DNA: Ǹjẹ́ o mọ̀ pé obìnrin lè bí Ìbejì tí wọn yóò sì ní bàbá ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀?

Ẹsẹ awọn ibeji kan

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Taiwo ati Kehinde Olanrewaju (kii ṣe orukọ wọn gangan ree, akan lo oruko yii ni) jẹ ọmọ meji akọkọ ti obi wọn bi.

Nipa ti jijọ, wọn ko foju jọ ara wọn to bẹẹ ṣugbọn eleyi ko jẹ tuntun nitori awọn ibeji mii wa to jẹ pe wọn kii jọ ara wọn.

Nigba ti wọn wa lọmọ ọdun mẹfa, Kehinde farapa ti wọn si nilo lati ṣe iṣẹ abẹ fun un.

Iṣẹ abẹ naa nilo ki wọn gba ẹya ara baba rẹ kan, ki o to le gbadun.

Awọn dokita ṣetan, wọn ṣe ayẹwo baba rẹ ṣugbọn wọn ri i wi pe ẹya rẹ ko papọ mọ ti Kehinde.

Àkọlé fídíò, Bí mo ṣe rí ọ̀pọ̀ Mílíọ̀nù Nàírà tí mo sì dáà padà fún Ọlọ́pàá lọ́dún 1971 àmọ́ ǹkan t'íjọba sọ rèé - Baba Shonubi

Ọrọ naa ṣe wọn ni kayeefi, ti o si mu ki baba Kehinde maa beere pe bawo leyi ti ṣe jẹ.

Asẹyinwa aṣẹyinbọ, wọn ṣayẹwọ DNA fun Kehinde, ti wọn si ri wi pe kii ṣe ọmọ baba rẹ ṣugbọn ayẹwo fihan pe oun lo bi Taiye.

Àkọlé fídíò, 2021 Twin Festival: Aráàlú ní Ifá ló sọ pé ìbejì yóò pọ̀ ní Igboora, kìí ṣe jíjẹ Ìlasa

Njẹ eeyan le bi ibeji fun baba ọtọọtọ?

Nigba ti wọn n salaye bi eyi se ri bẹẹ, awọn dokita ni o ṣeese ki o ṣẹlẹ bẹẹ niwọn igba ti iya awọn ọmọ naa ba ni ibalopọ pẹlu awọn ọkunrin meji lasiko kan naa ṣaaju ki o to loyun.

Wọn ni iru iṣẹlẹ yii ṣọwọn amọ o le ṣẹlẹ.

Orukọ ti wọn pe iru isẹlẹ yi ni ede Gẹẹsi ni ‘Heteropaternalsuperfecundation’.

Àkọlé fídíò, Ẹ̀mí kan náà ló n darí ìrìnàjò wa táa fi jọ kọ́lé papọ̀- Ìbejì

Bawo lo ṣe n ṣẹlẹ:

Awọn onimọ ṣayensi fidi ọrọ mulẹ pe, iṣẹlẹ superfecundationis yii ṣọwọn laarin awọn eeyan ṣugbọn lagbo ẹranko, iru rẹ a maa wọpọ daadaa.

Ni ṣoki, ohun to ṣẹlẹ ni pe, àtọ̀ orisi meji ọtọọtọ ni yoo dapọ mọ ẹyin obinrin lasiko ibalopọ ọtọọtọ, ti yoo si bi ibeji lati ara ọkunrin ọtọọtọ.

Àkọlé fídíò, Se lootọ?: Wo irú sítàílì tó yẹ láti fi bẹ̀rẹ̀ ìbàlópọ̀ lẹ́yìn ìbímọ- Tola Ajayi

Iru iṣẹlẹ yii kan naa to waye ni orileedẹ Vietnam lọdun 2016.

Ọjọgbọn Le Dinh Luong, to jẹ aarẹ awọn onimọ ẹya ara Vietnam Genetic Association, ṣayẹwo awọn ibeji kan ti wọn ko foju jọ ara wọn, to si fidi ọrọ mulẹ pe wọn kii ṣe ọmọ baba kan naa.

Àkọlé fídíò, Promise Akinlade: ọmọ ọdún mọ́kànlá tó ń fi ìlù dárà bíi àgbàlagbà sọ̀rọ̀ nípa tálẹ́ǹtì rẹ

O ni iru iṣẹlẹ yi ko wọpọ ''koda o ni awọn ibeji to ni baba ọtọọtọ bayii ko ju mẹwaa lọ tawọn mọ lagbaye''

O tẹsiwaju pe, o ṣeeṣe ki awọn mii wa ṣugbọn tawọn obi wọn ko mọ pe baba ọtọọtọ lo bi wọn tabi ki wọn si maa fẹ pariwo rẹ faraye gbọ.

Àkọlé fídíò, Glorious Twins: Taiwo àti Kehinde Ekundayo ní ọ̀dọ́ ìyá àgbà ní àwọn ti ẹ̀bún orin kíkọ

Awọn onimọ tẹsiwaju pe, ki iru nnkan bayii to le ṣẹlẹ yoo jẹ wi pe, ẹyin meji ọtọọtọ to n di ọmọ lara obinrin ni yoo wa ninu ile ọmọ obinrin naa,

ti aatọ awọn ọkunrin mejeeji to ba ba a lopọ lasiko kan naa, yoo si da pọ mọ wọn lọtọọtọ.

O tun le ṣẹlẹ ti ile ọmọ obinrin ba pese ẹyin lẹẹmeeji lera wọn, ti awọn ẹyin ọtọọtọ yii ba si dapọ mọ aatọ ọkunrin meji ọtọọtọ to ni ibalopọ pẹlu obinrin naa.

Àkọlé fídíò, TolaSex style and danger in pregnancy: Irú sítàílì ìbálòpọ̀ wo ló n jẹ́ kí oyún tètè dúró?

Ti adura ba gba ti o di oyun, ohun ti yoo ṣẹlẹ ni pe awọn ọmọ meji pẹlu baba ọtọọtọ ni obinrin naa yoo bi.

Yatọ si iṣẹlẹ ta fidi rẹ mulẹ pe o waye ni Vietnam lọdun 2016, awọn irufẹ iṣẹlẹ yii ti waye ni ilẹ Amẹrika niluu New Jersey lọdun 2015.

Àkọlé fídíò, Wo àwọn ìbejì tó lẹ́ pọ̀ lẹ́yìn àṣeyọrí ìṣẹ́ abẹ dókìtà 70

Ibeji obinrin lawọn ọmọ yii, awọn si ni ikẹta irufẹ isẹlẹ yii ti akọsilẹ wa pe o ṣẹlẹ ni Amẹrika.

Awọn irufẹ isẹlẹ mii to tun waye ni ti orileede Turkey nibi ti awọn ileeṣẹ iroyin ni awọn ibeji kan ni baba ọtọọtọ lọdun 2010.

Àkọlé fídíò, Promise Akinlade: ọmọ ọdún mọ́kànlá tó ń fi ìlù dárà bíi àgbàlagbà sọ̀rọ̀ nípa tálẹ́ǹtì rẹ

Awọn Taiye Kehinde ti a wa sọ nibẹrẹ iroyin yii nkọ?

Apejuwe la fi wọn ṣe ṣugbọn ko tumọ si pe ko le ṣẹlẹ ni Naijiria naa.

Taa n ti ẹ mọ boya iru rẹ ti waye ṣugbọn tawọn mọlẹbi ko kan fẹ polongo ṣetigbọ araye?