Wo ọjọ́ tí Ramadan yóò bẹ̀rẹ̀, ọjọ́ Àjíǹde, àti àwọn ọjọ́ ìsinmi tí ìjọba yóò kéde ní 2026

Awọn eeyan ti wọn wa niwaju asia Naijiria

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Ba a ṣe n wọ inu ọdun 2026 wẹrẹwẹrẹ lọ la ni ki a maa fi to o yin leti pe awọn ọjọ ìsinmi kan wa ti ọmọ Naijiria yoo jẹ anfaani rẹ.

Yatọ si awọn eyi tijọba yoo kede awọn miiran wa to ṣe pe ikede kankan ko ni waye lori wọn sugbọn awọn eeyan yoo ṣami wọn nitori pe ọjọ pataki ni fun wọn.

January 1

Ọjọbọ tii ṣe ọjọ Kiini inu ọdun 2026 jẹ ọjọ isinmi. Ohun ni wọn fi ṣami iṣipo kuro ninu ọdun 2025 to pari si ọdun 2026.

March 20

Ogunjọ, oṣu Kẹta ni o ṣeéṣe ki ọdun itunu awẹ awọn musulumi, Eid-el-Fitr bọ si. Eyi le ṣokùnfà ki ijọba kede ọjọ naa fun isinmi.

Ijọba a maa kede ọjọ yi ni ọjọ isinmi kete ti wọn ba ti ri oṣu oju ọrun ti oṣu Shaban.

Amọ o ṣeeṣe ki ọjọ yii yipada bi wọn ba ṣe ri oṣu oju ọrun si eyi ti wọn maa n lo gẹgẹ bi kajọkaṣu awọn musulumi.

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

April 3

Lọdun 2026 yii, ayajọ Good Friday bọ si ọjọ Kẹta, oṣù Kẹrin, ọjọ isinmi ni yoo jẹ fun awọn ọmọlẹyin Kristi.

Wọn yoo fi ṣe isami kikan Jesu mọ igi agbelebu ati iku rẹ lori oke Calvary.

April 6

Easter Monday

Ayajọ ọdun yii bọ si ọjọ Kẹfa, oṣu Kẹrin.

O si jẹ ọjọ keji Ajinde ti ọpọ orileede lagbaye maa n ṣami rẹ pẹlu isinmi l'ẹnu iṣẹ.

May 1

Ọjọ kiini, oṣu Karun-un lagbaye jẹ ayajọ awọn oṣiṣẹ ta a mọ si International Workers Day.

Ijọba maa n kede ọjọ yii fun awọn oṣiṣẹ lati fi sinmi.

Wọn a maa fi ọjọ yii ṣe imọriri pataki igbiyanju awọn oṣiṣẹ lagbaaye.

May 27 àti 28

Id el Adha

Ayajọ ọdun nla awọn Musulumi yii le bọ si ọjọ Kẹtadinlọgbọn, oṣu Karun-un.

Oṣù oju ọrun ni wọn fi n ka ọjọ ọdun yii.

Eyi le mu ki ijọba kede ọjọ Kẹtadinlọgbọn àti ikejìdínlọ́gbọ̀n, oṣu Karun-un láti fi ṣami ayẹyẹ ọdún Ileya.

Isinmi yoo wa lọjọ yii.

June 12

Democracy Day

Ayajọ ijọba awaarawa lọjọ yii jẹ ni Naijiria.

Wọn a maa fi ṣe iranti bi Naijiria ṣe bọ kuro labẹ ijọba ologun si ijọba awaarawa lọdun 1999.

August 26

Ijọba yoo kede isinmi ayajọ Id el Maulud, ti awọn Musulumi kan fi máa n ṣe ayajọ ọjọ ibi Anọbi Muhammad.

October 1

Ayajọ ominira Naijiria bọ si ọjọbọ oṣu Kẹwaa lọdun 2026.

Ijọba Naijiria a si maa fun araalu ni isinmi isami ọjọ yii.

Pataki ọjọ naa wa ninu ṣiṣe iranti bi Naijiria ṣe bọ kuro lọwọ ijọba amunisin ilẹ Gẹẹsi lọdun 1960.

December 25

Ọjọ yii ni ayajọ ọdun Keresimesi to sì jẹ ọjọ ìsinmi lẹnu iṣẹ ni isami ayajọ ọjọ ibi Jesu Kristi fawọn Kristẹni.

December 26

Boxing Day jẹ isinmi, ọjọ keji ọdun Keresimesi.

Awọn ọjọ mii ti ijọba ko nii kede isinmi ṣugbọn ti awọn araalu maa n ya sọtọ

February 14

Ọjọ Abamẹta ni ọjọ kẹrinla, oṣu Keji bọ si ni 2026.

Ayajọ ololufẹ ni wọn mọ ọjọ yii si.

Ijọba kii kede rẹ amọ araalu a maa kopa ninu eto isami ayajọ naa lọwọ arawọn.

Feb 17

Oṣù Ramadan le bẹrẹ lọjọ yii ni ibamu pẹlu ẹsin Islam.

Ọjọ naa ṣe pataki nitori pe o tọka si ọjọ akọkọ ti oṣu Ramadan ti awẹ yoo bẹrẹ.

A ko le sọ ni pato pe awẹ yoo bẹrẹ ni ọjọ yii, nitori pe igbimọ to n mojuto ọrọ ẹsin Islam lo maa n kede ọjọ ti awẹ yoo bẹrẹ.

O le jẹ ọjọ yii tabi ọjọ miiran.

March 8

Lọjọ kẹjọ, oṣu Kẹta, ni ayajọ awọn obinrin lagbaye International Women Day.

Kii sí ọjọ isinmi lọjọ yii, amọ lagbaye awọn eeyan maa n lo o lati ṣe afihan awọn àṣeyọrí obìnrin lagbaaye.

May 27

Children's Day

Ọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣu Karun un, ni awọn ọmọde maa fi n ṣe ayajọ ti wọn naa ni agbaye, eyi ti ko yọ Naijiria silẹ.

Ijọba kii kede isinmi lati fi ṣami ọjọ yii, amọ wọn mọ riri pataki ọrọ ọmọde gẹgẹ bo ṣe ri l'awọn orileede mii lagbaaye.