Alfa dáná sun ilé ìyàwó rẹ̀ tó kọ̀ láti kírun pẹ̀lú rẹ̀ l’Ekiti

Oríṣun àwòrán, getty images
Olukọ ẹsin Islam kan nipinlẹ Ekiti, Ahmed Ojo, ti sọ ina si ile iyawo rẹ latari pe o kọ lati darapọ mọ oun lati kiruun.
Agbegbe Egbe Odo, to wa ni Isua Ijesha nipinlẹ Ekiti ni iṣẹlẹ ọhun ti waye.
Ninu ifọrọwerọ pẹlu ileeṣe iroyin Abẹle Punch, obinrin ti ọkọ rẹ jo ile rẹ, Bosede Afolabi sọ pe iṣẹlẹ naa waye lọjọ kẹtadinlogun, oṣu Kẹrin, ọdun 2024.
Gẹgẹ bii ohun to sọ, ọkunrin naa wa sile ni nnkan bii aago mọkanla alẹ, o si ke si oun pe ki wọn wa kirun ṣugbọn oun kọ nitori o ti rẹ oun.
Afolabi ṣalaye siwaju si pe igbeṣe oun naa bi ọkọ oun ninu, eyii to mu ki oun pe awọn eeyan adugbo lati da si ọrọ naa.
Obinrin ọhun sọ siwju si pe nigba ti wahala naa sun oun loun fi ile oun ti wọn n gbe silẹ lati lọ sun sile ara adugbo wọn mii.
O ni “ni nnkan bii aago mejila oru ni ọdọbinrin kan ladugbo wa kan ilẹkun ile ti mo wa lati sọ fun pe ile mi ti n jona ati pe igbagbọ wa pe ọkọ mi lo sọ ina si ile naa.
“Lẹyin naa ni ọwọ tẹ afurasi ọhun ti wọn si fa a le ọlọpaa lọwọ.”
Obinrin naa sọ pe oun di iyawo Ojo lẹyin ti ọkọ oun akọkọ papoda, ile oun ni afurasi si n gbe lati igba ti wọn ti fẹ ara wọn.
Bo tilẹ jẹ pe o ni kii ṣe pe ija ti maa n waye laarin awọn mejeji tẹlẹ, oun gbagbọ pe o ti mu ọti yo lọjọ to dana sun ile oun naa.
O ni “ohun ti mo ṣakiyesi ni pe o ti mu ọti yo, idi ree ti mo fi yẹra fun wahala to waye lọjọ naa, lọpọ igba lo maa n wa sile ti yoo mu ọti yo amọ a ko tii ni ija to buru lọ titi.
“Mi o mọ bi ara mi ṣe wa lati igba ti iṣẹlẹ naa ti waye nitori adanu ti iṣelẹ ọhun mu ba aye mi, mo bẹ awọn ọmọ Naiiria ki wọn ṣaanu fun mi.”
Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ekiti, Sunday Abutu ti fidi iṣẹlẹ naa mulẹ fun BBC Yoruba, o fikun pe awọn ti bẹrẹ iwadii.














