Kí ló dé tí Garri gbé owó lórí lọ́jà? -

Àkọlé fídíò, Kí ló dé tí Garri gbé owó lórí lọ́jà - Àwọn àgbẹ̀ ṣàlàyé ohun tí ojú wọn ń rí
Kí ló dé tí Garri gbé owó lórí lọ́jà? -

Pupọ awọn araalu lo n kegbe sita pe Garri lo jẹ pọku lowo rẹ, to si n gba ọpọ lọwọ ebi naa ti gbe owo lori lọja bayii.

Bo ti lẹ jẹ pe awa ara wa ni a n gbin awọn nnkan ti a n fi ṣe Garri bi ẹgẹ sugbọn sibẹsibẹ wiwa garri mu ti di inira fun awọn araalu lasiko yii.

Ileeṣẹ BBC tẹ ọkọ leti lọ oko Garri lati lọ ba awọn agbẹ sọrọ paapa awọn agbẹ to mọ nipa ẹgẹ gbingbin.

Ọmọwe Adeola Odedina to ti fi igba kan jẹ kọmisana fun eto ọgbin Ogun, to tun jẹ agbẹ to n gbin ẹgẹ ni ko ki n ṣe oni ni awuyewuye ti bẹrẹ lori Garri wipe o wọn lọja.

O ni otitọ ni pe gẹgẹ bi isẹdalẹ wa ni ile Yoruba, a ko le fọwọ rọ Garri sẹyin .

Aworan

“Ti a ba ti ri Garri wa mu, ebi ti kuro ninu iṣẹ.”

“Nigba ti ọwọngogo de ba gbogbo nnkan, ko le fi kan silẹ, epo Diesel wọn, epo bẹntiroolu wọn, eto irinna wọn jẹ nnkan to jẹ ki owo Garri naa lọ soke.”

Ni pupọ awọn nnkan ti awọn fi n gbin ẹgẹ lo ti gbe owo lori, to si n fa inira fun awọn agbẹ loko.

Iya oni Garri, to pe ara rẹ ni Iya Alimo ba wa sọrọ, to si salaye pe yatọ si nnkan ti wọn, Idi ti paki fi wọn ni ojo to rọ kọja ti ba gbogbo paki jẹ ninu oko to si ba gbogbo paki jẹ tan.

“Ni bayii, apẹẹrẹ paki a ma n ra ni ẹgbẹrun meji naira tẹlẹ sugbọn bayii a n ra ni ọgbọn ẹgbẹrun naira.

“Idi ti awa oni Garri fi wa wo pe ki awa na fi owo le Garri niyẹn.

Ọmọwe Odedina wa pe fun iranlọwọ fun awọn agbẹ nipa bi wọn yoo ṣe ma ṣe ẹgẹ, irọnu yoo de ba pupọ awọn ninu oko.