Ọ̀pọ̀ akẹ́kọ̀ọ́ Fáṣítì US dèrò àhámọ́ nítorí ìfẹhonúhàn tí wọ́n ṣe lórí ìkọlù Israel sí Gaza

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ogunlọgọ awọn ọdọ to jẹ akẹkọọ fasiti lorilẹede Amẹrika lo ti dero ahamọ nitori wọn gun le ifẹhonuhan to tako bi ogun ṣe n tẹsiwaju ni Gaza.
Ifẹhonuhan yii ko sẹyin ikọlu Israel si Gaza nibi ti eeyan to le ni ẹgbẹrun lọna ọgbọn eeyan ti wọn jẹ ọmọ ilẹ Palestinians ti padanu ẹmi wọn gẹgẹ bii ileeṣẹ eto ilera Hamas ṣe kede sita.
Kini wọn n sọ nipa oludije Stein?
Oludije Aarẹ labẹ asia ẹgbẹ oṣelu Green Party, Jill Stein naa pẹlu awọn eeyan to wa ni ahamọ Ileeṣẹ ọlọpaa.
Agbẹnusọ arabinrin Stein ni o wa lara ọgọrin eeyan ti awọn ọlọpaa mu ni fasiti Washington ni St Louis, ni ipinle Missouri.
Sugbọn awọn akẹkọọ Jew ti bu ẹnu atẹlu bi awọn olufẹhonuhan kan ṣeese si awọn.
O tẹsiwaju pe wọn ti ka ẹsun si oludije naa lẹsẹ.
Bakan naa ni Ile ẹkọ gbogbonise Poly California ti wọgile ki eto ẹkọ maa waye ni ọgba ile ẹkọ, ti wọn si tun sun ayẹyẹ ikẹkọọgboye awọn akẹkọọ siwaju.
Ifẹhonuhan yii lo ti bẹrẹ ni ọjọ kẹtadinlogun, oṣu kẹrin, ti o si ti bẹrẹ si ni buyọ ni awọn agbegbe mii kaakiri orilẹede naa.
Tajutaju ni awọn ọlọpaa fi n tu awọn akẹkọọ ka, ti o le ni ọgọrun-un akẹkọọ si ti wa ni atimọlẹ bayii.
Ko pẹ si asiko naa ni ifẹhonuhan mi tun buyọ ni Fasiti Yale ni Connecticut.
Ni Fasiti Northeastern ni Boston, o le ni ọgọrun-un akẹkọọ to ti wa ni ahamọ ileeṣẹ ọlọpaa Massachusetts fun ririn gberegbere ni ọjọ Satide.
Fasiti naa gbe e sori ayelujara pe awọn kọlọrọsi eeyan lo n ṣe agbatẹru ifẹhonuhan naa, ti ile ẹkọ ko si mọ ohunkohun nipa rẹ.
Ni Fasiti South California, awọn olufẹhonuhan tun tu sita lẹyin awọn olori ile ẹkọ kesi Ileeṣẹ ọlọpaa lati wa le awọn akẹkọọ nibi ti wọn ti n ṣe iwọde naa.
Ifẹhonuhan ni wọn ni o jẹ ifẹhonuhan alaafia sugbọn awọn olori ile ẹkọ fẹsun kan awọn olufẹhonuhan pe wọn ba dukia ile ẹkọ naa jẹ.
Eeyan mẹtalelogun ni ọwọ tẹ ni Fasiti Indiana lọjọ Satide.














