Mi ò fipò sílẹ̀ nítorí mo ṣe nǹkan tí kò tọ́, ṣùgbọ́n nítorí mo bọ̀wọ̀ fún ọ́fíìsì mi-Kemi Adeosun

Oríṣun àwòrán, OTHERS
Minisita nigba kan ri fun eto isuna lorilẹede Naijiria, Kemi Adeosun, ti sọ idi pataki to fi kọwe fipo rẹ silẹ lọdun 2018, lẹyin tí wọn fẹsun kan an pe o yí iwe ẹri pe o kopa ninu eto isinru ilu ti a tun mọ si agunbanirọ.
Saaju ninu ọrọ Adeosun lọdun 2022, o ni ojoojumọ ni òun fi ń wa ẹkún mu fún oṣù mẹ́ta láì ṣe iṣẹ́ kankan.
Nigba to n sọrọ ninu ifọrọwerọ to ṣe pẹlu Channels TV, Adeosun ni oun pari eto ẹkọ oun ni ẹni ọdun mejilelogun (22) ni ilẹ UK, gẹgẹ bii ọmọ ilẹ UK.
"Orilẹede Naijiria ko faaye gba ki eeyan jẹ ọmọ onilu meji titi ọdun 1999.
"Mo ti ṣísẹ ni ilẹ UK fun ọdun marundinlogoji, tí mo si ni iyọnda agunbanirọ."
Nigba ti wọn bi i pe ki lo fa a to fi kọwe fipo silẹ nigba to mọ pe oun ko jẹbi ẹsun tí wọn fi kan an.
"N ko kọwe fipo mi silẹ nítorí mo ṣe nnkan ti ko daa, mo kọwe fipo silẹ nítorí mo ni ibọwọ fun ileeṣẹ tí mo n dari."
Bẹẹ ni Kemi Adeosun dahun.
Tẹ o ba gbagbe, Kemi Adeosun gbe ìjọba apapọ lọ sile ẹjọ nigba naa lori ọrọ yii, ninu idajọ ile ẹjọ giga ni ilu Abuja ni adajọ si ti sọ pe ko pọn dandan fun un lati sin ilu rẹ fun ọdun kan labẹ eto NYSC, nitori ko yẹ fun ipe naa.
Adajọ Taiwo Taiwo ni Adeosun ki i ṣe ọmọ Naijiria nigba to ṣetan ni ile iwe giga, to si pe ẹni ọgbọn ọdun, nitori naa ko nilo sabuke.
Bakan naa ni adajọ naa fi kun un pe ko nilo lati fi sabuke NYSC han ko too le gba ipo minisita lorilẹede Naijiria.
Kí lo ṣẹlẹ saaju?
Ọdun 2018 ni Kemi Adeosun fi ipo rẹ silẹ gẹgẹ bi minisita fun eto iṣuna lẹyin ti wọn fẹsun kan an pe ayederu sabuke lo lo fun NYSC rẹ.
Ninu atẹjade ti Adeosun fi sita lo ti ni oun yoo gbe gbogbo igbeṣẹ to yẹ labẹ ofin bayii lati ri i pe oun ja fun orukọ oun ti wọn bajẹ.
''Mo ti gbọ lati ọdọ awọn agbẹjọro mi pe mi o nilo lati ṣe NYSC ki n too di minisita ni Naijiria, eleyii si ni mo ti n ja fun lati ọjọ yii, amọ mo dupẹ pe ọrọ naa ti ni ojutu.''
Bayii ni Minisita tẹlẹ naa sọ.












