Wo àwọn awuyewuye tó ṣúyọ lórí ọ̀nà Eko sí Calabar tí ìjọba Nàìjíríà fẹ́ ṣe

Oríṣun àwòrán, BOLA TINUBU/FACEBOOK
Láti ìgbà tí ìjọba àpapọ̀ Nàìjíríà ti kéde pé àwọn fẹ́ ṣe ọ̀nà láti ìpínlẹ̀ Eko lọ sí Calabar, olú ìlú ìpínlẹ̀ Cross River ni awuyewuye ti ń wáyé lórí ọ̀nà náà.
Ààrẹ Bola Tinubu buwọ́lu ṣíṣe ọ̀nà ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rin kìlómítà (700km) náà nínú oṣù Kejì ọdún 2024, ọdún mẹ́jọ sì ni yóò gba ìjọba láti parí rẹ̀.
Ṣùgbọ́n láti ìgbà tí ìjọba ti kéde ìpinnu wọn láti ṣe ọ̀nà náà ni àwọn èèyàn ti ń sọ̀rọ̀ lórí rẹ̀.
Àwọn olóṣèlú, àjọ tí kìí ṣe ti ìjọba tó fi mọ́ àwọn tálákà ló ti fi èrò wọn hàn lórí kíkọ́ ọ̀nà ọ̀hún.
Èyí ló mú wa wo àwọn awuyewuye tó ti wáyé lórí ọ̀nà yìí.
Ọ̀nà yìí ní nǹkan ṣe pẹ̀lú Seyi Tinubu
Igbákejì Ààrẹ tẹ́lẹ̀ rí ní Nàìjíríà, tó tún jẹ́ olùdíje sípò Ààrẹ lẹ́gbẹ́ òṣèlú Peoples Democratic Party, PDP, Alhaji Atiku Abubakar ní ọ̀kan nínú àwọn ọmọ Ààrẹ Tinubu ní nǹkan ṣe pẹ̀lú kíkọ́ ọ̀nà yìí.
Nínú àtẹ̀jáde kan tí Atiku Abubakar fi sórí ìkànnì X rẹ̀ ní Seyi Tinubu wà lára àwọn Alákóso iléeṣẹ́ CDK Integrated Companies tó wà lára àwọn iléeṣẹ́ Chagoury Group tí Gilbert Chagoury jẹ́ olùdásílẹ̀ rẹ̀.
Atiku ní bí iléeṣẹ́ náà ṣe wá lára àwọn iléeṣẹ́ tó ń rí sí kíkọ́ ọ̀nà Eko sí Calabar náà lòdì sí òfin Nàìjíríà.
Ó ní iléeṣẹ́ ìròyìn kan ní orílẹ̀ èdè France Africa Intelligence News Agency ní àjọ tó ń rí sí ìforúkọ àwọn iléeṣẹ́ sílẹ̀ ní Nàìjíríà fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé Seyi Tinubu wà lára àwọn tó ni iléeṣẹ́ Chagoury Group.
Àmọ́ nígbà tí iléeṣẹ́ Ààrẹ fèsì padà fún Atiku nínú àtẹ̀jáde kan, wọ́n ní ohun tí iṣẹ́ àkànṣe ọ̀nà náà dálé kò yé Atiku.
Ohun tí wọ́n ní Tinubu ń ṣe ń wáyé ní àwọn ìpínlẹ̀ mìíràn
Lámèyítọ́ ètò òṣèlú kan ní Nàìjíríà, Abdulmajid Babangida Sa’ad ní bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ìjọba Nàìjíríà ti jiyàn ẹ̀sùn Atiku, ó ní bí kò bá ní ohun tó so Seyi Tinubu mọ́ ọ̀rọ̀ náà, wọn ò ní so ó pọ̀ mọ́ ọn.
Ó ní ohun ìbànújẹ́ ló jẹ́ pé ohun tí yóò bá ṣe àǹfàní fún àwọn olórí àtàwọn ẹbí wọn ni àwọn olórí Nàìjíríà máa ń ṣe láì nání àwọn ará ìlú tó dìbò fún wọn.
Abdulmajid fi kún ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé ohun tó lòdì sí òfin iṣẹ́ ni kí olórí gbé iṣẹ́ àkànṣe fún iléeṣẹ́ tó jẹ́ ti ara rẹ̀ tàbí ẹbí rẹ̀.
