Mo ti bá olóòtú fíìmù lòpọ̀ rí, kí n lè kópa nínú sinimá rẹ̀ – Seun Sean Jimoh

Oríṣun àwòrán, Seun Sean Jimoh
Gbajumọ oṣere tiata Yoruba, Seun Sean Jimoh ti sọ pe oun ti fi akoko igba kan ni ibalopọ pẹlu olootu fiimu ri lọna ati kopa ninu ere naa.
Jimoh lo sọ ọrọ yii ninu ifọrọwerọ ori eto kan pẹlu akẹgbẹ rẹ ninu iṣẹ ọhun, Biola Adebayo.
O ni bo tilẹ jẹ pe oun dagba laini baba, koda ọmọ ọdun mẹrindinlogun loun wa, ki oun to kọkọ foju kan baba oun.
Amọ ṣa, o ni baba rere ni oun si awọn ọmọ oun, oun si jẹ ọkan lara awọn baba to ṣee mu yangan lawujọ lonii.

Oríṣun àwòrán, Seun Sean Jimoh
"Bi ibalopọ naa ṣe waye ree..."
O ni “awọn obinrin kan ti lo ipo wọn ninu iṣẹ tiata le mi lori ri, nigba ti mo ṣẹṣẹ n dagba ninu iṣẹ yii.
“Bo ṣe ri ree, ti o ba kere, ti o si n wa nnkan, ti ẹni to ni nnkan ti o n wa si gbiyanju lati ni ibalopọ pẹlu rẹ ṣugbọn ti ko si nnkan ti o le ṣe nipa rẹ.
“Mo ṣi maa n ranti eyii to ṣẹlẹ si mi titi di oni yii, idi ree ti mo ṣe mọ bo ṣe n ri lara awọn obinrin, ti wọn ba sọ pe ẹnikan fọwọ kan wọn lọna aitọ.
“Mo mọ bo ṣe ri lara nitori o ṣẹlẹ si mi ri, mo ni ibalopọ pẹlu olootu ere nitori mo ro pe mi o ni agbara.
O ṣalaye pe bo tilẹ jẹ pe awọn to n ni ibalopọ akọsakọ ti gbiyanju lati ba oun lopọ ri, àmọ́ abo ni olootu ere ti oun ba lopọ.
Jimọh ni bo tilẹ jẹ pe oun gbadun ibalopọ naa lọdun naa lọhun, sugbọ́n kii ṣe oun to wu oun lati ṣe ni.
O wa pari ọrọ rẹ pe ko bojumu ki eeyan maa lo ipo rẹ lati ni ibalopọ pẹlu ẹlomiran nitori agbara ti wọn ni lori irufẹ ẹni bẹe tabi nitori ohun ti ẹni ọhun fẹ gba lọwọ wọn.
Bo tilẹ jẹ pe iṣẹlẹ naa ti kuregbe-kuregbe, o ni o ṣi maa n ba oun ninu jẹ titi di oni yii.















