Nǹkan ti ń burú síi fún Ukraine lójú ogun pẹ̀lú Russia - Ọ̀gá ọmogun Ukraine

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ọga ologun Ukraine, Olaksandr Syrskyi, ti sọ pe nnkan ti buru sii fun awọn ọmogun orilẹede Ukraine loju ogun pẹlu Russia.
Ọgagun Syrskyi sọ pe awọn ọmogun Russia ti n ṣe ikọlu lera lera si awọn ọmogun Ukraine.
Syrskyi ṣalaye pe awọn ọm'ogun Ukraine ti kuro loju ija pẹlu Russia lapa ila oorun ẹkun Donetsk.
Awọn ọm'ogun Russia fẹ lo agbara won ki Ukraine to ri iranwọ ohun ija oloro lati ọwọ orilẹede Amerika lo.
Ni ọsẹ to lọ, orilẹede Amẹrika fun ileeṣẹ ologun Ukraine ni awọn nnkan ija oloro ti owo rẹ to biliọnu mọkanlelọgọta dọla, $61bn.
Amọ, ileeṣẹ ọm'ogun Ukraine ko tii lo awọn nnkan ija oloro ti Amerika fun wọn loju ogun.
Ẹwẹ, awọn ọm'ogun Ukraine ko tii lo awọn nnkan ija oloro ti Amẹrika ko fun wọn papaa jùlọ l'awọn agbegbe ti Ukraine ko ti ni nkan ija ogun.
Syrskyi sọ loju opo Telegram ileeṣẹ ologun Ukraine pe nnkan ti le sii gan an loju ija fun awon ọm'ogun Ukraine.
O fidi rẹ mulẹ pe lootọọ ni ileeṣẹ ologun ti ko awọn ọm'ogun rẹ kuro ni ẹkun Donetsk.
Syrskyi ṣalaye pe ẹkun yii wa lara awọn ẹkun ti Russia ti gba lẹyin ti wọn ti gba Avdiivka loṣu Keji.
Ọpọ ija to n waye ṣẹlẹ ni agbegbe Chasiv Yar to wa labẹ iṣakoso Ukraine, eleyii ti Russia fẹ gba lẹyin ti wọn ti gba Avdiivka tan.















