Ilé alájà dàwó lu òṣìṣẹ́ márùndínlógún ní Kano

Oríṣun àwòrán, channelstv.com
Ile alaja meji kan ti dawo ni ilu Kano lẹkun Ariwa orilẹede Naijiria.
Gẹgẹbi iroyin ṣe sọ, ile naa dawo le awọn oṣiṣẹ to n kọ ọ lọwọ ni agbegbe Gwale ni ijọba ibilẹ Gwale.
Eeyan kan ti iṣẹlẹ naa ṣoju rẹ ṣalaye fun BBC pe awọn oṣiṣẹ to n ṣiṣẹ nibi ile naa lasiko to da wo to marundinlogun.
Nibayii, awọn oṣiṣẹ adoola ẹmi ti n gbiyanju lati doola awọn eeyan naa labẹ awoku ile ọhun.
Lasiko ti BBC fi ba o-ṣoju-mi-koro naa sọrọ, eeyan mẹta ninu awọn ti wọn ti doola ni wọn ti ri fa sita.
Ọkan ninu awọn ti wọn doola ẹmi wọn naa ti j'alaisi, nigba ti awọn meji yooku wa lẹsẹ kan aye, ẹsẹ kan ọrun.
Ko tii si ẹni lee ọ ni pato iye awọn ti ijamba ile alaja to dawo naa ṣe lọṣẹ.











