Ṣé lóòótọ́ ní òògùn owó ṣíṣe wà? Babaláwo ṣàlàyé
Ti a ba n sọrọ nipa nnkan ti ọpọ awọn eeyan fẹ mọ, ọkan lara rẹ ni n jẹ ṣe loootọ ni oogun owo n bẹ gẹgẹ bii a ti ṣe n gbọ kiri.
Ọpọ igba ni ọwọ ileeṣẹ ọlọpaa ti tẹ awọn eeyan pe awọn ṣekupa eeyan kan nitori etutu ọla.
Eyi lo mu BBC News Yoruba gbera lọ ba ogbontagiri Babalawo, Olakunle Olasope lati tan imọlẹ si ibeere yii ati pe ṣe lootọ ni pe awọn Babalawo tabi oniṣẹẹse lo n ṣe oogun owo yii fun awọn eeyan.
Ninu alaye rẹ, Olakunle ni o ṣe koko ki a yọ kuro ninu ọka wa wa pe Babalawo n fi eeyan ṣe owo.
"Eewọ ni, ẹni to ba ti n fi eeyan ṣe owo ki I ṣe Babalawo."
O tẹsiwaju pe ko si bi wọn ti ṣe fẹ irẹsi ti ko ni si kanda ninu rẹ.
Olakunke ni awọn eeyan kan wa ti wọn n fi aṣọ Babalawo boju lati ṣe orisirisi iranu pe awọn n ṣe ogun owo.
"Tẹ ẹ ba ri ẹni to n wa owo tipatipa, tẹ ẹ ba wa a kulẹkulẹ, ki I ṣe onisẹẹse, nitori oniṣees ki I wa owo tipatipa."
Alaye wa ninu ifọrọwerọ ti a ṣe







