Ọlọ́pàá sọ̀rọ̀ lórí ikú adarí ikọ̀ ìpolongo gómìnà Aiyedatiwa l’Ondo tí agbébọn pa

Oríṣun àwòrán, Lucky Orimisan Aiyedatiwa
Awọn agbebọn ti ṣekupa Alaba Excel Abbey, to jẹ ọkan lara awọn oludari ikọ ipolongo gomina ipinlẹ Ondo, Lucky Aiyedatiwa
Oloogbe naa to jẹ ọkan gboogi lara awọn adari ikọ ipolongo gomina lẹkun waadu ni a gbọ pe wọn ṣekupa niluu Supare Akoko, to jẹ ilu bibi rẹ.
Ọkan lara awọn agbẹnusọ igbakeji gomina ipinlẹ Ondo, Rahaman ‘Ray of Hope’ Adekunle lo fidi iroyin naa mulẹ fun BBC Yoruba.
Ẹwẹ, ọga agba ikọ ipolongo ọhun, David Ajobiewe, to bu ẹnu atẹ lu iṣẹlẹ naa juwe oloogbe ọhun gẹgẹ bii ẹni ti kii ṣe jagidijagan.
Lẹyin na lo rọ ileeṣẹ ọlọpaa lati wa kulẹkulẹ iṣẹlẹ ọhun.
Ajobiewe sọ pe “Excel jẹ ọkan pataki lara awọn to n ṣiṣẹ takuntakun fun ipolongo gomina Aiyedatiwa ni waadu kẹwaa to wa niluu Supare.
“Bẹẹ si ni kii ṣe onijọgbọn, a ko gbọ iroyin jagidijagan tabi iroyin iwa ipa ninu ile nipa rẹ ri.
“A rọ ileeṣẹ ọlọpaa ki wọn ba wa ṣewadii iku rẹ ki wọn si fi imu gbogbo ẹni to ba lọwọ ninu rẹ danrin.”
Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ondo, Funmilayo Odunlami-Omisanya naa ti fidi iroyin ọhun mulẹ.
Odunlami-Omisanya sọ pe “a ti gbọ nipa iṣẹlẹ ipaniyan naa, a si ti bẹrẹ iwadii lati mọ kulẹkulẹ ohun to ṣẹlẹ.”
Alukoro ọlọpaa pari ọrọ rẹ pe oun ko tii le sọ boya iṣekupani ọhun lọwọ oṣelu ninu.















