Ẹ má kó oúnjẹ 5000 tí mo pín lọ sílé yín, àwọn mẹ̀kúnnù tó nílò rẹ̀ ni kí ẹ pín fún - Sanwo-Olu kìlọ̀

Sanwo-Olu n pin ounjẹ

Oríṣun àwòrán, jidesanwoolu/Instagram

Latari ọwọngogo ounjẹ ati bi apa araalu ko ṣe ka a lasiko yii ni Naijiria, Gomina Eko, Babajide Sanwo-Olu ti gbe eto ipese ounjẹ kan kalẹ fun ẹgbẹrun lẹẹẹdẹgbẹta (500,000) eeyan l’Ekoo.

‘’Eko Cares Initiative’’ ni Sanwo-Olu pe eto naa.

Ọjọru, ọjọ kẹrinlelogun oṣu kẹrin 2024 yii leto ọhun gbera sọ.

Bijọba Eko ṣe wi, awọn eeyan ijọba ibilẹ ogun (20), ati tawọn Onidagbasoke (LCDA) mẹtadinlogoji (37) to wa l’Ekoo ni yoo janfaani naa.

Nigba to n sọrọ nibi ifilọlẹ eto naa, Gomina Sanwo-Olu kilọ fawọn aṣoju lati awọn ijọba ibilẹ pe ki wọn ma ṣe ko awọn ounjẹ naa pamọ.

O ni ki wọn ri i pe awọn to nilo rẹ lo gba a, wọn ko gbọdọ ko o lọ silee tiwọn.

Gomina sọ pe idẹrun araalu nijọba oun fẹ, oun yoo si tẹsiwaju ninu ẹ.

Sanwo-Olu ni kawọn eeyan Eko ṣaa maa ti oun lẹyin lọ, ohun gbogbo yoo daa laipẹ.

Sanwo-Olu n pin ounjẹ

Oríṣun àwòrán, jidesanwoolu/Instagram

Àwọn wo nìjọba yó koó oúnjẹ náà fún láti pin?

Gomina Sanwo-Olu sọ pe awọn olori agbegbe, olori ileejọsin, ẹgbẹ awọn akanda ẹda, ẹgbẹ ajafẹtọọ ọmọniyan ati bẹẹ bẹẹ lọ nijọba yoo ko awọn ounjẹ naa fun.

O ni awọn ni wọn yoo pin in fawọn eeyan wọn.

Gomina rọ wọn lẹẹkan si i lati ma ṣe ko ounjẹ naa pamọ, kawọn to nilo rẹ le ri i gba bo ṣe yẹ.

Sanwo-Olu sọ pe koko eto naa ni pe k’ebi ma pa awọn eeyan Eko.

Bakan naa lo sọ pe eto Ounje Eko tijọba ṣe, ti wọn n ta ounjẹ lowo to rọju yoo maa tẹsiwaju lọ.

Sanwo-Olu n pin ounjẹ

Oríṣun àwòrán, jidesanwoolu/Instagram