Kí ló ṣokùnfà tí kò fi sí ọyẹ́ lásìkò yìí?

Ọkùnrin kan fẹ́ sọdá ojú pópó, àwọn ọkọ̀ ń kọjá, kùrukùru bo ojú ọjọ́

Oríṣun àwòrán, OTHER

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Ọdún tuntun tún ti bẹ̀rẹ̀ ṣùgbọ́n ohun tó ń ya ọ̀pọ̀lọpọ̀ èèyàn lẹ́nu ni pé dípò ọyẹ́ tó máa ń kí oṣù Jánúárì káàbọ̀, pàápàá ní apá ìlà gúúsù àti àríwá Nàìjíríà, ooru lo ń mú kíkankíkan.

Gẹ́gẹ́ bí ìṣe, tó bá fi máa di ìparí oṣù Kejìlá sí ìbẹ̀rẹ̀ oṣù Kìíní ọdún, ọyẹ́ ti máa ń mú gidigidi láwọn apá ibìkan káàkiri Nàìjíríà ṣùgbọ́n èyí kò rí bẹ́ẹ̀ lọ́dún yìí rárá.

Èyí ti mú kí ọ̀pọ̀ èèyàn máa kọminú, tí wọ́n sì ń bèèrè pé kí ni ohun tó ń ṣokùnfà àyípadà yìí.

Ẹ̀wẹ̀, àwọn onímọ̀ gbàgbọ́ pé ó ní àwọn nǹkan tó ń ṣokùnfà àyípadà ojú ọjọ́ yìí àti pé ọ̀pọ̀ rẹ̀ ló jẹ́ àfọwọ́fà ọmọnìyàn.

Àyípadà ojú ọjọ́

Láti ṣèwádìí ohun tó ṣẹlẹ̀, BBC kàn sí adarí iléeṣẹ́ tó ń rí sí àyípadà ojú ọjọ́, Umar Saleh Anka sọ pé àyípadà ojú ọjọ́ ló ń ṣokùnfà ohun tí gbogbo àgbáyé ń rí báyìí.

Gẹ́gẹ́ bó ṣe sọ, àwọn ìpínlẹ̀ bíi Yobe, Benue, Adamawa, Sokoto, Katsina, Kano àti Jigawa tí wọ́n tètè máa ń rí ọyẹ́ ni wọn kò ì tíì rí ọyẹ́ lásìkò yìí.

Ó ní láàárín oṣù Kọkànlá sí oṣù Kẹta ni àwọn ìpínlẹ̀ yìí fi máa ń rí ọyẹ́ ṣùgbọ́n tí àyípadà ńlá ti bá báyìí èyí tó ní ó jẹ́ àpẹẹrẹ àyípadà ojú ọjọ́.

Nígbà tó ń sọ̀rọ̀ nípa ohun tó ṣokùnfà èyí, Umar Anka ní òjò kò fi bẹ́ẹ̀ rẹ̀ lọ́dún 2025 débi pé ó fa ọ̀gbẹlẹ̀ láwọn ibìkan ní apá àríwá.

Onímọ̀ nípa ojú ọjọ́ náà sọ pé òjò tí kò rọ̀ dáadáa náà ni kò jẹ́ kí ọyẹ́ náà tètè jáde.

Ó fi kun pé ọ̀pọ̀ nǹkan ló ń ṣokùnfà àyípadà ojú ọjọ́ tó fi mọ́ gígé àwọn igi nínú igbó, àwọn iléeṣẹ́ ńláńlá tí wọ́n ń da èéfí sínú àyíká, bó ṣe ní àwọn ni wọ́n ń dákún àyípadà tó ń bá ojú ọjọ́.

"Ní kúkurú, àyípadà ojú ọjọ́ ń wáyé látàrí àwọn àyípadà tó ń wáyé sí àyíká àti ojú ọjọ́, èyí tó ń fa àyípadà sí àwón àkókò àti ìgbà tí a máa ń rí."

Kí ni àwọn nǹkan tó yẹ ní ṣíṣe?

Nígbà táwọn nǹkan báyìí bá ń wáyé, ohun tí àfojúsùn máa ń jẹ́ ni láti wá ojútùú sí ìṣòro bẹ́ẹ̀, àtàwọn ọ̀nà láti wá àtúnṣe síi.

Umar Saleh Anka sọ pé àwọn ìṣòro tó jẹ́ pé àyípadà ojú ọjọ́ ló ṣe okùnfà wọn kìí ṣe ohun tí wọ́n le wá ojútùú sí ní kíákíá.

"Àwọn ipá àyípadà ojú ọjọ́ kìí ṣe ohun tó ṣeéṣe àtúnṣe sí ní kíákíá ṣùgbọ́n wọ́n lè mú àdínkù bá ipa rẹ̀ díẹ̀díẹ̀."

Onímọ̀ náà la àwọn ìlànà pàtàkì kalẹ̀ tí wọ́n lè tẹ̀lé láti mú àyípadà bá ipa rẹ̀:

  • Gbíngbin igi
  • Mú àdínkù bá igi gígé nínú igbó
  • Ṣíṣe ètò ọ̀gbìn ní ìlànà ìgbàlódé tí kò ní ṣàkọbá fún àyípadà
  • Lílo àwọn èso tí ọ̀gbẹ̀lẹ̀ kò lè ṣàkóbá fún ètò ọ̀gbìn
  • Ṣíṣe òfin lórí àyípadà ojú ọjọ́

Anka ní ìjọba nílò láti gbé òfin kalẹ̀ ní kíákíá láti lè ṣàmójútó àyípadà ojú ọjọ́ àti àwọn ipa tó le ní lórí àwùjọ.

"Lọ́dọ̀ ti wa gẹ́gẹ́ bí àjọ tí kìí ṣe ti ìjọba, a ti bẹ̀rẹ̀ àwọn àkànṣe iṣẹ́ láti mú àdínkù bá ipa tí àyípadà ojú ọjọ́ le ní. A ní ìrètí pé ìjọba máa fọwọ́sowọ́pọ̀ pẹ̀lú wa láti ṣe àṣeyọrí."