Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá bẹ̀rẹ̀ ìwádìí lórí pásítọ̀ Chris Okafor táwọn obìnrin fẹ̀sùn kan pé ó fipá báwọn lòpọ̀

Oríṣun àwòrán, CHRIS OKAFOR MINISTRIES/INSTAGRAM
Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ní ìpínlẹ̀ Eko sọ pé àwọn ti bẹ̀rẹ̀ ìwádìí lórí pásítọ̀ ìjọ kan, Pásítọ̀ Chris Okafor, ẹni tí ọ̀pọ̀ àwọn obìnrin fẹ̀sùn kàn pé ó fi tipátipá bá àwọn ní àjọṣepọ̀.
Ní ọjọ́ Àìkú, ọjọ́ Kẹrin, oṣù Kìíní, ọdún 2026 ni iléeṣẹ́ ọlọ́pàá, nínú àtẹ̀jáde kan tí agbẹnusọ iléeṣẹ́ ọlọ́pàá Eko, Abimbola Adebisi fi léde, fi ìwé ìpè ránṣẹ́ sí pásítọ̀ náà láti yọjú sí ẹ̀ka tó máa ń wádìí ìwà ọ̀daràn tó wà ní Panti.
Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ní pásítọ̀ náà, tó jẹ́ pásítọ̀ àgbà nínú ìjọ Mountain of Liberation and Miracles Ministries, ìpínlẹ̀ Eko máa kojú ìwádìí tó lágbára.
Àtẹ̀jáde náà ní ohun tí àwọn ránṣẹ́ pe pásítọ̀ náà fún kò ṣẹ̀yìn àwọn ẹ̀sùn tó jọ mọ́ ìfipábánilòpọ̀ èyí tí ọ̀pọ̀ àwọn obìnrin fi kàn-án.
Adebisi fi kun pé àwọn ti pèsè ètò ààbò tó péye láti fi dá ààbò bo gbogbo àwọn èèyàn tí wọ́n fẹ̀sùn kàn pé pásítọ̀ náà ti ṣe aṣemáṣe pẹ̀lú àwọn.
Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ní àwọn máa ri dájú pé ìdájọ́ òdodo wáyé lórí ẹ̀sùn náà àti pé àwọn máa ṣe ìwádìí tó rinlẹ̀ lórí àwọn ẹ̀sùn náà.
Àwọn aláṣẹ dá sí ọ̀rọ̀ náà lẹ́yìn tí ọ̀pọ̀ àwọn obìnrin fẹ̀sùn kan pásítọ̀ náà lórí ìkànnì ayélujára pé ó ṣe àṣemáṣe pẹ̀lú àwọn.
Nínú oṣù Kejìlá, ọdún 2025 láwọn obìnrin bẹ̀rẹ̀ sí ní jáde láti fẹ̀sùn kan pásítọ̀ náà lẹ́yìn tí gbajúmọ̀ òṣèré tíátà kan, Doris Ogala fẹ̀sùn kàn pé pásítọ̀ náà ṣe ìlérí láti gbé òun níyàwó ṣùgbọ́n tí kò ṣe bẹ́ẹ̀.
Okafor gbà pé òun jẹ̀bi
Gẹ́gẹ́ bí Ogala ṣe sọ, ó ní láti ọdún 2017 ni òun àti pásítọ̀ náà ti ń bá eré ìfẹ́ bọ̀, tí pásítọ̀ sì ṣèlérí pé òun máa fẹ́ òun ṣùgbọ́n tó jẹ́ pé irọ́ ló pa fún òun.
Ó ní ìbáṣepọ̀ àti eré ìfẹ́ tó ń wáyé láàárín òun àti pásítọ̀ náà ló da ìgbéyàwó òun rú.
Ogala ní òun fi ọkọ òun sílẹ̀ lẹ́yìn pásítọ̀ náà sọ fún òun láti ṣe bẹ́ẹ̀ àmọ́ tí pásítọ̀ padà já òun sí kolobo.
Lẹ́yìn tí Ogala fẹ́sùn kan pásítọ̀ náà ni Pásítọ̀ Chris Okafor kúnlẹ̀ níwájú pẹpẹ, tó sì sọ fáwọn èèyàn ìjọ rẹ̀ pé kí wọ́n foríji òun, pé òun ti ṣe àwọn àṣìṣe kan sẹ́yìn.
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Okafor kò sọ wí pé òun gba gbogbo àwọn ẹ̀sùn tí wọ́n fi kan òun síbẹ̀ ó tọrọ àforíjìn lórí àwọn ẹ̀sùn náà.
Lẹ́yìn náà ló sọ pé òun máa fi pẹpẹ sílẹ̀ fún oṣù kan ná.
Ní Nàìjíríà, ẹni tó bá fipá bá èèyàn lò pọ̀ ló ṣeéṣe kí wọ́n rán ní ẹ̀wọ̀n gbére tàbí ẹ̀wọ̀n ọdún méjìlá fún ẹ̀ṣẹ̀ tó bá kéré.















