pe o ṣeeṣe ki aṣimu ọdaran wa eyi to le jẹ ki ijọba gbẹmi alaiṣẹ.
Ju gbogbo rẹ lọ, ọpọ lo gbagbọ pe igbesẹ ile aṣofin agba l’Abuja n ṣafihan akitiyan awọn aṣofin lati gbogun ti iwa ọdaran to niṣe pẹlu oogun oloro.















