Ìjì líle gba ẹ̀mí èèyàn mẹ́wàá, àwọn 20 di àwátì

Aworan agbara ojo

Ko din ni eeyan mẹta ti wọn jade laye ninu afẹfẹ iji lile to fẹ laipẹ yii nipinlẹ Rio Grande do Sul to wa lorileede Brazil, ti ogun eeyan si tun di awati.

Titi di asiko ti a pari akojọpọ iroyin yii, awọn ọkọ baluu agberapa ti a mọ si Helicopter ni wọn ṣi n fo kaakiri lati fi wa awọn ogun to di awati.

Afẹfẹ iji lile naa lo fa agbara ojo nla, eyi to ṣakoba fun iku awọn eeyan naa, ati bi awọn ogun tun ṣe poora.

Ni awọn agbegbe kan, agbara ojo naa pọ debi wi pe awọn oko baluu agberapa yii ko le ri ibi balẹ si.

Gomina ipinlẹ yii ti rawọ ẹbẹ sijọba apapọ lati dide iranlọwọ fun wọn lori bi wọn ṣe le ṣawari awọn to di awati naa, ati aabo fun awọn araalu.

Ninu ọrọ ti Gomina Eduardo Leite kọ soju opo ayelujara X rẹ, o ni “Aarẹ Lula, ẹ tara ṣaṣa ran awọn iranwọ oju afẹfẹ wa si Rio Grande do Sul.

“A nilo lati ran awọn to le ni ọgọrun-un to wa ninu iṣẹlẹ pajawiri lọwọ, lori ojo nla to rọ, ati awọn eyi ti yoo ṣi tun rọ siwaju sii.”

Loju ẹsẹ ni Aarẹ Luiz Inácio Lula da Silva ti fi idahun ṣọwọ wi pe ijọba apapọ yoo dide iranwọ.

“Ijọba apapọ yoo dide iranwọ fun ijọba ipinlẹ lati ṣe iranwọ lasiko ipenija yii, eyi to waye nitori ayipada oju ọjọ to n ṣẹlẹ.”

Gẹgẹ bi awọn alẹnulọrọ ṣe sọ, wọn ni eyan mẹwaa ni jiji lile naa gba ẹmi rẹ.

Awọn ni eeyan meji ku sinu mọto nigba ti agbara ojo gbe wọn lọ pẹlu mọto ti wọn wa ninu ẹ lagbegbe Paverama. Awọn miran ku ni Salvador do Sul.

A ṣi n wa awọn mọkanlelogun, ati pe gbogbo awọn ti ko tii ri iranwọ bayii jẹ ẹgbẹrun kan ataabọ.

“A maa tubọ maa ṣiṣẹ takuntakun lati rii pe a ṣawari awọn to di awati, ki a si rii daju pe aabo wa fun awọn eeyan lawọn agbegbe ti ewu wa.” Ọgbẹni Leite ṣalaye.