Conjoined Twins: Wọ́n fi mí ṣe yẹ̀yẹ́ ládùúgbò, ojú tì mì - Ìyá àwọn ìbejì

Ileewosan ijọba to wa ni Yola, ipinlẹ Adamawa tun ti ṣiṣẹ alaṣeyọri kan gẹgẹ bi wọn ṣe fi aṣẹ abẹ ya awọn ọmọ ibeji to lẹpọ.
Ikọ onimọ ilera mejidinlaadọta lo ṣe iṣẹ abẹ naa lori awọn ibeji ọhun lẹyin oṣu mẹjọ ti wọn bi wọn.
Eyi ni igba kẹta ti ile iwosan ijọba to wa ni Yola ti ṣiṣẹ abẹ lori awọn ibeji ti wọn bi bẹẹ ti wọn lẹpọ gẹgẹ bi adari ile iwosan naa, Ọjọgbọn Auwal Abubakar ṣe sọ ọ.
- Iléẹjọ gíga jùlọ da ẹjọ́ SDP àti PDP nù, wọ́n ní Yahaya Bello ló wọlé ìbò gómìnà Kogi
- Ààrẹ Buhari buwọ́lu gbígbé ìṣàkoso nọ́mbà ìdánimọ̀ (NIMC) lọ sí ẹ̀ka ìjọba tó ń rí sí ìbáraẹnisọ̀rọ̀
- Wọ́n ti sún ìdájọ́ àwọn sójà tó pa ìyá àti ọmọ ní ọdun 2018 sí oṣù tó m bọ̀
- Ṣé Nàìjíríà lẹ́mìí nkan tí Ghana ń ṣe fáwọn akẹ́kọ̀ọ́ "Secondary" tí yóò wọlé ní October yìí?
Awọn to wa ninu ikọ to ṣe iṣẹ abẹ naa ni awọn dokita oniṣẹ abẹ atawọn onimọ ilera mii ti wọn lo wakati mẹta lati doola awọn ọmọ mejeeji lọjọ kẹwaa oṣu kẹjọ ọdun 2020 ti wọn bi wọn pẹlu ẹdọ ati eegun aya kan naa ti wọn jọ mu wa latọrun.
Oniṣẹ abẹ agba to tun jẹ oludari ile iwosan FMC ni ilu Yola, Ọjọgbọn Auwal sọ pe iṣẹ abẹ naa jẹ aṣeyọri.

"Ẹdọ kan naa ati egungun aya kan naa ni wọn ni ṣugbọn a ti irinṣẹ kan wa ti a lo eyi to ran wa lọwọ gan lati din ẹjẹ ti yoo ṣofo ku ti yoo si mu iṣẹ naa pari laarin akoko kukuru".
Ọjọgbọn naa fi kun un wipe, wọn ti n ṣeto lati ṣe ipinya awọn ọmọ naa tipẹ ṣugbọn wọn ni lati dawọ duro di ọjọ kẹwaa, oṣu kẹjọ.
Bakan naa, awọn ọmọ naa wa daadaa ti wọn si ti bẹrẹ si nii ṣere lẹyin ọjọ mẹta ti wọn ti pari iṣẹ abẹ naa. "Wọn ti gbe wọn pada si ilu wọn a si n pe wọn lori ago lai si iyọnu kankan.
Awọn ibeji naa, Grace ati Mercy ti iya wọn, Aibekipriye Ebinyefa ni ọkan oun ti lọ lasiko ti wọn n ṣe iṣẹ abẹ naa toripe ẹu n ba oun fun ọjọ iwaju awọn ọmọ oun.
"Nigba ti wọn ni a maa ṣe iṣẹ abẹ, ẹru ba mi diẹ tori eeyan ẹlẹran ara lemi naa ati pe gẹgẹ bii abiyamọ, ẹru ba mi".
"Inu mi ko dun pe emi ni obirin akọkọ to kọkọ bi ibeji to lẹpọ ni ilu wa ati ni ipinlẹ wa".
O ni awọn eeyan dẹyẹ si mi, wọn fi mi ṣe yẹyẹ, oju si n ti mi, ṣugbọn ni bayii inu mi dun tori ko sewu nibẹ. Lonii a ti n lọ ile. Ebinyefa sọ bẹẹ.
Arabinrin naa sọ pe yoo wu oun ki awọn ọmọ oun naa di dokita ti wọn ba dagba.
"Mo kan ṣaa fẹ ki wọn di dokita ni ṣugbọn mi o mọ ohun ti wọn maa fẹ funra wọn ti wọn ba dagba tori gbogbo eeyan to dagba lo lẹtọ lati yan ohun to ba wu wọn".
Ṣugbọn o ni oun maa sọ fun wọn pe ki wọn naa le ran awọn mii to lẹpọ bii tiwọn lọwọ lọjọ iwaju".
Baba awọn ọmọ ọhun ni "nigba ti iyawo mi bi awọn ibeji yii, mo ro o pe kilode ti eyi ṣẹlẹ si mi ni ọjọ ori mi yii ṣugbọn nibayii mo ti dupẹ lọwọ Ọlọrun".
Ijọba ibilẹ Nembe ni ipinlẹ Bayelsa ni iha Guusu Naijiria ni wọn ti bi awọn ọmọ naa ti wọn si gbe wọn wa si iha Ariwa nipinlẹ Adamawa latinu oṣu kini ọdun yii fun iṣẹ abẹ.
Eyi ni igba ẹkẹẹta ti ileewosan ijọba ti Yola yoo ṣe iṣẹ abẹ fun awọn ọmọ to lẹpọ lẹyin eyi ti wọn ṣe lati ọdun 2018.
















