Egypt ni Orunmila kọ́kọ́ dé sí kó tó rìn wá sí Ile Ife, Ife kọ́ ni olùdáyé- Babaláwo
Babalawo kan lati Itoko nilu Abeokuta nipinlẹ Ogun, Obafemi Makinde ti salaye fun BBC Yoruba nipa atupalẹ ẹsin Ifa ati awọn nnkan to rọ mọ.
Makinde, ẹni to ni ibudo ti wọn ti n kọ nipa ẹsin Ifa ni Abeokuta salaye nipa ibi ti Ifa ti rin wa ati bi a se le lo awọn Odu Ifa fun igbe aye ọmọniyan.
Bakan naa lo tun sọrọ nipa asise to wa ninu ka fi ọwọ yẹpẹrẹ mu ẹsin iṣẹse ati ewu ti eyi lee ni lori wa.
Bakan naa, Baba Awo Makinde tun sọrọ lori ibi ti Orunmila ti rin wa ati ipo ti Ile Ife wa ninu Ifa.

"Ọpọ asise si lawọn eeyan n se lode oni nipa ilu to jẹ oludaye"
Nigba to n ba BBC Yoruba sọrọ, Baba Awo Obafemi Makinde ni ko wu oun lati sisẹ babalawo amọ Ifa lo pe oun.
"Wọn bi mi sinu isẹse ni, gbogbo ọmọ ti wọn si bi sinu iṣẹṣe ni wọn maa n tẹ Ifa fun.
Inu igboro ti wọn ti lọ tẹ Ifa fun mi ni Ifa ti ni Babalawo ni maa ṣe.
Ko wu mi rara lati sisẹ awo, amọ mo ti mọ bayii pe lẹyin Ọlọrun, Ifa lo tun kan.
Ko si yẹ ka fi ọwọ rọ iṣẹṣe sẹyin nitori ọmọ to ba sọ ile nu, o so apo iya kọ.
Ọpọ asise si lawọn eeyan n se lode oni nipa ilu to jẹ oludaye, ti maa si la wọn lọyẹ nipa okodoro ọrọ."

"Ile Ife yii kọ ni Ife Oludaye, Egypt ni Ife Oludaye wa"
Ninu alaye rẹ, babalawo Makinde ni ọrọ ẹnu Olodumare ni Ifa jẹ, Orunmila si ni Ongbufọ rẹ.
O fikun pe ilẹ Egypt ni Orunmila ti wa, kii si se ilu Ile Ife rara gẹgẹ bi awọn eeyan kan ti maa n sọ.
"Egypt ni oludaye, kii se ilu Ile Ife ode oni nitori ilẹ Egypt ni Orunmila ti rin wa silẹ Yoruba.
Bakan naa, Ile Ife kii ṣe oludaye nibi ti ojumọ ti n mọ wa sile aye, amọ Egypt ti Orunmila ti wa ni.
Ifẹtẹdo ni wọn n pe Ile Ife ode oni, kii se oludaye rara.
Ikin ni olutọsọna Orunmila nigba to n bọ lati ilẹ Egypt, ti Ọpẹlẹ si jẹ ọmọṣẹ Orunmila.
Ọpẹlẹ gberaga si Orunmila lo se fọ si meje, to si ni ka maa beere ohunkohun lọwọ Ọpẹlẹ, oun yoo maa da wa lohun."
Bakan naa ni Babalawo Obafemi Makinde tun salaye pe ọdun mẹta ni eeyan fi n kọ Ifa amọ ẹni to ba fẹ mọ ọ daadaa yoo lo to ọdun mẹfa si meje.



