Wo ohun tó ṣẹlẹ̀ s’áwọn tó fẹ̀hónú hàn nítorì ọ̀wọ́ngógó oúnjẹ ní Benin

Aworan awọn ọlọpaa ati oluwọde

Oríṣun àwòrán, MC Yọkọyọkọ

Ibi gbogbo lati n ko adiẹ alẹ ni ọrọ ọwọngogo ounjẹ lasiko yii.

Bo ṣe n ṣẹlẹ ni Naijiria naa ni wọn n kigbe ọwọngogo ati airowo ra ounjẹ lorilẹ-ede Olominira Benin naa.

Bi gbogbo nnkan ṣe n nira fawọn araalu ni Repubublic of Benin, ti ara wọn ko gbe e mọ lo fa a ti awọn ajafẹọọ ọmọniyan kan fi pinnu lati ṣewọde tako inira naa.

Wọn ni iwọde ọhun ko ni i bi wahala funjọba tabi araalu, wọọrọ ni yoo jẹ.

Awọn yoo kan fi sọ ohun to n koju awọn nilẹẹ baba awọn ni.

Ọjọ Satide, ọjọ kẹtadinlogun oṣu kẹrin yii ni wọn fi iwọde naa si.

Ìjọba kìlọ̀, wọ́n ní ìwọ́de kò gbọdọ̀ wáyé

Awọn ọlọpaa to fẹẹ dena iwọde

Oríṣun àwòrán, MC Yọkọyọkọ

Ṣaaju ọjọ iwọde naa ni ikilọ ti waye lati ọdọ gomina Cotonou, Alain Orounla, pe ẹnikẹni ko gbọdọ ṣe iwọde kankan.

Ikilọ ijọba naa de etigbọ awọn eeyan ti wọn fẹẹ sẹwọde, wọn si gba pe awọn ko ni i ṣe e mọ.

Koda, awọn ọlọpaa rẹpẹtẹ ni wọn jade sigboro laarọ Satide naa, paapaa lagbegbe Gbegame ti i ṣe ibi ti awọn ajafẹtọọ naa pọ si.

A gbọ pe awọn ọlọpaa naa bẹrẹ si i yin tajutaju lati dena ifẹhonuhan ati ki ẹnikẹni ma baa jade ṣewọde.

Ọrọ bẹ́yin yọ, àwọn aráàlú padà ṣèwọ́de

Aworan awọn araalu to n ṣewọde

Oríṣun àwòrán, MC Yọkọyọkọ

Ṣugbọn ọrọ pada bẹyin yọ lori iwọde yii, nigba ti awọn afẹhonuhan ti wọn ti lawọn ko ni i jade mọ tun pada jade ti wọn si n wọde kaakiri awọn agbegbe.

Bi wọn ṣe n wọde ọhun lai si wahala ni wọn n sọ ẹdun ọkan wọn nipa igbesi aye inira ti wọn n gbe.

Ọlọpaa kó olùwọ́de mẹ́tàdínlógún

Nibi ti iwọde ọhun ti n lọ lọwọ lawọn ọlọpaa ti ko mẹtadinlogun (17) ninu awọn oluwọde naa.

Awọn ti wọn jẹ olori ajafẹtọọ la gbọ pe o pọ ninu awọn ti wọn ko naa.

Wọn ru wọn lọ si teṣan, wọn ko wọn si gbaga.

Ariwo gba orí ayélujára, àwọn èèyàn bínú sí ìgbésẹ ìjọba

Aworan awọn ọlọpaa

Oríṣun àwòrán, MC Yọkọyọkọ

Bi wọn ṣe ko awọn eeyan naa sahaamọ fa ariwo lori ayelujara.

Ọpọ eeyan lo koro oju si bawọn ọlọpaa ṣe ko awọn oliwọde yii, wọn si bẹrẹ kigbe ijọba.

Nigba ti yoo fi di aṣalẹ ọjọ Satide ọhun, ijọba tun ero wọn pa.

Wọn fi awọn eeyan naa silẹ lati maa lọ latari ikoro oju to pọ naa.

Ṣugbọn bi wọn ṣe yọnda wọn naa lawọn eeyan n ṣi n sọrọ, wọn ni titẹ ẹtọ ẹni loju mọlẹ ni iwa tijọba naa hu.

Ṣaa, alaafia ti pada sawọn agbegbe, ayipada ọwọngogo ounjẹ naa lawọn eeyan n reti bayii.