"Mo máa ń ṣọ́ra gan an:" Wo bí àwọn akọ̀ròyìn BBC tó ń ṣàtìpó nílẹ̀ òkèèrè ṣe ń pọ̀ si

Shazia Haya maa n kaakiri Afghanistan gege bi akoroyin
Àkọlé àwòrán, Shazia Haya maa n kaakiri Afghanistan gege bi akoroyin
    • Author, Stephanie Hegarty
    • Role, Population correspondent, BBC World Service

Iye awọn akọroyin BBC to n ṣatipo nilẹ okeere ti di okoo le lọọdunrun bayii lati ọdun 2020.

Nọmba ọhun ni wọn gbe jade ṣaaju ayajọ ọjọ ṣiṣẹ iroyin pẹlu ominira lo n ṣapujuwe ohun toju awọn akọroyin n ri lorilẹede Russia, Afghanistan ati Ethiopia.

Awọn akọroyin l'awọn orilẹede bii Iran ti n gbe nilẹ okeere fun bi ọdun mẹwaa bayii.

Ọpọ akọroyin ni wọn ti dajọ ẹwọn fun, wọn n dunkoko iku mawọn mii.

Ogbagba ileeṣẹ iroyin BBC, Lilian Landor sọ pe "ọna kan ti wọn n fi le ṣiṣẹ ni nipa kikuro nile wọn.

Bi iye awọn akọroyin yii ti ko le gbe ile wọn ṣiṣẹ mọ ṣe n pọ si jẹ nnkan to n kọ wa lominu."

Ọpọ akọroyin BBC lo kuro ni Afghanistan nigba ti awọn Taliban gbjoba lọdun 2021.

Awọn oṣiṣẹ to jẹ obinrin ko le ṣiṣẹ mọ, nigba ti wọn n dunkoko mawọn ọkunrin.

Iru nnkan yii naa n ṣẹlẹ ni Myanmar ati ni Ethiopia.

Jiyar Gol to jẹ akọroyin BBC Persia "mo maa ṣọra gidi gan an.

Mo ni ọpọlọpọ ẹrọ kamẹra fun aabo mi ninu ile.

Bakan naa ni wọn kìlọ fun mi pe ki n paarọ ile ẹkọ ọmọbinrin mi."

Ọdun 2007 ni Jiyar ti de Iran kẹyin.

Koda, ko le lọ sile lati lọ sin oku iya rẹ.

O ti n ṣọra ṣe lati igba ti arun jẹjẹrẹ ti ṣekupa iyawo rẹ ni bi ọdun mẹrin sẹyin.

Jiyar ni "ti nnkan kan ba ṣẹlẹ si mi, ki lo maa ṣẹlẹ si omodebinrin mi?

Ohun ti mo maa n ro ni gbogbo igba niyii."

"Ìjọba orilẹede Iran ko bikita nipa ohun tawon eeyan n sọ nipa orilẹede naa.

Wo ṣe oriṣiiriṣii ofin to de awon akọroyin.'

Nina Nazarova fi Russia lodun 2022 pelu oko ati omo re
Àkọlé àwòrán, Nina Nazarova fi Russia lodun 2022 pelu oko ati omo re
Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Jodie Ginsburg to jẹ ọkan lara ọmọ igbimọ to n daabo bo awọn akọroyin sọ iye awọn akọroyin t'awọn n ṣe iranwọ owo fun nibi ti wọn ti n ṣatipo nilẹ okeere ti lọ soke pẹlu ida 225%.

O ni "ọpọ akọroyin lo wa lẹwọn nigba ti awọn ti wọn n ṣekupa ti pọ si lati ọdun 2015."

Awọn ijọba orilẹede bii Russia, Iran ati Saudi Arabia fẹ maa ṣakoso ohun to n lọ lọdọ wọn ati ohun tawon eeyan n sọ nipa wọn lẹyin odi.

Nina Nazarova to n ṣiṣẹ pẹlu BBC Russia fi ile rẹ silẹ lẹyin ti Russia yabo Ukraine.

Ti o ṣe n lọ ni o ri pe ọkọ rẹ toun naa jẹ akọroyin n bomi loju.

Ọjọ kẹrin oṣu Kẹta ọdun 2022 ni ofin tuntun to n ṣagbeyẹwo iroyin jade.

O ni "mo le dero ẹwọn nipa sisọ nipa ogun."

Oun ati ọkọ rẹ gbera pẹlu ọmọkunrin wọn ọmọ ọdun kan ati oṣu mẹrin morile orilẹede Turkey.

Wọn kọkọ lọ si Dubai fun isinmi ti wọn ti sanwo rẹ ki ogun Russia ati Ukraine to bẹrẹ.

