Ojú mi ri tó lẹ́yìn tí ìyàwó mi jáde láyé ní ọjọ́ kẹta tó bí ìbẹta- Gafar

Àkọlé fídíò,
Ojú mi ri tó lẹ́yìn tí ìyàwó mi jáde láyé ní ọjọ́ kẹta tó bí ìbẹta- Gafar
Baba ìbẹta àtawọn ọmọ rẹ̀

Ìdùnnú máa ń ṣubú layọ̀ fún àwọn tọkọtaya lẹ́yìn tí wọ́n bá gba ìròyìn pé ọlẹ̀ ọmọ bá sọ nínú ìyàwó wọn.

Bẹ́ẹ̀ náà ló rí fún ìdílé Afolarin Gafar nígbà tó gbọ́ pé ìyàwó òun tún lóyún bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n ti ní ọmọ méjì nílẹ̀ tẹ́lẹ̀.

Gafar ní ìdùnnú àwọn tún lékún un nígbà tí àwọn lọ ṣe àyẹ̀wò, tí wọ́n sì sọ fún àwọn pé ìbejì ló wà nínú ìyàwó òun.

Ó ní òun gbàgbọ́ pé Ọlọ́run máa bá àwọn tọ́jú àwọn ọmọ náà ṣùgbọ́n àyà ka òun nígbà tí àwọn tún lọ ṣàyẹ̀wò tí wọ́n sì sọ fún àwọn pé ìbẹta ni àwọn ń retí.

Ó ṣàlàyé pé ṣáájú àkókò tí wọ́n fún ìyàwó òun pé ó máa bímọ ni ó bẹ̀rẹ̀ sí ní da omira tí àwọn sì gbe e lọ ilé ìwòsàn fún iṣẹ́ abẹ nítorí àwọn ti mọ̀ pé iṣẹ́ abẹ ni yóò ṣáájú àkókò náà.

Gafar pẹ̀lú ìpòruru ọkàn ní ọjọ́ kẹta tí ìyàwó bí àwọn ọmọ náà tán, tí àwọn ti ń dunnú pé Ọlọ́run ti bá àwọn sọ ẹrù inú rẹ̀ kalẹ̀, ló jáde láyé.

“Láti ìgbà náà ni mo ti ń dá tọ́jú àwọn ìbẹta pẹ̀lú àwọn ọmọ méjì tí a ti ṣáájú bí tẹ́lẹ̀.

Ó ní kò rọrùn fún òun láti máa tọ́jú àwọn ọmọ náà ṣùgbọ́n òun ń sá gbogbo ipá òun láti ri i pé wọ́n ń gbé ayé ìrọ̀rùn.

Bákan náà ló ń kọminu lórí ohun tí òun yóò sọ fún àwọn ọmọ náà lọ́jọ́ iwájú tí wọ́n bá ń bèèrè nípa ìyá tó bi wọn.