Ó wòye pé kìí ṣe Tinubu nìkan ló jẹ̀bi irú ọ̀rọ̀ báyìí nítorí ọ̀pọ̀ àwọn gómìnà káàkiri ìpínlẹ̀ Nàìjíríà ló ń gbé iṣẹ́ àkànṣe fún àwọn iléeṣẹ́ tó jẹ́ ti ẹbí, ìyàwó tàbí ọmọ wọn.
Bílíọ̀nù mẹ́rin náírà ni wọ́n máa fi kọ́ kìlómítà kọ̀ọ̀kan
Lára àwọn nǹkan tó fà awuyewuye láàárín ìjọba àtàwọn ará ìlú nígbà tí wọ́n kéde kíkọ́ ọ̀nà yìí ni iye owó tí wọ́n kéde láti fi kọ́ kìlómítà kọ̀ọ̀kan.
Atiku Abubakar ní pẹ̀lú iye tí ìjọba kéde àwọn máa ná lórí ọ̀nà náà, ó túmọ̀ sí pé bílíọ̀nù mẹ́jọ náírà ni wọ́n máa ná lórí kìlómítà kọ̀ọ̀kan.
Ẹ̀wẹ̀, Mínísítà fún iṣẹ́ òde, David Umahi ní ọ̀rọ̀ kò rí bẹ́ẹ̀, tó sì ní bílíọ̀nù mẹ́rin náírà ni àwọn máa ná lórí kìlómítà kọ̀ọ̀kan lòdì sí bílíọ̀nù mẹ́jọ náírà tí Atiku pè é.
David Umahi ní ó ṣeéṣe kí iṣẹ́ ọ̀nà ọ̀hún ná àwọn tó tírílíọ̀nù mẹ́ẹ̀dógún náírà.
Lọ́jọ́ Kìíní, oṣù Karùn-ún ọdún 2024 ni Umahi kéde pé ìjọba máa san owó gbà má à bínú fún àwọn tí ọ̀nà kíkọ́ náà ṣàkóbá fún ilé ìgbé àti okòwò wọn.
Ó ní ₦2.75bn ni ìjọba ti yà kalẹ̀ láti fi tu àwọn ènìyàn náà nínú.
'Àwọn ènìyàn bíi Atiku ń pe ìjọba sí àkíyèsí'

Abdulmajid Babangida Sa’ad kan sáárá sí Atiku Abubakar fún bí ó ṣe ń ṣe lámèyítọ́ àwọn ìgbésẹ̀ ìjọba lórí àwọn iṣẹ́ tí wọ́n ń ṣe tó ṣeéṣe kí ọ̀pọ̀ ọmọ Nàìjíríà má mọ̀ nípa rẹ̀.
“A dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run pé àwọn alátakò bíi Atiku Abubakar wà nítorí pé bí kò bá sí òun, ọ̀pọ̀ àwọn nǹkan ni kò bá ti kọjá mọ́ àwọn ọmọ lára.
“Kódà bí ọ̀pọ̀ nǹkan tí wọ́n bá fẹ̀sùn kàn ìjọba lé lórí kìí bá ṣe òótọ́, ó máa ń pe ìjọba padà lórí àwọn ìgbésẹ̀ wọn.”
Lẹ́nu ọjọ́ mélòó kan yìí ni Atiku Abubakar ti ń bù ẹnu àtẹ́ lu àwọn ìpinnu àti ìgbésẹ̀ ìjọba lábẹ́ ìdarí Ààrẹ Bola Ahmed Tinubu.
Ní ìbẹ̀rẹ̀ ọ̀sẹ̀ yìí ni Atiku Abubakar bu ẹnu àtẹ́ lu bí Tinubu àti igbákejì rẹ̀, Kashim Shettima ṣe rìnrìn àjò lọ ilẹ̀ òkèrè fún ìpàdé.
Atiku Abubakar ní Nàìjíríà wà lásán láìsí ẹni tó ń tukọ̀ rẹ̀ àmọ́ iléeṣẹ́ Ààrẹ fun lésì pé kò sí ibi tí Tinubu kò ti le máa ṣe ìjọba Nàìjíríà.