Leyin naa ni wọn lọ si Montenegro ki wọn to morile Riga ti i ṣe olu ilu Latvia nibi ti BBC fi ṣe ọfiisi fawon oṣiṣẹ rẹ to kuro ni Russia.

Loṣu Kẹrin ọdun yii, ami lati ilẹ okeere ni wọn n pe Llya Barabanov to jẹ akẹgbẹ Nina ni BBC Russia.

Wọn fẹsun kan an wi pe ni ṣe lo ngbe iroyin ofege kiri ti o si n tako ogun to n lọ.

Oun ati BBC tako eleyii nile ẹjọ.

Loṣu kẹta to kọja, wọn gun akọroyin aladani kan lọbẹ lẹsẹ ni ilu London.

Ẹwẹ, ileeṣẹ ọlọpaa UK to n gbogun ti igbesunmọmi kìlọ pe idunkoko mawọn akọroyin BBC Persia to n gbe ni UK ṣi maa pọ si.

 Farnaz Ghazizadeh ati Rana Rahimpour awon akaroyin BBC Persia fi Iran siler (r)
Àkọlé àwòrán, Farnaz Ghazizadeh ati Rana Rahimpour awon akaroyin BBC Persia fi Iran sile

Ni ọdun 2022, awọn kan wọ inu ọkọ Rana Rahimpour to jẹ akaroyin

BBC Persia.

Wọn si gbe ọrọ ti oun ati iya rẹ jọ sọ ti wọn ká silẹ jade loju opo iroyin to jẹ ti ijọba Iran.

Wọn ṣe eda rẹ ko le dabi eni pe o n ṣatilẹyin fun ijọba Iran.

Nigba naa ni Rana sinmi lẹnu iṣẹ akaroyin fun igba diẹ.

Rana ni "ohun to sẹlẹ si mi jẹ ọkan lara awọn ọna ti wọn n gba lati tabuku wa."

Akaroyin mii Farnaz Ghazizadeh ni nigba kugba toun ba n pe mama oun ni Iran, oun maa n mọ pe ẹlòmíràn n gbọ ohun tawọn n sọ.

Ko tii pada si Iran fun ọdun mọkanlelogun bayii.

Laipẹ yii o mọ wọn ti dajọ ẹwọn ọdun kan fun oun ati akẹgbẹ rẹ mẹsan an mii ni Iran.

Ṣaaju ni ijọba Iran fẹsun kan awọn oṣiṣẹ BBC Persia pe wọn n da rogbodiyan silẹ ati pe wọn tẹ ẹtọ ọmọnìyàn mọlẹ.

Farnaz ati ọkọ rẹ fi ilu silẹ pẹlu ọmọ wọn oṣu mẹfa leyin ti ọkọ rẹ ṣe ẹwọn ọjọ mẹẹdọgbọn tori pe o kọ iroyin kan.

Lọdun 2022, buọda Farnaz ṣe aisan, o si ku lẹyin ọsẹ mẹfa.

Lẹyin oṣu mẹfa, baba rẹ ku.

O ni "ohun ti mi o le gbegbe laelae ni eleyii.

O wu mi ki n gbaruku ti ẹbi mi ni Iran, amọ, mi o le lọ síbẹ."

Shazia Haya to jẹ oṣiṣẹ BBC Pashto ni tiẹ maa n ronu pe oun jẹbi awọn ebi oun.

Oun nikan lo raye wa si UK nigba t'awọn Taliban gbajọba ni Afghanistan lọdun 2022, o si fi awọn obi rẹ ati buọda rẹ silẹ ni Kabul.

"Lootọọ ni mo gba ominira, sugbọn inu ẹwọn ni o dabi ẹni pe mo wa nibi."

Ọkan lara awọn akọroyin BBC ti ko darukọ ara rẹ ni iṣoro nla kan toun ati akẹgbẹ oun n koju ni ai le sọ pe ọmọ orilẹede kan bayii pato l'awọn ṣe, ti ijọba ba kọ lati ṣe isọdọtun iwe irinna awọn.

Ni Afghanistan ati Iran, wọn n dunkoko mọ ọpọ eeyan to ba ba BBC sọrọ.

Nina sọ oun ko lanfaani lati b'awọn araalu sọrọ mọ lati sọ ohun ti wọn ma ba elomiiran sọ.

Bakan naa lo n ṣafẹri ipejọpọ pẹlu awọn eeyan rẹ.

Farnaz ni ṣiṣe iṣẹ nilẹ okeere dabi eni pe igbe aye abọ ni eeyan n gbe.

"O ko le gbe igbe aye ti o fẹ.

Mo ti di ara ilẹ Gẹẹsi bayii tori ibi ni mo n gbe.

Kii ṣe bi nnkan ṣe n ṣiṣẹ niyii.

Eeyan wa ni atipo, o ṣi tun wa ni ilu rẹ bakan naa," Farnaz lo sọ bẹẹ.