Èèyàn kan ló kú níbi ìbúgbàmù afẹ́fẹ́ ìdáná l’Abẹokuta, mẹ́rin kọ́-FRSC

Ibudo ijamba naa

Oríṣun àwòrán, FRSC Ogun

Yatọ si iroyin kan to jade, pe eeyan mẹrin lo ku nibi ibugbamu afẹfẹ idana to waye niluu Abẹokuta nirọlẹ Satide, ajọ ẹṣọ ojupopo FRSC, ti sọ pe ẹnikan lo ku.

Ninu atẹjade ti agbẹnusọ FRSC nipinlẹ Ogun, Florence Okpe, fi sita lo ti fidi eyi mulẹ.

Okpe ṣalaye pe ọmọ ẹyin ọkọ (Motor boy) ti ina ọhun ka mọ inu ọkọ ni ko raye jade, to si ku sinu iṣẹlẹ naa.

O fi kun un pe eeyan meji lo farapa pẹlu, mẹrin kọ.

Kí ló ṣẹlẹ̀ tí iná ńlá fi ṣẹ́yọ n’Ita-Ọṣin, l’Abẹokuta

Ibudo iṣẹlẹ ijmaba ina naa

Oríṣun àwòrán, FRSC Ogun

Irọlẹ ọjọ Satide, ọjọ kẹtadinlọgbọn oṣu kẹrin ọdun 2024 yii ni iroyin gbode, pe tanka kan to gbe afẹfẹ idana deede gbina lagbegbe Ita-Ọṣin, niluu Abẹokuta.

Bi ina ọhun ṣe ṣẹyọ ni wọn ni awọn eeyan kan to wa nitosi jona, ati pe ọpọlọpọ ṣọọbu lo faragba a.

Bi eyi ṣe n lọ lọwọ ni iroyin naa n tan kari ayelujara, ti ọlọkan-o-jọkan onka eeyan to ku si n jade nipa rẹ.

Ṣugbọn ajọ FRSC ipinlẹ Ogun, labẹ iṣakoso Kọmanda Anthony Uga, ṣalaye pe eeyan mẹfa ni iṣẹlẹ naa kan.

Wọn ni ọkunrin ni gbogbo wọn. Eeyan meji ni wọn lo farapa ninu wọn, ẹnikan lo si doloogbe.

Ìjánu ọkọ̀ tó gbé afẹ́fẹ́ ìdáná ni kò mú mọ́ tí iná fi ṣẹ́yọ

Ibudo iṣẹlẹ ijmaba ina naa

Oríṣun àwòrán, Ogun FRSC

Nigba ti wọn n ṣatupalẹ iye mọto ti ijamba naa kan, FRSC ogun sọ pe marun-un ni.

Tanka to gbe gaasi naa ni wọn lo padanu ijanu rẹ (brake failure), eyi lo si fa a to fi fori sọ pepele ti wọn fi dabuu ọna.

Bi eyi ṣe ṣẹlẹ ni tanka naa gbina lojiji, ti ina nla ṣẹyọ.

Ninu ina naa ni ọmọ ẹyin ọkọ tanka naa ku si, nitori ko ri ọna abajade.

Eyi lawọn ọkọ ti ijamba ina naa kan bi FRSC Ogun ṣe fi sita.

AAN544 YC NISSAN

GDB841XR MICRA

LSD993 CY NISSAN

T23771 LA SINO TRUCK

Ati ọkọ HONDA CRV ti ko ni nọmba idanimọ.

Wọn gbe oku ọmọ ẹyin ọkọ lọ sile igbokusi ọsibitu ijọba to wa l’Abẹokuta, nigba ti ẹbi awọn to farapa lọọ tọju wọn bi ajọ ẹṣọ oju popo ṣe ṣalaye.