Àwọn gómìnà lápá Àríwá lọ Amẹ́ríkà láti wá ojútùú sí ààbò tó mẹ́hẹ, àbọ̀ wọn rèé

Awọn agbebọn ati ile ti wọn jo

Oríṣun àwòrán, collage

Iṣoro aisi aabo to rinlẹ lapa Ariwa orilẹ-ede Naijiria lo mu awọn gomina ibẹ tẹkọ leti lọ sorilẹ-ede Amẹrika laipẹ yii.

Wọn lọ ṣe ipade pẹlu awọn oyinbo lori ọna ati fopin si i.

Lẹyin ti ipade naa pari, awọn gomina yii ti fidi ẹ mulẹ, pe awọn ti ri awọn aṣiri kan to ju ti tẹlẹ lọ, eyi tawọn le fi koju iṣoro aisi aabo naa.

Wọn ni aṣiri ọna aabo tawọn mu bọ lati Amẹrika pọ ju ohun tawọn mọ nigba tawọn ko ti i ṣepade oke okun naa.

Gomina ipinlẹ Katsina, Dikko Ummaru, ṣalaye fun BBC pe ọna abayọ ti wa bayii lati ṣẹgun rogbodiyan aabo to n daamu Ariwa Naijiria.

Dikko Ummaru, Gomina ipinle Katsina

Oríṣun àwòrán, DIKKO UMMARU FACEBOOK PAGE

’’A ti sọ ohun tí a fẹ́ k’Amẹrika ṣe fún wa’’

Gomina Katsina ṣalaye pe awọn ti sọ ohun tawọn fẹ ki orilẹ-ede Amẹrika ṣe fawọn lori ọrọ yii.

Dikko sọ pe, ‘’ Nigba ti wọn ji ọmọ orilẹ-ede Amẹrika kan gbe lorilẹ-ede Niger, ti wọn gbe e wa sapa Oke Ọya, laarin asiko perete l’Amẹrika gba a kalẹ.

‘’Bi wọn ba le sare gba eeyan wọn kalẹ bẹẹ, ki lo de ti wọn o le ran awa naa lọwọ pẹlu iru imọ bẹẹ ati ba a ṣe maa lo o.

‘’A tun jiroro lori eto ọrọ aje wa naa, nipa ba a ṣe le ṣẹgun iṣẹ ati oṣi.

‘’Ọna abayọ oriṣiiriṣii la lakalẹ ninu ipade wa naa, lagbara Oluwa, gbogbo ẹ la o maa ko kalẹ nigba ta a ba pada si Naijiria.’’

Imugbooro ẹka ọgbin, ina ọba to duro deede ati bi wọn yoo ṣe maa wa ohun alumọọni inu ilẹ tun wa lara ohun to ni ipade naa yannana, fun idagbasoke Oke Ọya.

Bakan naa si ni iṣoro aikawe to n yọ wọn lẹnu naa, Dikko lawọn oyinbo ti kọ awọn lohun tawọn yoo ṣe si i.

’’Yíyanjú ìṣòro yìí kò gba ìkánjú’’

Gomina Katsina sọ pe ati yanju awọn iṣoro yii ko gba ikanju rara.

O ni ohun ti yoo gba asiko pupọ lati ṣe ni.

Ipinlẹ Katsina jẹ ọkan lara awọn ibi to n koju ikọlu awọn agbebọn.

Bi wọn ṣe n wọ inu ilu ni wọn n wọ abule ji wọn gbe, bẹẹ ni wọn n ji dukia awọn olugbe ibẹ gidi.

Gomina Ariwa mẹwaa ni wọn rin irinajo yii, awọn naa ni Dikko Ummaru lati Katsina, Uba Sani (Kaduna), Aba Yusuf(Kano) Nasir Idris(Kebbi), Umar Namadi (Jigawa).

Awọn yooku ni:Ahmad Aliyu (Sokoto), Dauda Lawal (Zamfara), Hyacinth Akia (Benue), Mohammed Bago(Niger) ati Caleb Mutfwanf (Plateau)

Ọjọ kẹtalelogun si ọjọ kẹẹẹdọgbọn oṣu kẹrin 2024 yii ni ipade ti wọn ṣe l’Amẹrika naa fi waye.